-
Ègbé Ni fún Ọgbà Àjàrà Aláìṣòótọ́!Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
-
-
29. Àgbákò wo ló ń dúró de Ísírẹ́lì, ọgbà àjàrà Jèhófà, níkẹyìn?
29 Aísáyà mú ìsọfúnni alásọtẹ́lẹ̀ yìí wá sópin nípa ṣíṣàpèjúwe àgbákò tí yóò bá àwọn tó “ti kọ òfin Jèhófà” tí wọn kò sì so èso òdodo. (Aísáyà 5:24, 25; Hóséà 9:16; Málákì 4:1) Ó polongo pé: “[Jèhófà] gbé àmì àfiyèsí sókè sí orílẹ̀-èdè ńlá kan tí ó jìnnà réré, ó sì ti súfèé sí i ní ìkángun ilẹ̀ ayé; sì wò ó! pẹ̀lú ìṣekánkán ni yóò wọlé wá pẹ̀lú ìyára.”—Aísáyà 5:26; Diutarónómì 28:49; Jeremáyà 5:15.
30. Ta ni yóò kó “orílẹ̀-èdè ńlá” jọ ní ìdojú ìjà kọ ènìyàn Jèhófà, kí sì ni yóò jẹ́ àbáyọrí rẹ̀?
30 Láyé àtijọ́, tí wọ́n bá ri òpó mọ́ ibi gíga, ó lè jẹ́ fún “àmì àfiyèsí” tàbí ibi ìkójọpọ̀ fáwọn ènìyàn tàbí ọmọ ogun. (Fi wé Aísáyà 18:3; Jeremáyà 51:27.) Wàyí o, Jèhófà yóò fúnra rẹ̀ kó “orílẹ̀-èdè ńlá,” tí kò dárúkọ yìí jọ, kí wọ́n lè mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ.b Yóò ‘súfèé sí i,’ ìyẹn ni pé, yóò pàfiyèsí rẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ̀ oníwàkiwà pé wọ́n yẹ láti fi ṣèjẹ. Wòlíì yìí wá ṣàpèjúwe bí ìkọlù àwọn aṣẹ́gun tó dà bíi kìnnìún yìí yóò ṣe yára kánkán tí yóò sì bani lẹ́rù tó, bí wọn yóò ṣe “gbá ẹran ọdẹ mú,” ìyẹn, orílẹ̀-èdè Ọlọ́run, tí “wọn yóò sì gbé e lọ” sí ìgbèkùn “láìséwu.” (Ka Aísáyà 5:27-30a.) Ohun tó yọrí sí fún orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn Jèhófà mà burú o! “Ènìyàn yóò sì tẹjú mọ́ ilẹ̀ náà ní ti tòótọ́, sì wò ó! òkùnkùn tí ń kó wàhálà báni ni ó wà; ìmọ́lẹ̀ pàápàá ti ṣókùnkùn nítorí àwọn ohun tí ń kán sí i lórí.”—Aísáyà 5:30b.
-
-
Ègbé Ni fún Ọgbà Àjàrà Aláìṣòótọ́!Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
-
-
b Nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn, Aísáyà tọ́ka sí Bábílónì gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tí yóò mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ lé Júdà lórí.
-