ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ègbé Ni fún Ọgbà Àjàrà Aláìṣòótọ́!
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
    • 17. Ìwà burúkú wo ni Aísáyà bẹnu àtẹ́ lù nínú ègbé kìíní tí ó ké?

      17 Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu Jèhófà ni Aísáyà kọ ní ẹsẹ kẹjọ. Fúnra rẹ̀ ló kéde ègbé àkọ́kọ́ nínú ègbé mẹ́fà tó fi bẹnu àtẹ́ lu mélòó kan lára “èso àjàrà ìgbẹ́” tí Júdà so, ó sọ pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń so ilé pọ̀ mọ́ ilé, àti àwọn tí ń fi pápá kún pápá títí kò fi sí àyè mọ́, a sì ti mú kí ẹ máa dá gbé ní àárín ilẹ̀ náà! Ní etí mi, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti búra pé ọ̀pọ̀ ilé, bí wọ́n tilẹ̀ tóbi, tí wọ́n sì dára, yóò di ohun ìyàlẹ́nu pátápátá, láìsí olùgbé. Nítorí pé, àní sarè mẹ́wàá ọgbà àjàrà yóò mú kìkì òṣùwọ̀n báàfù kan ṣoṣo jáde, àní irúgbìn tí ó jẹ́ òṣùwọ̀n hómérì kan yóò sì mú kìkì òṣùwọ̀n eéfà kan jáde.”—Aísáyà 5:8-10.

  • Ègbé Ni fún Ọgbà Àjàrà Aláìṣòótọ́!
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
    • 19 Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò gba gbogbo ohun tí oníwọra wọ̀nyẹn ti fi bìrìbìrì kó jọ. Ilé tí wọ́n já gbà yóò wà “láìsí olùgbé.” Èso táṣẹ́rẹ́ ni ilẹ̀ tójú wọn wọ̀ yóò so. Kò sọ bí ègún yìí ṣe máa ṣẹ àti ìgbà tí yóò ṣẹ. Bóyá apákan rẹ̀, ó kéré tán, tọ́ka sí ohun tó máa bá wọn lọ́jọ́ iwájú, nígbà ìgbèkùn ní Bábílónì.—Aísáyà 27:10.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́