ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Dídá Àwọn Ońṣẹ́ Tòótọ́ Mọ̀ Yàtọ̀
    Ilé Ìṣọ́—1997 | May 1
    • 10. Lọ́nà wo ni Kírúsì fi jẹ́ “ẹni àmì òróró,” báwo sì ni Jèhófà ṣe lè bá a sọ̀rọ̀ ni ohun tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú kí a tó bí i?

      10 Ṣàkíyèsí pé Jèhófà bá Kírúsì sọ̀rọ̀ bí ẹni pé ó wà láàyè. Èyí bá ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù mu, pé Jèhófà “pe àwọn ohun tí kò sí bí ẹni pé wọ́n wà.” (Róòmù 4:17) Bákan náà, Ọlọ́run pe Kírúsì ní ‘ẹni òróró òun.’ Èé ṣe tí ó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó ṣe tán, àlùfáà àgbà Jèhófà kò fìgbà kan rí da òróró mímọ́ sí Kírúsì lórí. Òtítọ́ ni, ṣùgbọ́n yíyàn alásọtẹ́lẹ̀ ni èyí. Ó túmọ̀ sí yíyanni sí ipò iṣẹ́ àkànṣe kan. Nítorí náà, Ọlọ́run lè pe yíyàn tí ó yan Kírúsì sípò ṣáájú àkókò ní ìfòróróyàn.—Fi wé Ọba Kìíní 19:15-17; Ọba Kejì 8:13.

  • Dídá Àwọn Ońṣẹ́ Tòótọ́ Mọ̀ Yàtọ̀
    Ilé Ìṣọ́—1997 | May 1
    • 12, 13. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà tipasẹ̀ Aísáyà ońṣẹ́ rẹ̀ sọ ṣe ní ìmúṣẹ nígbà tí Bábílónì ṣubú sọ́wọ́ Kírúsì?

      12 Ṣùgbọ́n, ìrètí àwọn Júù tí a kó nígbèkùn, tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, kò ṣákìí! Wọ́n ní ìrètí tí ó dájú. Nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀, Ọlọ́run ti ṣèlérí láti dá wọn sílẹ̀. Báwo ni Ọlọ́run ṣe mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ? Kírúsì pàṣẹ pé kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ darí Odò Yúfírétì sí ọ̀pọ̀ kìlómítà ní ìhà àríwá Bábílónì. Nípa báyìí, dé ìwọ̀n gíga, olórí ààbò ìlú náà ti di etí bèbè gbígbẹ táútáú. Ní alẹ́ ọjọ́ mánigbàgbé yẹn, àwọn alárìíyá aláriwo ní Bábílónì, tí wọ́n ti mu ọtí yó kẹ́ri, fi ilẹ̀kùn aláwẹ́ méjì náà tí ó wà lórí etí bèbè Yúfírétì sílẹ̀ gbayawu ní ṣíṣí sílẹ̀, láìbìkítà. Jèhófà kò fọ́ àwọn ilẹ̀kùn idẹ náà sí wẹ́wẹ́ ní ti gidi; bẹ́ẹ̀ sì ni kò gé àwọn ọ̀já irin tí a fi ń ti àwọn ilẹ̀kùn ẹnubodè náà ní ti gidi, ṣùgbọ́n bí ó ṣe fọgbọ́n darí ọ̀ràn lọ́nà ìyanu, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n wà ní ṣíṣí sílẹ̀ gbayawu, tí a kò sì fi àgádágodo tì wọ́n ní àbájáde kan náà. Àwọn ògiri Bábílónì kò wúlò! Àwọn ọmọ ogun Kírúsì kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní láti gùn wọ́n kí wọ́n tó wọ inú ìlú. Jèhófà ti lọ ṣáájú Kírúsì, láti sọ “ibi wíwọ́” di títọ́, bẹ́ẹ̀ ni, láti mú gbogbo ìdènà kúrò lọ́nà. A fi hàn pé Aísáyà jẹ́ ońṣẹ́ tòótọ́ ti Ọlọ́run.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́