-
Ìtùnú fún Àwọn Èèyàn Ọlọ́runÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
12. Kí ni ìdí tí kò fi yẹ kí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bẹ̀rù nígbà tí àwọn èèyàn tó takò wọ́n bá ń bà wọ́n lórúkọ jẹ́?
12 Jèhófà wá kọjú ọ̀rọ̀ sí àwọn “ènìyàn tí ń lépa òdodo,” ó ní: “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin tí ó mọ òdodo, ẹ̀yin ènìyàn tí òfin mi wà ní ọkàn-àyà yín. Ẹ má fòyà ẹ̀gàn àwọn ẹni kíkú, ẹ má sì jẹ́ kí a kó ìpayà bá yín kìkì nítorí ọ̀rọ̀ èébú wọn. Nítorí pé òólá yóò jẹ wọ́n tán bí ẹni pé ẹ̀wù ni wọ́n, òólá aṣọ yóò sì jẹ wọ́n tán bí irun àgùntàn. Ṣùgbọ́n ní ti òdodo mi, yóò wà àní fún àkókò tí ó lọ kánrin, àti ìgbàlà mi, fún àwọn ìran tí kò níye.” (Aísáyà 51:7, 8) Àwọn èèyàn yóò ba àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà lórúkọ jẹ́, àní wọn yóò pẹ̀gàn wọn nítorí ọkàn akin tí wọ́n ní, ṣùgbọ́n ìyẹn kì í ṣe ohun à-ń-bẹ̀rù rárá. Ọmọ adáríhurun lásánlàsàn làwọn ẹlẹ́gàn yìí, àwọn tó jẹ́ pé bí ìgbà tí òólá bá jẹ aṣọ ni wọ́n yóò ṣe di ‘jíjẹ tán’ pátá.a Bí àwọn Júù olóòótọ́ láyé àtijọ́ kò ṣe ní láti bẹ̀rù náà ni kò ṣe sídìí fún àwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní láti bẹ̀rù ẹni yòówù kó takò wọ́n. Jèhófà, Ọlọ́run ayérayé, ni ìgbàlà wọn. (Sáàmù 37:1, 2) Ṣe ni ẹ̀gàn àwọn ọ̀tá Ọlọ́run tún jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ̀mí Ọlọ́run ń bẹ lára àwọn èèyàn Jèhófà.—Mátíù 5:11, 12; 10:24-31.
-
-
Ìtùnú fún Àwọn Èèyàn Ọlọ́runÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
a Ẹ̀rí fi hàn pé òólá tí ibí yìí ń sọ ni òólá tí ìdin rẹ̀ máa ń baṣọ jẹ́ gan-an.
-