-
Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Tó Dára fún Ọkàn àti ÌleraJí!—2012 | January
-
-
“Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn.”—ÒWE 17:22.
-
-
Ọ̀rọ̀ Ọgbọ́n Tó Dára fún Ọkàn àti ÌleraJí!—2012 | January
-
-
Bí èèyàn bá jẹ́ ẹni tí inú rẹ̀ máa ń dùn, ìyẹn pẹ̀lú máa ń jẹ́ kí èèyàn ní ìlera tó dáa. Dókítà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Derek Cox, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ètò ìlera lórílẹ̀-èdè Scotland, sọ nínú ìròyìn kan ní Ilé Iṣẹ́ Rédíò Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì (BBC) pé: “Tó bá jẹ́ pé inú rẹ sábà máa ń dùn, tó bá di ọjọ́ iwájú, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé o kò ní máa ṣàìsàn bíi ti àwọn tí inú wọn kì í dùn.” Ìròyìn náà tún sọ pé: “Àwọn tí inú wọn máa ń dùn sábà máa ń bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro bí àrùn ọkàn àti rọpárọsẹ̀.”
-