ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀—Fun Ète Wo?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1993 | January 15
    • Ẹni Naa Ti A Fifunni “Gẹgẹ bi Ìmọ́lẹ̀ Awọn Orilẹ-ede”

      6. Awọn ifojusọna ńláǹlà wo ni Jehofa ti mú ki ó ṣeeṣe fun wa nipasẹ Jesu Kristi?

      6 Àní ṣaaju ki a tó lé Adamu ati Efa jade kuro ninu Paradise, Jehofa sọ asọtẹlẹ “iru-ọmọ” kan ti yoo jẹ́ oludande awọn olufẹ òdodo. (Genesisi 3:15) Lẹhin ìbí ẹ̀dá eniyan Iru-ọmọ ti a ṣeleri yẹn, Jehofa mú ki Simeoni arugbo, ni tẹmpili ni Jerusalemu, fi ẹni yẹn hàn gẹgẹ bi “ìmọ́lẹ̀ kan lati mu ìbòjú kuro loju awọn orilẹ-ede.” (Luku 2:29-32, NW) Nipasẹ igbagbọ ninu ẹbọ iwalaaye ẹ̀dá eniyan pípé ti Jesu, iran eniyan lè ri itura kuro lọwọ idalẹbi ti ń jẹyọ lati inu ẹṣẹ ti a bí mọ́ wa. (Johannu 3:36) Ni ibamu pẹlu ifẹ-inu Jehofa, wọn lè fojusọna nisinsinyi fun ìyè ayeraye ninu ijẹpipe gẹgẹ bi apakan Ijọba ọrun tabi gẹgẹ bi ọmọ-abẹ́ rẹ̀ ninu paradise lori ilẹ̀-ayé. Ẹ wo iru ipese agbayanu ti iyẹn jẹ!

      7. Eeṣe ti awọn ileri ni Isaiah 42:1-4 ati imuṣẹ ti wọn ní ní ọrundun kìn-ín-ní ṣe fi ireti kún inu wa?

      7 Jesu Kristi fúnraarẹ̀ ni ẹri-idaniloju imuṣẹ awọn ifojusọna titobilọla wọnyi. Ni isopọ pẹlu mímú ti Jesu mú awọn eniyan ti a pọnloju larada, aposteli Matteu fi ohun ti a kọsilẹ ninu Isaiah 42:1-4 silo fun un. Ẹsẹ iwe mimọ yẹn sọ, ni apakan pe: “Wo iranṣẹ mi, ẹni ti mo yàn; ayanfẹ mi, ẹni ti inu mi dùn si gidigidi: emi o fi ẹmi mi fun un, yoo sì fi idajọ hàn fun awọn [orilẹ-ede, NW].” Kìí ha ṣe ohun ti awọn eniyan orilẹ-ede gbogbo nilo niyi bi? Asọtẹlẹ naa ń baa lọ pe: “Oun ki yoo jà, ki yoo sì kigbe, bẹẹ ni ẹnikẹni ki yoo jẹ ki a gbọ́ ohùn rẹ̀ ni igboro. Iyè fífọ́ ni oun ki yoo ṣẹ́, òwú fitila ti ń rú eefin ni oun ki yoo sì pa.” Ni ibamu pẹlu eyi, Jesu kò lekoko mọ́ awọn eniyan ti a ti ń pọnloju tẹlẹ. O fi aanu hàn fun wọn, o kọ́ wọn nipa awọn ète Jehofa, o sì wò wọn sàn.—Matteu 12:15-21.

      8. Ni èrò itumọ wo ni Jehofa ti gba fi Jesu funni “gẹgẹ bi majẹmu awọn eniyan” ati “gẹgẹ bi imọlẹ awọn orilẹ-ede”?

      8 Olufunni ni asọtẹlẹ yii dari afiyesi rẹ̀ si Iranṣẹ rẹ̀, si Jesu, ó sì wi pe: “Emi [Jehofa] ni o ti pe ọ ninu òdodo, emi o si di ọwọ́ rẹ mú, emi o si pa ọ mọ́, emi o si fi ọ ṣe majẹmu awọn eniyan, ìmọ́lẹ̀ awọn [orilẹ-ede, NW]. Lati la oju awọn afọju, lati mú awọn onde kuro ninu túbú, ati awọn ti o jokoo ni okunkun kuro ni ile túbú.” (Isaiah 42:6, 7) Bẹẹni, Jehofa ti pese Jesu Kristi gẹgẹ bii majẹmu kan, gẹgẹ bi ẹri-idaniloju ileri wiwuwo kan. Ẹ wo bi iyẹn ti ń funni niṣiiri tó! Jesu fi idaniyan tootọ hàn fun iran-araye nigba ti o wà lori ilẹ̀-ayé; o tilẹ tun fi iwalaaye rẹ̀ lélẹ̀ fun araye. Eyi ni ẹni naa ti Jehofa ti fa iṣakoso lori gbogbo orilẹ-ede lé lọwọ. Abajọ ti Jehofa fi tọka si i gẹgẹ bi ìmọ́lẹ̀ awọn orilẹ-ede. Jesu funraarẹ sọ pe: “Emi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”—Johannu 8:12.

