Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Tí Sólómọ́nì Fúnni Nípa Irú Ìwé Tó Yẹ Ká Máa Kà
“NÍNÚ ṣíṣe ìwé púpọ̀, òpin kò sí, fífi ara ẹni fún wọn lápọ̀jù sì ń mú ẹran ara ṣàárẹ̀.” (Oníwàásù 12:12) Nígbà tí Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì kọ gbólóhùn yìí sílẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, kì í ṣe pé ó ní kéèyàn má kàwé o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń sọ ni pé ká ṣọ́ ohun tá a máa kà. Ìmọ̀ràn yẹn sì wúlò gan-an lákòókò tá a wà yìí, nítorí pé ọ̀kẹ́ àìmọye ìwé làwọn èèyàn ń tẹ̀ jáde lọ́dọọdún!
Ó dájú pé àwọn ìwé tí kò lè gbéni ró tàbí ṣeni láǹfààní ni “ìwé púpọ̀” tí Sólómọ́nì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Nítorí náà, ó fi yé wa pé béèyàn bá ń fi gbogbo àkókò rẹ̀ ka irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n á kàn máa “mú ẹran ara ṣàárẹ̀” dípò kí wọ́n kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ gidi kí wọ́n sì ṣeni láǹfààní tó máa wà títí lọ.
Àmọ́ o, ṣé ohun tí Sólómọ́nì wá ń sọ ni pé kò sáwọn ìwé tó lè fúnni ní ìtọ́sọ́nà gidi tó ṣeé gbára lé, táá sì ṣe ẹni tó ń kà á láǹfààní? Rárá o, ohun tó ń sọ kọ́ nìyẹn, nítorí ó tún kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n dà bí ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù, àti gẹ́gẹ́ bí ìṣó tí a gbá wọlé ni àwọn tí ó jọ̀wọ́ ara wọn fún àkójọ àwọn gbólóhùn; láti ọ̀dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn kan ni a ti fi wọ́n fúnni.” (Oníwàásù 12:11) Ká sòótọ́, àwọn ìwé kan wà tó jẹ́ pé bí “ọ̀pá kẹ́sẹ́ màlúù” ni wọ́n rí, tí wọ́n lè fúnni níṣìírí tó máa ranni lọ́wọ́. Àwọn ìwé yìí lè jẹ́ kéèyàn tọ ọ̀nà tó dára. Ìyẹn nìkan kọ́, “bí ìṣó tí a gbá wọlé,” wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ láti dúró lórí ìpinnu wa ká sì máa tọ ọ̀nà tó tọ́ nìṣó.
Ibo la ti wá lè rí àwọn ìwé tó ní irú àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ nínú? Gẹ́gẹ́ bí Sólómọ́nì ṣe sọ, èyí tó gbawájú lára irú àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ ni èyí tó wá látọ̀dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn kan, ìyẹn Jèhófà. (Sáàmù 23:1) Fún ìdí yìí, kò sóhun tó dára tó kéèyàn máa ká Bíbélì, ìwé tí Ọlọ́run mí sí. Kíka ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí déédéé lè jẹ́ ká dẹni tó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Tímótì 3:16, 17.