ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 3/15 ojú ìwé 24-25
  • Ó Rí Ìmúṣẹ Ìfẹ́-Ọkàn Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Rí Ìmúṣẹ Ìfẹ́-Ọkàn Rẹ̀
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Messia Fúnni Ní Ìrètí
  • Síbẹ̀ Kò Tíì Sí Messia!
  • Ọkùnrin Olùfọkànsìn Kan
  • Àwọn Ọ̀rọ̀ Alásọtẹ́lẹ̀ Simeoni
  • Gbólóhùn Simeoni sí Maria
  • Simeoni Lo Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Messia
  • Ọmọ Ileri Naa
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Ọmọ Tí Ọlọ́run Ṣèlérí
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Bí O Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ó Dé ‘Ìparí Èrò Nínú Ọkàn Rẹ̀’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 3/15 ojú ìwé 24-25

Ó Rí Ìmúṣẹ Ìfẹ́-Ọkàn Rẹ̀

ÓHA jẹ́ ìfẹ́-ọkàn rẹ láti rí i kí Ìjọba Messia tẹ́wọ́gba ìṣàkóso lórí gbogbo ilẹ̀-ayé bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ ń yánhànhàn o sì ń gbàdúrà fún àwọn ìbùkún orí ilẹ̀-ayé tí a ṣèlérí lábẹ́ Ìjọba ọ̀run yẹn. Nígbà náà, ní sùúrù nítorí pé “nígbà tí [ohun tí a lọ́kàn-ìfẹ́ sí bá dé, NW] igi ìyè ni.”​—⁠Owe 13:12; Jakọbu 5:​7, 8.

Ní nǹkan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 2,000 ọdún sẹ́yìn, Simeoni ọkùnrin kan tí ó jẹ́ “olóòótọ́ àti olùfọkànsìn” gbé ní Jerusalemu. Ó ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Messia ó sì ń fi sùúrù “retí ìtùnú Israeli.”​—⁠Luku 2:⁠25.

Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Messia Fúnni Ní Ìrètí

Jehofa ni orísun àsọtẹ́lẹ̀ Messia àkọ́kọ́​—⁠ọ̀kan tí ó fún aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ àti ẹni kíkú ní ìrètí. Ọlọrun sàsọtẹ́lẹ̀ wíwá Irú-Ọmọ “obìnrin” rẹ̀, tàbí ètò-àjọ àgbáyé.​—⁠Genesisi 3:⁠15.

Ẹni yẹn ni a fihàn pé ó jẹ́ irú-ọmọ Abrahamu, Jakọbu sì sàsọtẹ́lẹ̀ wíwá rẹ̀. (Genesisi 22:17, 18; 49:10) Àwọn ògo Ìjọba Messia náà ni a kókìkí nínú àwọn psalmu. (Orin Dafidi 72:​1-⁠20) Isaiah sọtẹ́lẹ̀ pé Irú-Ọmọ náà ni a óò bí nípasẹ̀ wúndíá, Mika sì sọtẹ́lẹ̀ pé ìbí rẹ̀ yóò wáyé ní Betlehemu. (Isaiah 7:14; Mika 5:⁠2) Ìwọ̀nyí jẹ́ ìwọ̀nba díẹ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Messia.

Síbẹ̀ Kò Tíì Sí Messia!

Ronú padà sí ìgbà tí ó ti kọjá, kí o sì wòye pé ọ̀rúndún kìn-⁠ín-⁠ní C.E. ti ń súnmọ́lé. Àsọtẹ́lẹ̀ Messia tí Ọlọrun sọ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ti pé 4,000 ọdún nísinsìnyí. Àwọn Ju ti ní ìrírí ìparun tẹ́ḿpìlì Jehofa, ìsọdahoro ilẹ̀-ìbílẹ̀ wọn, ìkónígbèkùn aláàádọ́rin ọdún lọ sí Babiloni, àti 500 ọdún síi lábẹ́ ìtẹnilóríba àwọn Alákòóso Kèfèrí. Síbẹ̀ kò tíì sí Messia!

Ẹ wo bí àwọn Ju olùbẹ̀rù Ọlọrun ti yánhànhàn fún wíwá Messia tó! Ìbùkún yóò ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣàn dé ọ̀dọ̀ wọn àti dé gbogbo orílẹ̀-èdè.

