Àfi Bí Ẹlẹ́ǹgà
ÌWỌ ha ti rìn la pápá oko tútù kan kọjá rí ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí o sì rí àìmọye àwọn ẹlẹ́ǹgà tí wọ́n ń fò kúrò lójú ọ̀nà tí o ń tọ̀ bọ̀ bí? Ó dàbí ẹni pé wọ́n wà ní ibi gbogbo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ ti lè má fún wọn ní àfiyèsí tí ó pọ̀ tó. Ó ṣetán, wọ́n dàbí aláìlèpanilára àti aláìjámọ́ nǹkan.
Síbẹ̀, àìjámọ́ nǹkan àwọn ẹlẹ́ǹgà lọ́nà yìí mú kí wọ́n jẹ́ ohun ìṣàpẹẹrẹ aráyé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn gbajúmọ̀ ènìyàn kan lè ka araawọn sí pàtàkì lọ́nà gíga, Ẹlẹ́dàá wa ń ronú lọ́nà tí ó yàtọ̀. Wòlíì rẹ̀ Isaiah sọ pé: “Òun ni ẹni tí ó jókòó lórí òbìrí ayé, gbogbo àwọn tí ń gbé ibẹ̀ sì dàbí ẹlẹ́ǹgà.”—Isaiah 40:22.
Ìtóbilọ́lá Jehofa Ọlọrun, agbára, àti ọgbọ́n gbé e ga fíofío rékọjá ilẹ̀-ọba ènìyàn lásán, gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti tayọ rékọjá ẹlẹ́ǹgà ní òye àti agbára. Bí ó ti wù kí ó rí, ànímọ́ gíga jùlọ tí Ọlọrun ni ìfẹ́. Ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ rẹ̀ sì sún un láti ṣàkíyèsí wa, ràn wá lọ́wọ́, kí ó sì dáàbòbò wá—bí àwa bá nífẹ̀ẹ́ tí a sì ṣègbọràn sí i. Jehofa ń fi ìfẹ́ bá wa lò, bi ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa dàbí àwọn ẹlẹ́ǹga tí kò jámọ́ nǹkan. Olórin náà wí pé: “Ta ni ó dàbí Oluwa Ọlọrun wa, tí ó ń gbé ibi gíga. Ẹni tí ó rẹ araarẹ̀ sílẹ̀ láti wo ohun tí ó wà ní ọ̀run àti ní ayé! Ó gbé tálákà [“ẹni rírẹlẹ̀,” NW] sókè láti inú erùpẹ̀ wá.”—Orin Dafidi 113:5-7.
Bí orin yìí ṣe ṣàlàyé, Jehofa fi tìfẹ́tìfẹ́ nawọ́ ìrànlọ́wọ́ sí àwọn ẹni rírẹlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ni, Òun ń ran àwọn tí wọ́n fi pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ‘wá Ọlọrun kí wọ́n lè rí i níti gidi’ lọ́wọ́. (Iṣe 17:27) Àwọn tí wọ́n ń wá Ọlọrun—tí wọ́n sì ṣiṣẹ́sìn ín—tilẹ̀ ṣeyebíye ní ojú rẹ̀. (Fiwé Isaiah 43:4, 10.) Ẹlẹ́ǹgà rírẹlẹ̀ náà tipa báyìí ṣiṣẹ́ láti rán wá létí nípa àìjámọ́ nǹkan tiwa fúnraawa àti nípa ìfẹ́ atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa, ẹni tí ó fi ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àti inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ jíǹkí àwọn ènìyàn onígbọràn. Ìwọ ha ń fi ìmọrírì hàn fún ìfẹ́ Ọlọrun bi?