-
Jíjíròrò Ohun Tẹ̀mí Ń gbéni RóIlé Ìṣọ́—2003 | September 15
-
-
20. Kí la lè ṣe tá a bá bá onítìjú èèyàn pàdé?
20 Kí lo máa ṣe bí ẹnì kan kò bá fẹ́ gbọ́ ìjíròrò tẹ̀mí tó o dẹ́nu lé? Má ṣe jẹ́ kí ìyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ. O lè wá àkókò mìíràn láti bá a sọ̀rọ̀. Sólómọ́nì sọ pé: “Bí àwọn èso ápù ti wúrà nínú àwọn ohun gbígbẹ́ tí a fi fàdákà ṣe ni ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.” (Òwe 25:11) Fòye bá àwọn tó jẹ́ onítìjú lò. “Ìmọ̀ràn ní ọkàn-àyà ènìyàn dà bí omi jíjìn, ṣùgbọ́n ènìyàn tí ó ní ìfòyemọ̀ ni yoo fà á jáde.”a (Òwe 20:5) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, má ṣe jẹ́ kí ìwà àwọn ẹlòmíràn mú kó sú ọ láti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó o gbọ́ tó sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn.
-
-
Jíjíròrò Ohun Tẹ̀mí Ń gbéni RóIlé Ìṣọ́—2003 | September 15
-
-
a Àwọn kànga kan ní Ísírẹ́lì jìn gan-an. Àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí ìkùdu omi kan tó jìn tó mítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ní Gíbéónì. Ó ní àwọn àtẹ̀gùn nínú, èyí tó mú kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti sọ̀ kalẹ̀ lọ fa omi jáde nínú rẹ̀.
-