-
Jèhófà Fi Ìmọ́lẹ̀ Bu Ẹwà Kún Àwọn Èèyàn Rẹ̀Ilé Ìṣọ́—2002 | July 1
-
-
4, 5. (a) Kí ni Jèhófà pàṣẹ pé kí obìnrin kan ṣe, ìlérí wo sì ni Jèhófà ṣe? (b) Ìsọfúnni alárinrin wo ló wà nínú Aísáyà orí ọgọ́ta?
4 Àwọn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ nínú Aísáyà orí ọgọ́ta ní í ṣe pẹ̀lú obìnrin kan tí inú rẹ̀ bà jẹ́ gidigidi. Ńṣe ló nà gbalaja sílẹ̀ẹ́lẹ̀ nínú òkùnkùn biribiri. Lójijì, ìmọ́lẹ̀ tàn yòò, òkùnkùn sì para dà, Jèhófà wá ké sí i pé: “Dìde, ìwọ obìnrin, tan ìmọ́lẹ̀ jáde, nítorí pé ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé, àní ògo Jèhófà sì ti tàn sára rẹ.” (Aísáyà 60:1) Àkókò tó wàyí kí obìnrin náà gbéra nílẹ̀, kí ó sì gbé ìmọ́lẹ̀, ìyẹn ògo, Ọlọ́run yọ. Kí nìdí? A rí ìdáhùn ní ẹsẹ tó tẹ̀ lé e, ó ní: “Wò ó! òkùnkùn pàápàá yóò bo ilẹ̀ ayé, ìṣúdùdù nínípọn yóò sì bo àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè; ṣùgbọ́n Jèhófà yóò tàn sára rẹ, a ó sì rí ògo rẹ̀ lára rẹ.” (Aísáyà 60:2) Nígbà tí obìnrin yẹn ṣe bí Jèhófà ṣe wí, a mú un dá a lójú pé ìyọrísí rẹ̀ yóò kọyọyọ. Jèhófà sọ pé: “Dájúdájú, àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì lọ sínú ìmọ́lẹ̀ rẹ, àwọn ọba yóò sì lọ sínú ìtànyòò tí ó wá láti inú ìtànjáde rẹ.”—Aísáyà 60:3.
5 Ọ̀rọ̀ alárinrin tó wà nínú ẹsẹ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí jẹ́ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti àkópọ̀ ohun tó wà nínú ìyókù ìwé Aísáyà orí ọgọ́ta. Ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí obìnrin kan tí àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ó sì ṣàlàyé bá a ṣe lè máa wà nínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé òkùnkùn bo aráyé. Àmọ́, kí ni àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ inú ẹsẹ mẹ́ta àkọ́kọ́ wọ̀nyí túmọ̀ sí?
6. Ta ni obìnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Aísáyà orí ọgọ́ta, àwọn wo ló sì ń ṣojú fún un lórí ilẹ̀ ayé?
6 Síónì ni obìnrin tí Aísáyà 60:1-3 ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, ìyẹn ètò Jèhófà ní ọ̀run, tó kún fún àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Àṣẹ́kù “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” ìyẹn ìjọ àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn jákèjádò ayé, tó ń retí láti bá Kristi jọba lọ́run, ló ń ṣojú fún Síónì lórí ilẹ̀ ayé lónìí. (Gálátíà 6:16) Àwọn tó wà nínú orílẹ̀-èdè tẹ̀mí yìí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, àwọn tó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé lára wọn ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà orí ọgọ́ta ń ṣẹ sí lára lóde òní. (2 Tímótì 3:1; Ìṣípayá 14:1) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí tún sọ ohun púpọ̀ nípa “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wọ̀nyí.—Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16.
-
-
Jèhófà Fi Ìmọ́lẹ̀ Bu Ẹwà Kún Àwọn Èèyàn Rẹ̀Ilé Ìṣọ́—2002 | July 1
-
-
8. Ìyípadà gígadabú wo ló wáyé lọ́dún 1919, kí sì ni ìyọrísí rẹ̀?
8 Àfi bó ṣe di ọdún 1919 tí ìyípadà gígadabú dé. Jèhófà tànmọ́lẹ̀ sórí Síónì! Àwọn tó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì Ọlọ́run gbéra nílẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run yọ, wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere náà láìbẹ̀rù. (Mátíù 5:14-16) Àkọ̀tun ìtara tí àwọn Kristẹni yìí ní mú kí àwọn mìíràn wá sínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà. A fẹ̀mí yan àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sínú ìmọ́lẹ̀ yìí láti di ara Ísírẹ́lì Ọlọ́run. Aísáyà 60:3 pè wọ́n ní ọba, nítorí pé wọ́n máa jẹ́ ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run. (Ìṣípayá 20:6) Lẹ́yìn náà, a wá bẹ̀rẹ̀ sí mú ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn wá sínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà. Àwọn wọ̀nyí ló di “àwọn orílẹ̀-èdè” tá a mẹ́nu kàn nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà.
-