ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Ẹ Tu Àwọn Ènìyàn Mi Nínú”
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
    • 17, 18. (a) Èé ṣe tí àwọn Júù tó wà nígbèkùn fi lè gbọ́kàn lé ìlérí ìmúbọ̀sípò náà? (b) Àwọn gbankọgbì ìbéèrè wo ni Aísáyà béèrè?

      17 Àwọn Júù tó wà nígbèkùn lè gbọ́kàn lé ìlérí ìmúbọ̀sípò tí Jèhófà ṣe nítorí pé Ọlọ́run jẹ́ Olódùmarè àti ọlọ́gbọ́n gbogbo. Aísáyà sọ pé: “Ta ni ó ti díwọ̀n omi nínú ìtẹkòtò ọwọ́ rẹ̀ lásán, tí ó sì ti fi ìbú àtẹ́lẹwọ́ lásán wọn ọ̀run pàápàá, tí ó sì ti kó ekuru ilẹ̀ ayé jọ sínú òṣùwọ̀n, tàbí tí ó fi atọ́ka-ìwọ̀n wọn àwọn òkè ńláńlá, tí ó sì wọn àwọn òkè kéékèèké nínú òṣùwọ̀n? Ta ni ó ti wọn ẹ̀mí Jèhófà, ta sì ni, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin tí ń gbà á nímọ̀ràn, tí ó lè mú kí ó mọ ohunkóhun? Ta ni òun bá fikùn lukùn, tí ẹnì kan fi lè mú kí ó lóye, tàbí kẹ̀, ta ni ó ń kọ́ ọ ní ipa ọ̀nà ìdájọ́ òdodo, tàbí tí ó ń kọ́ ọ ní ìmọ̀, tàbí tí ó ń mú kí ó mọ àní ọ̀nà òye gidi?”—Aísáyà 40:12-14.

      18 Gbankọgbì ìbéèrè nìwọ̀nyí fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn láti ronú lé lórí. Ǹjẹ́ ọmọ aráyé lè dá ìgbì àwọn òkun ńláǹlà dúró? Rárá o! Bẹ́ẹ̀ lójú Jèhófà, ńṣe ni àwọn òkun tó bo ilẹ̀ ayé dà bí ẹ̀kán omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀.b Ǹjẹ́ ọmọ adáríhurun lè díwọ̀n ìsálú ọ̀run tó lọ salalu, tó kún fún ìràwọ̀, tàbí pé kí ó wọn àwọn òkè ńlá àti òkè kéékèèké ayé lórí ìwọ̀n? Rárá o. Bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà díwọ̀n ìsálú ọ̀run tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn bí ìgbà téèyàn bá ń fi ìbú àtẹ́lẹwọ́ wọ̀n ọ́n, ìyẹn àlàfo tó wà láàárín àtàǹpàkò àti ọmọńdinrín bí a bá ya àtẹ́lẹwọ́ tán. Nípa bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run lè wọn àwọn òkè ńlá àti òkè kéékèèké lórí ìwọ̀n. Ǹjẹ́ àwọn tó tiẹ̀ gbọ́n jù lọ nínú ọmọ aráyé lè gba Ọlọ́run nímọ̀ràn nípa ohun tó lè ṣe sí ipò táyé wà lónìí, tàbí kí wọ́n sọ ohun tó yẹ kó ṣe lọ́jọ́ iwájú fún un? Ó dájú pé wọn ò lè ṣe bẹ́ẹ̀!

  • “Ẹ Tu Àwọn Ènìyàn Mi Nínú”
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
    • b Wọ́n ti ṣírò rẹ̀ pé “ìwọ̀n àwọn agbami òkun jẹ́ nǹkan bí 1.35 quintillion (1.35 x 1018) tọ́ọ̀nù lórí ìwọ̀n, ìyẹn ni pé, ká sọ pé a pín ìwọ̀n gbogbo Ilẹ̀ Ayé sí nǹkan bí ọ̀nà egbèjìlélógún [4,400], agbami òkun yóò kó ìdá kan rẹ̀.”—Encarta 97 Encyclopedia.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́