-
Ọwọ́ Jèhófà Kò KúrúÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
17. Ta ni Olùtúnnirà Síónì, ìgbà wo ló sì tún Síónì rà?
17 Lábẹ́ Òfin Mósè, tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá ta ara rẹ̀ sí oko ẹrú, olùtúnnirà lè rà á padà kúrò lóko ẹrú. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà sọ níṣàájú, ó ti sọ pé Jèhófà ni Olùtúnnirà àwọn kan tó ronú pìwà dà. (Aísáyà 48:17) Ó tún ṣàpèjúwe rẹ̀ nísinsìnyí pẹ̀lú pé ó jẹ́ Olùtúnnirà àwọn tó bá ronú pìwà dà. Aísáyà ṣàkọsílẹ̀ ìlérí Jèhófà, ó ní: “‘Dájúdájú, Olùtúnnirà yóò sì wá sí Síónì, àti sọ́dọ̀ àwọn tí ń yí padà kúrò nínú ìrélànàkọjá nínú Jékọ́bù,’ ni àsọjáde Jèhófà.” (Aísáyà 59:20) Ìlérí tó fini lọ́kàn balẹ̀ yìí ṣẹ lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n ó tún ní ìmúṣẹ síwájú sí i. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yìí yọ látinú Bíbélì Septuagint, ó sì ní wọ́n ṣẹ sí àwọn Kristẹni lára. Ó kọ̀wé pé: “Lọ́nà yìí ni a ó gba gbogbo Ísírẹ́lì là. Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Olùdáǹdè yóò jáde wá láti Síónì, yóò sì yí àwọn ìṣe àìṣèfẹ́ Ọlọ́run padà kúrò lọ́dọ̀ Jékọ́bù. Èyí sì ni májẹ̀mú náà níhà ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú wọn, nígbà tí mo bá mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn kúrò.’” (Róòmù 11:26, 27) Ní tòótọ́, ibi tí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣẹ dé rìn jìnnà gan-an ni, àní ó rìn jìnnà dé ìgbà tiwa ó tún ré kọjá rẹ̀ pàápàá. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?
-
-
Ọwọ́ Jèhófà Kò KúrúÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
19. Májẹ̀mú wo ni Jèhófà bá Ísírẹ́lì Ọlọ́run dá?
19 Nísinsìnyí, Jèhófà wá bá Ísírẹ́lì Ọlọ́run dá májẹ̀mú. A kà á pé: “‘Ní tèmi, èyí ni májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn,’ ni Jèhófà wí. ‘Ẹ̀mí mi tí ó wà lára rẹ àti àwọn ọ̀rọ̀ mi tí mo fi sí ẹnu rẹ—a kì yóò mú wọn kúrò ní ẹnu rẹ tàbí kúrò ní ẹnu àwọn ọmọ rẹ tàbí kúrò ní ẹnu àwọn ọmọ-ọmọ rẹ,’ ni Jèhófà wí, ‘láti ìsinsìnyí lọ àní dé àkókò tí ó lọ kánrin.’” (Aísáyà 59:21) Yálà ọ̀rọ̀ yìí ṣẹ sára Aísáyà fúnra rẹ̀ tàbí kò ṣẹ o, ó dájú pé wọ́n ṣẹ lára Jésù, ẹni tí a mú kó dá lójú pé “yóò rí àwọn ọmọ rẹ̀.” (Aísáyà 53:10) Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ti kọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, ẹ̀mí Jèhófà sì tún bà lé e. (Jòhánù 1:18; 7:16) Ó sì tún bá a mu gẹ́ẹ́ pé àwọn arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n jọ jẹ́ ajùmọ̀jogún, àwọn tó jẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run, gba ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà bákan náà, wọ́n sì ń wàásù ohun tí wọ́n kọ́ látọ̀dọ̀ Bàbá wọn ọ̀run. Gbogbo wọn jẹ́ “àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.” (Aísáyà 54:13; Lúùkù 12:12; Ìṣe 2:38) Jèhófà wá dá májẹ̀mú wàyí, yálà nípasẹ̀ Aísáyà tàbí nípasẹ̀ Jésù tí Aísáyà ṣàpẹẹrẹ lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀, pé òun kò ní fi ẹnikẹ́ni rọ́pò wọn, pé ńṣe lòun yóò máa lò wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí òun àní títí dé àkókò tí ó lọ kánrin. (Aísáyà 43:10) Ṣùgbọ́n, àwọn wo wá ni “àwọn ọmọ-ọmọ” wọn tó tún jàǹfààní látinú májẹ̀mú yìí?
