ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ọ̀rọ̀ Àgàn Náà Dayọ̀
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • 9, 10. Kí ni ìtọ́ni tí obìnrin kan tó ń gbé inú àgọ́ láyé àtijọ́ gbà pé kí ó ‘mú kí ibi àgọ́ rẹ̀ túbọ̀ ní àyè gbígbòòrò’ yóò túmọ̀ sí fún un, kí sì nìdí tí yóò fi jẹ́ àkókò ìdùnnú fún obìnrin yẹn?

      9 Aísáyà wá gbẹ́nu lé àsọtẹ́lẹ̀ nípa àkókò tí ìbísí kíkàmàmà yóò dé, ó ní: “Mú kí ibi àgọ́ rẹ túbọ̀ ní àyè gbígbòòrò. Kí wọ́n sì na àwọn aṣọ àgọ́ ibùgbé rẹ títóbilọ́lá. Má fawọ́ sẹ́yìn. Mú kí àwọn okùn àgọ́ rẹ gùn sí i, kí o sì mú àwọn ìkànlẹ̀ àgọ́ tìrẹ wọ̀nyẹn le. Nítorí pé ìwọ yóò ya sí ọ̀tún àti sí òsì, àwọn ọmọ tìrẹ yóò sì gba àwọn orílẹ̀-èdè pàápàá, wọn yóò sì máa gbé àwọn ìlú ńlá tí ó ti di ahoro pàápàá. Má fòyà, nítorí pé a kì yóò kó ìtìjú bá ọ; má sì jẹ́ kí ìtẹ́lógo bá ọ, nítorí pé a kì yóò já ọ kulẹ̀. Nítorí pé ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe rẹ pàápàá, ẹ̀gàn ìgbà opó rẹ tí ń bá a nìṣó ni ìwọ kì yóò sì rántí mọ́.”—Aísáyà 54:2-4.

      10 Níhìn-ín, Ọlọ́run bá Jerúsálẹ́mù sọ̀rọ̀ bíi pé ó jẹ́ aya àti ìyá ọlọ́mọ tó ń gbé inú àgọ́, bíi ti Sárà gẹ́lẹ́. Bó bá ti di pé ìdílé rẹ̀ ń pọ̀ sí i, ó di dandan pé kí irú ìyá bẹ́ẹ̀ wá bí yóò ṣe mú kí ilé rẹ̀ gbòòrò sí i. Ó ń béèrè pé kí ó ta àwọn aṣọ àgọ́ àti àwọn okùn tó túbọ̀ gùn sí i, kí ó sì kan àwọn ìkànlẹ̀ àgọ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀ síbi tuntun. Iṣẹ́ tí yóò yá a lórí láti ṣe ni, àti pé, ní irú àsìkò tí ọwọ́ rẹ̀ dí gidi yẹn, kíákíá ló lè gbàgbé àwọn ọdún tí ọkàn rẹ̀ kò fi balẹ̀ nítorí ìrònú bóyá òun máa lè bí àwọn ọmọ kí ìlà ìdílé òun má bàa pa rẹ́.

  • Ọ̀rọ̀ Àgàn Náà Dayọ̀
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • a Gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 12:1-17 ṣe fi hàn, “obìnrin” Ọlọ́run yìí rí ìbùkún ńlá gbà ní ti bíbí tó bí “ọmọ” tó ṣe pàtàkì jù lọ, àmọ́ ẹ̀dá ẹ̀mí pàtó kan kọ́ ni ọmọ yìí o, Ìjọba Mèsáyà ní ọ̀run ni. Ọdún 1914 ló bí i. (Wo ìwé Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, ojú ewé 177 sí 186.) Ayọ̀ tó bá a nítorí bí Ọlọ́run ṣe ń bù kún àwọn ọmọ rẹ̀ ẹni àmì òróró tó wà ní orí ilẹ̀ ayé ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tẹnu mọ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́