ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ohun Gbogbo Làkókò Wà Fún
    Ilé Ìṣọ́—2009 | March 1
    • Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì ò sọ̀rọ̀ nípa kádàrá àwa èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni ò sọ̀rọ̀ nípa àyànmọ́ ìgbésí ayé àwa ẹ̀dá, kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe àti bó ṣe máa nípa lórí àwa èèyàn. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ tẹ̀ lé ẹsẹ Bíbélì yẹn ló jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì ti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tí “ìgbà tí a yàn kalẹ̀” ti wà fún, ó kọ̀wé pé: “Mo ti rí iṣẹ́ àjókòótì tí Ọlọ́run fi fún àwọn ọmọ aráyé láti jókòó tì. Ohun gbogbo ni ó ti ṣe rèterète ní ìgbà tirẹ̀.”—Oníwàásù 3:10, 11.

      Sólómọ́nì mẹ́nu kan ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan tí Ọlọ́run ti fún àwa èèyàn láǹfààní láti ṣe. Ọlọ́run tún ti fún wa lómìnira láti máa yan ohun tó bá wù wá láti ṣe. Àmọ́ ṣá ó, gbogbo nǹkan ló ti ní àkókò tàbí ìgbà tó yẹ ká ṣe é, tá a bá fẹ́ kó yọrí síbi tó dáa. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tí Sólómọ́nì sọ nínú ìwé Oníwàásù 3:2 nípa “ìgbà gbígbìn àti ìgbà fífa ohun tí a gbìn tu.” Àwọn àgbẹ̀ mọ̀ pé ohun ọ̀gbìn kọ̀ọ̀kan ló ti ní àkókó tó yẹn káwọn gbìn ín. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ bí àgbẹ̀ kan bá kọ̀ láti gbin irè oko kan nígbà tó yẹ, tó wá lọ gbìn ín nígbà tí kò yẹ? Bó bá tiẹ̀ ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí irè oko yẹn lè so dáadáa, àmọ́ tí kò rí èso mú níbẹ̀, ṣé kádàrá ẹ̀ náà ló fà á? Rárá o! Òun ló kọ̀ láti gbin irè oko yẹn lákòókò tó yẹ. Bí àgbẹ̀ yẹn bá fara balẹ̀ tẹ̀ lé ètò tí Ẹlẹ́dàá ti ṣe nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí, kò ní kìka àbámọ̀ bẹnu.

      Torí náà, Ọlọ́run ò yan ohunkóhun mọ́ ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ ni kò kádàrá ìṣẹ̀lẹ̀ èyíkéyìí, àmọ́ ó ti ṣètò àwọn ìlànà kan tó ń nípa lórí àwọn nǹkan táwa èèyàn bá ṣe níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀. Táwa èèyàn bá fẹ́ ṣàṣeyọrí nínú àwọn nǹkan tá à ń dáwọ́ lé nígbèésí ayé wa, a gbọ́dọ̀ mohun tí Ọlọ́run fẹ́, ká sì ṣe é lákòókò tó yẹ. Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run bá ti pinnu láti ṣe nìkan làwa èèyàn ò lè yí pa dà, Ọlọ́rún ò kádàrá nǹkan kan mọ́ wa o. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde . . . kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.”—Aísáyà 55:11.

  • Ohun Gbogbo Làkókò Wà Fún
    Ilé Ìṣọ́—2009 | March 1
    • Bó O Ṣe Lè Mọ Àsìkò Ọlọ́run

      Sólómọ́nì sọ nǹkan kan tó máa jẹ́ kọ́rọ̀ yìí tètè yé wa dáadáa. Lẹ́yìn tó sọ pé: “Ohun gbogbo ni [Ọlọ́run] ti ṣe rèterète ní ìgbà tirẹ̀,” ó wá fi kún ọ̀rọ̀ ẹ̀ pé: “Àní àkókò tí ó lọ kánrin ni ó ti fi sínú ọkàn-àyà wọn, kí aráyé má bàa rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.” Bí Bibeli Yoruba Atọ́ka ṣe tú ẹsẹ Bíbélì yẹn rèé, ó ní: ‘Pẹ̀lúpẹ̀lù ó fi ayérayé sí wọn ní àyà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò lè rídìí iṣẹ́ náà tí Ọlọ́run ń ṣe láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ títí dé òpin.’—Oníwàásù 3:11.

