A Fi Yẹtí Oníwúrà Ṣe É Lọ́ṣọ̀ọ́
LÁTI ìgbà ìjímìjí, a ka ohun ọ̀ṣọ́ wúrà sí ohun tí ó níye lórí gidigidi, tí ó sì lẹ́wà. Nígbà tí Jósẹ́fù di olórí ìjọba ní Íjíbítì, Fáráò fún un ní ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tí a fi wúrà ṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 41:42) A fún Rèbékà ní òrùka imú kan àti ẹ̀gbà ọwọ́ méjì tí a fi wúrà ṣe, tí iye rẹ̀ tó 1,400 dọ́là (U.S.) ní ìṣirò òde òní. (Jẹ́nẹ́sísì 24:22) Láìsí iyè méjì, ọpẹ́ ni wọ́n fi gba àwọn ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye wọ̀nyí, wọ́n sì fi ìdùnnú wọ̀ wọ́n.
Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ohun ọ̀ṣọ́ ìṣàpẹẹrẹ tí ó níye lórí fíìfíì ju èyí tí Jósẹ́fù àti Rèbékà wọ̀ lọ. Òwe 25:12 (NW) sọ pé: “Yẹtí tí a fi wúrà ṣe, àti ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi àkànṣe wúrà ṣe, ni ọlọ́gbọ́n olùfi ìbáwí tọ́ni sọ́nà jẹ́ ní etí tí ń gbọ́ràn.” Nígbà tí agbaninímọ̀ràn kan bá fúnni nímọ̀ràn tí a gbéka orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dípò èrò ti ara rẹ̀, ẹ̀bùn tí ó níye lórí ni ó ń fúnni ní tòótọ́. Èé ṣe? Nítorí pé ní ti gidi, ọ̀dọ̀ Jèhófà gan-an ni irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ti wá. Bíbélì sọ fún wa pé: “Ọmọ mi, má ṣe kọ ìbáwí Olúwa; bẹ́ẹ̀ ni kí agara ìtọ́ni rẹ̀ kí ó má ṣe dá ọ: Nítorí pé ẹni tí Olúwa fẹ́ òun ní í tọ́, gẹ́gẹ́ bí bàbá ti í tọ́ ọmọ tí inú rẹ̀ dùn sí.” (Òwe 3:11, 12) Nígbà tí ẹni tí ń tẹ́tí sílẹ̀ náà bá fi ìrẹ̀lẹ̀ gba ìmọ̀ràn náà, tí ó sì fi í sílò, ṣe ni ó dà bíi pé ó fi yẹtí oníwúrà ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́. Bí Bíbélì tí a mí sí ti sọ gan-an ni ó rí pé: “Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó wá ọgbọ́n rí, àti ọkùnrin náà tí ó gba òye. Nítorí tí owó rẹ̀ ju owó fàdákà lọ, èrè rẹ̀ sì ju ti wúrà dáradára lọ.”—Òwe 3:13, 14.