Ọkùnrin Olùfọkànsìn Kan

Lára àwọn Ju olùfọkànsìn tí wọ́n ń yánhànhàn tí wọ́n sì ń gbàdúrà fún wíwá Messia ní Simeoni, àgbàlagbà olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jehofa kan tí ń gbé nínú ìlú-ńlá tíí ṣe olú-ìlú Judea. Ohun kan tí ó jẹ́ àkànṣe ti ṣẹlẹ̀ sí Simeoni.

Ọlọrun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ sára Simeoni ó sì ti san èrè fún un nípasẹ̀ ìṣípayá. Simeoni kì yóò kú títí tí yóò fi rí Ẹni náà tí yóò jẹ́ Messia. Ṣùgbọ́n ọjọ́ àti oṣù ń kọjá lọ. Simeoni ń darúgbó èkukáká ni ó sì fi lè réti láti gbé pẹ́ síi. Ìlérí Ọlọrun fún un yóò ní ìmúṣẹ bí?

Ní ọjọ́ kan (ní 2 B.C.E.), tọkọtaya alárédè kan pẹ̀lú ọmọ lọ́wọ́ wá sí tẹ́ḿpìlì láti Betlehemu. Ẹ̀mí Mímọ́ ṣíi payá fún Simeoni pé èyí ni ọjọ́ náà tí ó ti ń dúró dè fún ìgbà pípẹ́. Ó lọ sí tẹ́ḿpìlì, níbi tí yóò ti rí Ẹni náà tí àwọn wòlíì ti kọ̀wé nípa rẹ̀. Ní yíyára bí ara rẹ̀ tí ó ti dogbó ti lè yọ̀ọ̀da fún un tó, ó rí Josefu, Maria, àti ọmọ náà.

Ẹ sì wo bí ayọ̀ tí Simeoni fi gbé ọmọ náà Jesu sí ọwọ́ rẹ̀ tí pọ̀ tó! Ẹni yìí ni yóò jẹ́ Messia náà tí a ṣèlérí​—⁠“Kristi Oluwa.” Ní irú ọjọ́ ogbó bẹ́ẹ̀, Simeoni kò lè retí láti ríi kí Jesu ṣàṣeparí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé. Síbẹ̀, ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ láti rí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ọwọ́ kan. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Messia ti bẹ̀rẹ̀ síí ní ìmúṣẹ. Ẹ wo bí Simeoni ti láyọ̀ tó! Nísinsìnyí yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn láti sùn nínú ikú títí di ìgbà àjíǹde.​—⁠Luku 2:​25-⁠28.

Àwọn Ọ̀rọ̀ Alásọtẹ́lẹ̀ Simeoni

Bí Simeoni ti gbé ohùn rẹ̀ sókè láti yin Jehofa, a gbọ́ ọ tí ó sọ pé: “Oluwa, nígbà yìí ni o tó jọ̀wọ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ lọ́wọ́ lọ ní àlàáfíà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ: nítorí tí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ ná, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ níwájú ènìyàn gbogbo; ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn Keferi, àti ògo Israeli ènìyàn rẹ. Ẹnu sì ya Josefu àti ìyá rẹ̀ sí nǹkan tí a ń sọ sí i wọ̀nyí.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ń báa lọ láti máa jẹ́ kàyéfì fún bàbá alágbàtọ́ Jesu, Josefu, àti ìyá Rẹ̀, Maria.​—⁠Luku 2:​29-⁠33.

Ìrísí-ojú Simeoni mọ́lẹ̀ yòò bí ó ti ń súre fún Josefu àti Maria, ẹ̀rí fihàn pé ó ń tọrọ ìbùkún Jehofa fún wọn láti lè mú àwọn ẹrù-iṣẹ́ wọn nípa ọmọ náà ṣẹ. Lẹ́yìn náà ni ojú ọkunrin arúgbó náà yípadà. Ní dídarí ọ̀rọ̀-àkíyèsí rẹ̀ sí Maria nìkan, ó fikún un pé: “Kíyèsí i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Israeli; àti fún àmì tí a ń sọ̀rọ̀ òdì sí; (idà yóò sì gún ìwọ náà ní ọkàn pẹ̀lú), ki a lè fi ìrònú ọ̀pọ̀ ọkàn hàn.”​—⁠Luku 2:​34, 35.