20. Báwo ni ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù ṣe ṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní?
20 Láyé àtijọ́, Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé: “Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:18) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, àwọn àṣẹ́kù kéréje tí wọ́n tẹ́wọ́ gba Mèsáyà lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa ti ara jáde lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ láti lọ máa wàásù ìhìn rere nípa Kristi. Ọ̀pọ̀ àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ ló sì ti tipasẹ̀ Jésù, Irú Ọmọ Ábúráhámù náà, “bù kún ara wọn,” bẹ̀rẹ̀ látorí Kọ̀nílíù. Wọ́n di ara Ísírẹ́lì Ọlọ́run, àti irú ọmọ onípò kejì nínú irú ọmọ Ábúráhámù. Wọ́n jẹ́ ara “orílẹ̀-èdè mímọ́” ti Jèhófà, iṣẹ́ wọ́n sì jẹ́ láti “polongo káàkiri àwọn ìtayọlọ́lá ẹni tí ó pè [wọ́n] jáde kúrò nínú òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀.”—1 Pétérù 2:9; Gálátíà 3:7-9, 14, 26-29.
21. (a) Irú “àwọn ọmọ-ọmọ” wo ni Ísírẹ́lì Ọlọ́run ti bí lákòókò òde òní? (b) Báwo ni májẹ̀mú tí Jèhófà dá, tàbí ẹ̀jẹ́ tó jẹ́, fún Ísírẹ́lì Ọlọ́run ṣe ń fi “àwọn ọmọ-ọmọ” yìí lọ́kàn balẹ̀?
21 Láyé òde òní, ó jọ pé a ti kó ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye àwọn tó jẹ́ ara Ísírẹ́lì Ọlọ́run jọ tán. Síbẹ̀, àwọn orílẹ̀-èdè ṣì ń gba ìbùkún lọ́nà tó tiẹ̀ tún gadabú. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ó rí bẹ́ẹ̀ ní ti pé Ísírẹ́lì Ọlọ́run ti ní “àwọn ọmọ-ọmọ,” ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó ń retí láti wà láàyè nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:11, 29) “Àwọn ọmọ-ọmọ” yìí pẹ̀lú gba ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà, wọ́n sì gba ìtọ́ni nípa àwọn ọ̀nà rẹ̀. (Aísáyà 2:2-4) Lóòótọ́, a kò fi ẹ̀mí mímọ́ batisí wọn, bẹ́ẹ̀ ni a kò kà wọ́n sí ẹni tó ń kópa nínú májẹ̀mú tuntun, àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ń fún wọn lókun láti lè borí gbogbo ìdènà tí Sátánì ń gbé dínà iṣẹ́ ìwàásù wọn. (Aísáyà 40:28-31) Iye wọn ti wọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ báyìí, ó sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i bí àwọn náà ṣe ń bí ọmọ-ọmọ pẹ̀lú. Májẹ̀mú tí Jèhófà dá, tàbí ẹ̀jẹ́ tó jẹ́, fún àwọn ẹni àmì òróró ń fi “àwọn ọmọ-ọmọ” wọ̀nyí lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà yóò máa bá a lọ láti lo àwọn náà gẹ́gẹ́ bí agbọ̀rọ̀sọ rẹ̀ títí ayérayé.—Ìṣípayá 21:3, 4, 7.
-