-
Àwọn Àbájáde Iṣẹ́ Ìwàásù—“Àwọn Pápá . . . Ti Funfun fún Kíkórè”Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
-
-
15. Ọ̀nà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Aísáyà 60:5, 22 gbà ní ìmúṣẹ? (Tún wo àwọn àpótí náà “Jèhófà Ló Mú Kó Ṣeé Ṣe,” ojú ìwé 93, àti “Bí ‘Ẹni Tí Ó Kéré’ Ṣe Di ‘Alágbára Ńlá Orílẹ̀-Èdè,’” ojú ìwé 96 àti 97.)
15 Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] ọdún ṣáájú kí Jésù tó sọ àwọn àkàwé yẹn, Jèhófà ti tipasẹ̀ Aísáyà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó wọni lọ́kàn nípa bí iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí tá à ń ṣe lónìí ṣe máa gbòòrò tó àti ayọ̀ tí iṣẹ́ ìkórè náà máa mú wá.c Jèhófà ṣàpèjúwe pé àwọn èèyàn tó pọ̀ gan-an “láti ibi jíjìnnàréré” yóò máa wá sínú ètò rẹ̀. Ó darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí “obìnrin” kan tó dúró fún àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé lónìí, ó sọ pé: “Ìwọ yóò wò, ìwọ yóò sì wá tàn yinrin dájúdájú, ọkàn-àyà rẹ yóò sì gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ ní tòótọ́, yóò sì gbòòrò, nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ ni ọlà òkun yóò darí sí; àní ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sọ́dọ̀ rẹ.” (Aísá. 60:1, 4, 5, 9) Òtítọ́ mà ni ọ̀rọ̀ yẹn o! Lónìí, inú àwọn tó ti ń sin Jèhófà láti ọ̀pọ̀ ọdún ń dùn gan-an bí wọ́n ṣe ń rí i tí iye àwọn akéde Ìjọba tó wà ní ilẹ̀ wọn ń pọ̀ sí i látorí ìwọ̀nba èèyàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún.
-
-
Àwọn Àbájáde Iṣẹ́ Ìwàásù—“Àwọn Pápá . . . Ti Funfun fún Kíkórè”Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
-
-
c Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí, wo ìwé Asọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì, ojú ìwé 303 sí 320.
-