Gbólóhùn Simeoni sí Maria

Ronu bí ìmọ̀lára Maria yóò ti rí. Kí ni Simeoni ní lọ́kàn? Àwọn kan yóò gba Kristi a óò sì gbé wọn dìde kúrò nínú ipò ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti wà. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn mìíràn yóò kọ̀ ọ́, wọn yóò kọsẹ̀ lára rẹ̀, wọn yóò sì ṣubú. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọtẹ́lẹ̀, ẹ̀rí fihàn pé Jesu jẹ́ òkúta ìdìgbòlù fún ọ̀pọ̀ àwọn Ju. (Isaiah 8:14; 28:16) Àwọn ọ̀rọ̀ Simeoni kò túmọ̀sí pé àwọn ọmọ Israeli lẹ́nìkọ̀ọ̀kan yóò kọ́kọ́ ṣubú sínú àìgbàgbọ́ tí wọn yóò sì dìde nínú ìgbàgbọ́ nípa gbígba Jesu. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀nà tí àwọn ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yóò gbà hùwàpadà sí i yóò yàtọ̀síra, ní fífi ìrònú ọ̀pọ̀ ọkàn hàn àti ṣíṣamọ̀nà sí ìdájọ́ Ọlọrun síhà ọ̀dọ̀ wọn fún rere tàbí búburú. Fún àwọn aláìgbàgbọ́, òun yóò jẹ́ àmì kan, tàbí ohun tí a ń sọ̀rọ̀ òdì sí. Nípa níní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, àwọn ẹlòmíràn ni a óò gbé dìde láti inú ikú ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀, tí wọn yóò sì wá gbádùn ìdúró òdodo pẹ̀lú Ọlọrun. Ìṣarasíhùwà àwọn ènìyàn sí Messia náà yóò fi ohun tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà wọn hàn.

Kí ni nípa ti àwọn ọ̀rọ̀ Simeoni pé: “Idà yóò sì gún ìwọ náà ní ọkàn pẹ̀lú”? Kò sí ìtọ́ka Ìwé Mímọ́ pé a fi idà gidi gun Maria. Síbẹ̀, kíkọ̀ tí àwọn tí ó pọ̀ jùlọ kọ Jesu yóò kó ìdààmú bá a. Ẹ sì wo bí ó ti ro Maria lára tó láti rí i tí a kan Jesu mọ́ òpó-igi kan! Èyí dàbí fífi idà kan gún un.

Simeoni Lo Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Messia

Ẹ̀mí Ọlọrun ti sún Simeoni láti lo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Messia fún Jesu. Simeoni lè fi ayé yìí sílẹ̀ ní àlàáfíà, tàbí ìdákẹ́jẹ́ẹ́, ‘nítorí tí ojú rẹ̀ ti rí ìgbàlà Ọlọrun tí ó ti pèsè sílẹ̀ níwájú ènìyàn gbogbo; ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn Keferi, àti ògo Israeli ènìyàn rẹ̀.’ (Luku 2:​30-⁠32) Ẹ wo bí èyí ti níí ṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Isaiah tó!

Wòlíì náà sọtẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì fi ògo Oluwa hàn, gbogbo ẹran-ara ni yóò jùmọ̀ rí i.” “Èmi [Jehofa] óò sì fi ọ́ [Messia] ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn Kèfèrí, kí ìwọ kí ó lè ṣe ìgbàlà mi títí dé òpin ayé.” (Isaiah 40:5; 42:6; 49:6; 52:10) Àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Griki àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣeéfojúrí ti fihàn láti ìgbà yìí wá pé Messia náà, Jesu Kristi, ni ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè, Ẹni náà tí yóò mú ìbòjú òkùnkùn tẹ̀mí kúrò tí yóò sì mú ìgbàlà wá fún àwọn ènìyàn.

Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò sọ jù bẹ́ẹ̀ lọ nípa Simeoni arúgbó. Ẹ̀rí fihàn pé ó kú ṣáájú kí Kristi tó ṣí ọ̀nà sí ìwàláàyè lókè ọ̀run sílẹ̀. Nígbà náà, láìpẹ́, Simeoni ni a óò jí dìde sí ìye lórí ilẹ̀-ayé. Ẹ wo ayọ̀ tí òun​—⁠àti ìwọ​—⁠lè ní ìrírí rẹ̀ nínú ayé titun lábẹ́ Ìjọba Messia Ọlọrun!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́