ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Dídá Àwọn Ońṣẹ́ Tòótọ́ Mọ̀ Yàtọ̀
    Ilé Ìṣọ́—1997 | May 1
    • “Ẹni tí . . . ó fi ìdí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ múlẹ̀, tí ó sì mú ìmọ̀ àwọn [ońṣẹ́, NW] rẹ̀ ṣẹ.”—AÍSÁYÀ 44:25, 26.

      1. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi àwọn ońṣẹ́ tòótọ́ hàn yàtọ̀, báwo sì ni ó ṣe ń táṣìírí àwọn èké ońṣẹ́?

      JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN ni Atóbilọ́lá ẹni tí ń fi àwọn ońṣẹ́ rẹ̀ tòótọ́ hàn yàtọ̀. Ó ń fi wọ́n hàn yàtọ̀ nípa mímú kí ọ̀rọ̀ tí òun tipasẹ̀ wọn sọ ní ìmúṣẹ. Jèhófà tún ni Atóbilọ́lá Olùtáṣìírí àwọn èké ońṣẹ́. Báwo ni ó ṣe ń táṣìírí wọn? Ó ń mú kí àwọn àmì àti àsọtẹ́lẹ̀ wọn já sí òtúbáńtẹ́. Lọ́nà yí, ó ń fi hàn pé, alásọtẹ́lẹ̀ tí ó yan ara rẹ̀ sípò ni wọ́n jẹ́, tí ìhìn iṣẹ́ wọ́n wá láti inú èrò èké tiwọn fúnra wọn—bẹ́ẹ̀ ni, láti inú ìrònú òmùgọ̀ wọn, tí ó jẹ́ ti ẹran ara!

  • Dídá Àwọn Ońṣẹ́ Tòótọ́ Mọ̀ Yàtọ̀
    Ilé Ìṣọ́—1997 | May 1
    • 6 Ní àfikún sí èyí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n wà ní ìgbèkùn tún ń gbọ́ ìsọkúsọ tí àwọn aríran, àwọn woṣẹ́woṣẹ́, àti awòràwọ̀ tí ń fọ́nnu ń sọ. Ṣùgbọ́n, Jèhófà fi àwọn ońṣẹ́ èké wọ̀nyí hàn gẹ́gẹ́ bí òmùgọ̀ tí ìsapá wọn já sí òtúbáńtẹ́, tí wọ́n ń sọ òdì kejì ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Nígbà tí àkókò tó, ó fi hàn pé Ìsíkẹ́ẹ̀lì ni ońṣẹ́ rẹ̀ tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí Aísáyà pẹ̀lú ti jẹ́. Jèhófà mú gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó sọ láti ẹnu wọn ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí, pé: “Ẹni tí ó sọ àmì àwọn èké di asán, tí ó sì ba àwọn aláfọ̀ṣẹ ní orí jẹ́, tí ó dá àwọn ọlọgbọ́n pa dà, tí ó sì sọ ìmọ̀ wọn di wèrè. Tí ó fi ìdí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ múlẹ̀, tí ó sì mú ìmọ̀ àwọn [ońṣẹ́, NW] rẹ̀ ṣẹ.”—Aísáyà 44:25, 26.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́