      Onírúurú ọ̀rọ̀ làwọn èèyàn ti kọ lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí. Àmọ́ òótọ́ ọ̀rọ̀ kan tí kò ṣeé já ní koro ni pé, nínú ọkàn wa lọ́hùn-ún, ó fẹ́ẹ̀ máà sí ẹnì kan nínú wa tí kò tí ì ronú rí nípa ìdí tá a fi wà láyé àtohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wa. Látìgbà táláyé ti dáyé ni inú àwa èèyàn kì í ti í dùn sí bó ṣe jẹ́ pé lẹ́yìn gbogbo kòókòó jàn-ánjàn-án tá a bá fayé wa ṣe ikú ló pàpà máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀. Nínú gbogbo àwọn nǹkan alààyè yòókù, àwa èèyàn dá yàtọ̀ torí pé a kì í ronú nípa bá a ṣe fẹ́ gbé láyé nísinsìnyí nìkan, àmọ́ a tún ń ronú nípa ọjọ́ ọ̀la wa àtàwọn nǹkan tó fẹ́ ṣẹlẹ̀ lẹ́yìnwá ọ̀la. Kò tiẹ̀ sẹ́ni tó fẹ́ kú nínú wa pàápàá. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ, Ọlọ́run ti ‘fi ayérayé sí wa ní àyà.’

      Torí pé kò sẹ́ni tó fẹ́ kú làwọn kan ṣe máa ń ronú pé èèyàn ṣì máa ń wà láàyè nìṣó níbì kan lẹ́yìn tó bá kú. Àwọn kan sọ pé ohun kan wà nínú àwa èèyàn tó ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn tá a bá kú. Àwọn kan nígbàgbọ́ nínú àtúnwáyé, nígbà táwọn míì sì gbà gbọ́ pé kádàrá ló ń darí ìgbésí ayé àwa ẹ̀dá tàbí pé a ti yan àyànmọ́ wa látọ̀run, àti pé àyànmọ́ ò gbóògùn. Ó ṣeni láàánú pé, kò séyìí tó tẹ́ àwọn èèyàn lọ́rùn látòkèdélẹ̀ nínú gbogbo àwọn àlàyé wọ̀nyí. Ìdí ni pé, bí Bíbélì ṣe sọ, àwọn èèyàn ò lè tipasẹ̀ agbára wọn “rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.”

      Látìgbà táláyé ti dáyé làwọn ọ̀mọ̀ràn àtàwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí ti ń sapá láti mọ ọ̀pọ̀ nǹkan tó jẹ́ àwámárìídìí, àmọ́ ibi pẹlẹbẹ náà lọ̀bẹ wọn ń fi lélẹ̀. Àmọ́, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló fi ayérayé sí wa ní àyà tíyẹn sì ń jẹ́ kó máa wù wá láti fẹ́ máa wà láàyè, ṣé kò ní bọ́gbọ́n mu pé ká wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ ẹ̀, kọ́wọ́ wa lè tẹ ohun tó wù wá yẹn? Ó ṣe tán, Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” (Sáàmù 145:16) Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a máa ráwọn àlàyé tó máa tẹ́ wa lọ́rùn nípa ìgbésí ayé àti ikú títí kan àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fáwa èèyàn àti ilẹ̀ ayé wa lọ́jọ́ iwájú.—Éfésù 3:11.

  • Ọwọ́ Ẹ Ló Kù Sí
    Ilé Ìṣọ́—2009 | March 1
    • “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:27.

      ÀWỌN ọ̀rọ̀ tọ́pọ̀ èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó yìí, tó wà nínú ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn nǹkan tí Ọlọ́run “ti ṣe rèterète ní ìgbà tirẹ̀,” ìyẹn dídá tó dá Ádámù àti Éfà, tọkọtaya àkọ́kọ́ lẹ́ni pípé. (Oníwàásù 3:11) Torí pé Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá wọn, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́