      9. Eeṣe ti Jesu kò fi fi araarẹ̀ fun mímú eto-igbekalẹ awọn nǹkan ti ń bẹ nigba naa sunwọn sii?

      9 Fun ète wo ni Jesu ṣiṣẹsin gẹgẹ bi ìmọ́lẹ̀ ayé? Dajudaju kìí ṣe fun ète ti ara tabi ti ọrọ̀ àlùmọ́nì. O kọ̀ lati gbiyanju lati ṣe atunṣe tabi mú eto-igbekalẹ oṣelu ti o wà nigba naa sunwọn sii oun kò sì ni tẹwọgba ipo ọba yala lati ọwọ Satani, oluṣakoso ayé, tabi lati ọwọ́ awọn eniyan. (Luku 4:5-8; Johannu 6:15; 14:30) Jesu fi ìyọ́nú ti o ga hàn fun awọn ti a pọnloju ti o si pese itura fun wọn ni ọna ti awọn miiran kò lè gbà ṣe é. Ṣugbọn o mọ̀ pe itura pipẹtiti ni a kò lè rí ninu ọna-igbekalẹ ẹgbẹ́ awujọ eniyan kan ti o wà labẹ idalẹbi atọrunwa nitori ẹṣẹ ti a bí mọ́ wa ti a si ń dọgbọn dari rẹ̀ lati ọwọ́ awọn agbara ẹmi airi buburu. Pẹlu òye-inú ti Ọlọrun ń funni, Jesu gbé gbogbo igbesi-aye rẹ kari ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun.—Heberu 10:7.

      10. Ni awọn ọ̀nà wo ati fun ète wo ni Jesu fi ṣiṣẹsin gẹgẹ bi ìmọ́lẹ̀ ayé?

      10 Ni awọn ọ̀nà wo ati fun ète wo, nigba naa, ni Jesu gba ṣiṣẹsin gẹgẹ bi ìmọ́lẹ̀ ayé? O ya araarẹ̀ sọtọ fun wiwaasu ihinrere Ijọba Ọlọrun. (Luku 4:43; Johannu 18:37) Nipa jijẹrii si otitọ nipa ète Jehofa, Jesu tun ṣe orukọ Baba rẹ̀ ọrun lógo. (Johannu 17:4, 6) Ni afikun si eyi, gẹgẹ bi ìmọ́lẹ̀ ayé, Jesu tudii aṣiri awọn isin èké ti o si tipa bayii pese ominira tẹmi fun awọn wọnni ti a fi sabẹ ìsìnrú isin. Ó tú Satani fó gẹgẹ bi ẹni aiṣeeri ti ó ń dọgbọn dari awọn wọnni ti wọn ba yọnda araawọn fun un lati lò. Jesu tun fi awọn iṣẹ ti ó jẹ́ ti okunkun hàn. (Matteu 15:3-9; Johannu 3:19-21; 8:44) Lọna ti o hàn gbangba-gbàǹgbà, oun fẹ̀rí hàn pe oun jẹ ìmọ́lẹ̀ ayé nipa fifi iwalaaye ẹda eniyan pipe rẹ̀ lelẹ gẹgẹ bi irapada, nipa bayii o ṣí ọ̀nà silẹ fun awọn wọnni ti wọn lo igbagbọ ninu ipese yii lati ni idariji ẹṣẹ, ibatan ti o ṣetẹwọgba pẹlu Ọlọrun, ati ifojusọna fun iwalaaye titilae gẹgẹ bi apakan idile agbaye Jehofa. (Matteu 20:28; Johannu 3:16) Ni paripari rẹ̀, nipa pipa ifọkansin pipe si Ọlọrun mọ́ jalẹ gbogbo igbesi-aye rẹ̀, Jesu di ipo ọba-alaṣẹ Jehofa mú ó sì fi Eṣu hàn bi opurọ kan, ó tipa bayii mú ki anfaani ayeraye ṣeeṣe fun awọn olufẹ òdodo. Ṣugbọn Jesu nikanṣoṣo ni o ha yẹ ki o jẹ olùtan ìmọ́lẹ̀ bi?

  • Awọn Olùtan Ìmọ́lẹ̀—Fun Ète Wo?
    Ilé-Ìṣọ́nà—1993 | January 15
    • 12. (a) Ìwọ̀n wo ni ó yẹ́ ki ìmọ́lẹ̀ tẹmi gbooro dé? (b) Ki ni ẹmi Jehofa mú ki ó ṣeeṣe fun Paulu lati fòyemọ̀ nipa Isaiah 42:6, bawo sì ni asọtẹlẹ yẹn ṣe nilati nipa lori igbesi-aye wa?

      12 Bi o ti wu ki o ri, wiwaasu ihinrere naa ni a kò nilati fimọ si pápá yẹn nikan. Jesu fun awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ni itọni lati maa ‘sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin.’ (Matteu 28:19) Lakooko iyilọkanpada Saulu ará Tarsu, Oluwa fihàn ni pato pe Saulu (ẹni ti o di aposteli Paulu) yoo waasu kìí ṣe fun awọn Ju nikan ni ṣugbọn fun awọn Keferi pẹlu. (Iṣe 9:15) Pẹlu iranlọwọ ẹmi mimọ, Paulu wá mọriri ohun ti iyẹn ni ninu. Nipa bayii, o woye pe asọtẹlẹ ti ó wà ninu Isaiah 42:6, eyi ti o ni imuṣẹ taarata ninu Jesu Kristi, tun jẹ aṣẹ ti a pẹ́sọ fun gbogbo awọn ti o bá lo igbagbọ ninu Kristi. Nitori naa, ni Iṣe 13:47, nigba ti o fa ọ̀rọ̀ yọ lati inu Isaiah, Paulu sọ pe: “Oluwa sá ti paṣẹ fun wa pe, Mo ti gbe ọ kalẹ fun ìmọ́lẹ̀ awọn [orilẹ-ede, NW], ki iwọ ki ó lè jẹ fun igbala titi de opin aye.” Iwọ ń kọ́? Iwọ ha ti fi iṣẹ aigbọdọmaṣe yẹn lati jẹ olùtan ìmọ́lẹ̀ sọ́kàn bi? Bii Jesu ati Paulu, iwọ ha ti gbe igbesi-aye rẹ karí ṣiṣe ifẹ-inu Ọlọrun bi?

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́