-
“Ẹ Tu Àwọn Ènìyàn Mi Nínú”Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
-
-
28, 29. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe rán àwọn èèyàn rẹ̀ létí pé òun yóò ṣèrànwọ́ fún àwọn tó ti rẹ̀? (b) Àpèjúwe wo ni Jèhófà lò láti fi bí òun ṣe ń fún àwọn ìránṣẹ́ òun lágbára hàn?
28 Jèhófà wá gbẹnu Aísáyà ń bá a lọ láti fún àwọn ìgbèkùn tọ́ràn ti sú pátápátá yìí ní ìṣírí, ó ní: “Ó ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀; ó sì ń mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi fún ẹni tí kò ní okun alágbára gíga. Àárẹ̀ yóò mú àwọn ọmọdékùnrin, agara yóò sì dá wọn, àwọn ọ̀dọ́kùnrin pàápàá yóò sì kọsẹ̀ dájúdájú, ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà yóò jèrè agbára padà. Wọn yóò fi ìyẹ́ apá ròkè bí idì. Wọn yóò sáré, agara kì yóò sì dá wọn; wọn yóò rìn, àárẹ̀ kì yóò sì mú wọn.”—Aísáyà 40:29-31.
29 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀ràn ìrìn àjò tó nira, tí àwọn ìgbèkùn yóò ní láti rìn láti padà sílé, ni Jèhófà ní lọ́kàn nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa fífún ẹni tó ti rẹ̀ ní agbára. Jèhófà rán àwọn èèyàn rẹ̀ létí pé ó jẹ́ àṣà òun láti ṣèrànwọ́ fáwọn ẹni tó ti rẹ̀ tó bá yíjú sí òun fún ìtìlẹyìn. Àní ó tiẹ̀ lè rẹ àwọn tó ń ta kébékébé nínú ọmọ ènìyàn, ìyẹn “àwọn ọmọdékùnrin” àti “àwọn ọ̀dọ́kùnrin,” kí ó rẹ̀ wọ́n tẹnutẹnu, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kọsẹ̀ pàápàá. Síbẹ̀, Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò pèsè agbára fún ẹni tó bá gbẹ́kẹ̀ lé òun, ìyẹn agbára láti sáré àti láti rìn láìkáàárẹ̀. Fífò tí ìdí ń fò fẹẹ bíi pé kò tiẹ̀ ṣe ìsapá kankan, ìyẹn ẹyẹ alágbára tó lè máa rá bàbà fún ọ̀pọ̀ wákàtí láìdáwọ́dúró, ni Jèhófà lò láti fi ṣàpèjúwe bí òun ṣe máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ òun lágbára.e Níwọ̀n bí àwọn Júù tó wà nígbèkùn ti ń retí àtirí irú ìtìlẹyìn bẹ́ẹ̀ gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kò sí ìdí fún wọn láti sọ̀rètí nù.
-
-
“Ẹ Tu Àwọn Ènìyàn Mi Nínú”Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
-
-
30. Báwo ní àwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní ṣe lè rí ìtùnú gbà látinú àwọn ẹsẹ tó parí Aísáyà orí ogójì?
30 Àwọn ẹsẹ tó parí Aísáyà orí ogójì yìí ní ọ̀rọ̀ ìtùnú nínú fáwọn Kristẹni tòótọ́ tó ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò nǹkan burúkú yìí. Bí pákáǹleke àti àwọn ìṣòro tó ń fẹ́ máa páni láyà ṣe pọ̀ gan-an yìí, ìfọ̀kànbalẹ̀ ló máa ń jẹ́ fúnni láti mọ̀ pé kò sí ìṣòro tí a ń forí tì tàbí ìwà ìyànjẹ tí wọ́n ń hù sí wa tí Ọlọ́run wa kò rí. Kí ó dá wa lójú pé Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, Ẹni tí “òye rẹ̀ ré kọjá ríròyìn lẹ́sẹẹsẹ,” yóò mú gbogbo ìwà ìyànjẹ kúrò lákòókò tirẹ̀ àti lọ́nà tirẹ̀. (Sáàmù 147:5, 6) Àmọ́ kó tó di ìgbà náà, kì í ṣe agbára tiwa la óò máa lò láti máa fi forí tì í. Jèhófà, ẹni tí agbára rẹ̀ ò lè pin láéláé, lè pèsè agbára, àní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lásìkò àdánwò.—2 Kọ́ríńtì 4:7.
-
-
“Ẹ Tu Àwọn Ènìyàn Mi Nínú”Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
-
-
e Agbára tí ìdí ń lò láti fi máa rá bàbà kì í tó nǹkan. Àwọn afẹ́fẹ́ olóoru tó ń fẹ́ lọ sókè sójú sánmà ló máa ń fọgbọ́n lò láti fi fò.
-