ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́—2003 | September 1
    • 18, 19. Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí wo ni Bíbélì fún wa tó lè mú ka gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, àmọ́ èrò tí kò tọ̀nà wo làwọn kan ń ní nípa èyí?

      18 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rọ̀ wá pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” (Òwe 3:5, 6) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ń tuni lára gan-an wọ́n sì ń fini lọ́kàn balẹ̀. Ó dájú pé kò sí ẹlòmíràn láyé lọ́run tó ṣeé gbíyè lé bí kò ṣe Baba wa ọ̀run. Àmọ́ ṣá, ó rọrùn gan-an láti ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn nínú ìwé Òwe ṣùgbọ́n ó lè ṣòro láti wá mú wọn lò.

  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́—2003 | September 1
    • 22, 23. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tá a bá níṣòro, báwo la sì ṣe lè ṣe èyí? (b) Ki la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

      22 Àmọ́ ṣá o, Òwe 3:6 sọ pé a gbọ́dọ̀ ‘ṣàkíyèsí Jèhófà ní gbogbo ọ̀nà wa,’ kì í ṣe kìkì ìgbà tí ìṣòro bá dé. Nítorí náà, àwọn ìpinnu tá a ń ṣe nínú ìgbésí ayé wa lójoojúmọ́ gbọ́dọ̀ fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Bí ìṣòro bá dé, a kò gbọ́dọ̀ sọ̀rètí nù, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wá, a sì gbọ́dọ̀ gbé ìlànà Jèhófà yẹ̀ wò lórí ọ̀nà tó dára jù lọ láti bójú tó àwọn ọ̀ràn náà. A gbọ́dọ̀ ka àdánwò sí àǹfààní láti ṣètìlẹ́yìn fún ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ, láti fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì, àti láti jẹ́ onígbọràn ká sì ní àwọn ànímọ́ mìíràn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí.—Hébérù 5:7, 8.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́