ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ègbé Ni fún Ọgbà Àjàrà Aláìṣòótọ́!
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
    • 6, 7. (a) Ta ló ni ọgbà àjàrà náà, kí sì ni ọgbà àjàrà yẹn? (b) Ẹjọ́ wo ni ọlọ́gbà àjàrà náà ní kí wọ́n dá?

      6 Ta ló ni ọgbà àjàrà yẹn, kí sì ni ọgbà àjàrà náà? Ọlọ́gbà àjàrà náà jẹ́ ká rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí nígbà tóun fúnra rẹ̀ sọ pé: “Wàyí o, ẹ̀yin olùgbé Jerúsálẹ́mù àti ẹ̀yin ènìyàn Júdà, ẹ jọ̀wọ́, ẹ ṣe ìdájọ́ láàárín èmi àti ọgbà àjàrà mi. Kí ni ó tún kù tí ó yẹ kí n ṣe fún ọgbà àjàrà mi tí n kò tíì ṣe sínú rẹ̀? Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé mo ń retí pé kí ó so èso àjàrà, ṣùgbọ́n tí ó so èso àjàrà ìgbẹ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀? Wàyí o, ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí èmi yóò ṣe sí ọgbà àjàrà mi di mímọ̀ fún yín: Ìmúkúrò ọgbà ààbò rẹ̀ yóò ṣẹlẹ̀, yóò sì di sísun kanlẹ̀. Ìwólulẹ̀ ògiri òkúta rẹ̀ yóò ṣẹlẹ̀, yóò sì di ibi ìtẹ̀mọ́lẹ̀.”—Aísáyà 5:3-5.

  • Ègbé Ni fún Ọgbà Àjàrà Aláìṣòótọ́!
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
    • 9. Báwo ni Jèhófà ṣe bójú tó orílẹ̀-èdè rẹ̀, bí ọgbà àjàrà tó ṣeyebíye?

      9 Jèhófà ‘gbin’ orílẹ̀-èdè rẹ̀ sí ilẹ̀ Kénáánì, ó sì fún wọn ní àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀, tó jẹ́ bí ògiri tó dáàbò bò wọ́n, kí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù má bàa kó ìwà ìbàjẹ́ ràn wọ́n. (Ẹ́kísódù 19:5, 6; Sáàmù 147:19, 20; Éfésù 2:14) Síwájú sí i, Jèhófà fún wọn ní àwọn onídàájọ́, àlùfáà, àti wòlíì tí yóò máa kọ́ wọn. (2 Àwọn Ọba 17:13; Málákì 2:7; Ìṣe 13:20) Nígbà tí ogun ń bá Ísírẹ́lì fínra, Jèhófà gbé àwọn olùdáǹdè dìde fún wọn. (Hébérù 11:32, 33) Ìyẹn ni Jèhófà fi béèrè pé: “Kí ni ó tún kù tí ó yẹ kí n ṣe fún ọgbà àjàrà mi tí n kò tíì ṣe sínú rẹ̀?”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́