ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run Rẹ, Yóò Di Ọwọ́ Ọ̀tún Rẹ Mú”
    Ilé Ìṣọ́—2012 | January 1
    • “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run Rẹ, Yóò Di Ọwọ́ Ọ̀tún Rẹ Mú”

      BÍ BÀBÁ kan àti ọmọ rẹ̀ ṣe fẹ́ sọdá ọ̀nà tí ohun ìrìnnà àti èrò pọ̀ sí, ó sọ fún ọmọ náà pé “di ọwọ́ mi mú dáadáa.” Nítorí pé bàbá náà fúnra rẹ̀ di ọwọ́ ọmọ náà mú dáadáa, ọmọ yìí kò ní bẹ̀rù, torí yóò ti gbà pé kò séwu fóun rárá. Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ìwọ náà bíi pé kó o rí ẹni tó máa mú ọ la gbogbo wàhálà àti ìdààmú tó wà nínú ayé yìí já? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Aísáyà lè tù ọ́ nínú.—Ka Aísáyà 41:10, 13.

      Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni Aísáyà darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí sí. Ọlọ́run kà wọ́n sí “àkànṣe dúkìá” rẹ̀, àmọ́ àárín ọ̀tá ni wọ́n ń gbé. (Ẹ́kísódù 19:5) Ǹjẹ́ ó yẹ kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì máa bẹ̀rù? Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ̀rọ̀ kan fún wọn tó fini lọ́kàn balẹ̀. Bí a ó ṣe máa gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé ọ̀rọ̀ yẹn kan àwa tá à ń sin Ọlọ́run lónìí.—Róòmù 15:4.

  • “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run Rẹ, Yóò Di Ọwọ́ Ọ̀tún Rẹ Mú”
    Ilé Ìṣọ́—2012 | January 1
    • Kí ni Jèhófà yóò wá ṣe fún àwọn olùjọsìn rẹ̀? Ó ṣèlérí fún wọn pé: “Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.” (Ẹsẹ 10) Ó sì tún sọ pé: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú.” (Ẹsẹ 13) Èrò wo ni gbólóhùn méjèèjì yìí gbé wá sí ọ lọ́kàn? Ìwé kan tí a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Téèyàn bá wo ẹsẹ méjèèjì yìí pa pọ̀, ṣe ló ń múni ronú nípa ọ̀rọ̀ òbí kan àti ọmọ rẹ̀. [Bàbá yìí] kò kàn dúró sí ìtòsí ọmọ rẹ̀ láti lè gbà á sílẹ̀ nígbà ewu. Ṣe lòun àti ọmọ náà jọ wà pa pọ̀; kò sì ní jẹ́ kí ohunkóhun pín òun àti ọmọ náà níyà.” Ìwọ rò ó wò ná, Jèhófà kò ní jẹ́ kí ohunkóhun pín òun àti àwọn èèyàn rẹ̀ níyà, kódà láwọn àsìkò tó lè dà bíi pé ìṣòro fẹ́ pin wọ́n lẹ́mìí.—Hébérù 13:5, 6.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́