-
Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Wa Jẹ Ọlọ́run Lógún?Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
-
-
Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa pọ̀ ju ìfẹ́ tó ń mú kí abiyamọ máa ṣìkẹ́ ọmọ ọwọ́ rẹ̀
Ó dájú pé ọ̀rọ̀ wa jẹ Ọlọ́run lógún gan-an. Ó sọ nínú Ìwé Mímọ́ rẹ̀ pé: “Aya ha lè gbàgbé ọmọ ẹnu ọmú rẹ̀ tí kì yóò fi ṣe ojú àánú sí ọmọ ikùn rẹ̀? Àní àwọn obìnrin wọ̀nyí lè gbàgbé, síbẹ̀, èmi kì yóò gbàgbé [rẹ].”a
Ǹjẹ́ o ò rí i pé ọ̀rọ̀ yìí fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an? Àní, ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa pọ̀ gan-an ju ìfẹ́ tó ń mú kí abiyamọ máa ṣìkẹ́ ọmọ ọwọ́ rẹ̀ lójú méjèèjì, bẹ́ẹ̀ sì rèé, abiyamọ kì í fi ọ̀rọ̀ ọmọ rẹ̀ ṣeré. Ọlọ́run kò ní pa wá tì láé! Kódà, ó tiẹ̀ ti ṣèrànlọ́wọ́ kan fún wa lọ́nà ìyanu. Ìrànlọ́wọ́ wo nìyẹn? Ó ti jẹ́ ká mọ ohun tí yóò máa fún wa ní ayọ̀, ìyẹn sì ni ìgbàgbọ́ òdodo.
-
-
Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Wa Jẹ Ọlọ́run Lógún?Ìgbàgbọ́ Òdodo Ló Máa Mú Kó O Ní Ayọ̀
-
-
a Wo Aísáyà 49:15 nínú Ìwé Mímọ́.
-