ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ara-ilu Tabi Àlejò, Ọlọrun Tẹwọgba Ọ́!
    Ilé-Ìṣọ́nà—1992 | April 15
    • 19. Ni isopọ pẹlu ipada Isirẹli, itọka alasọtẹlẹ wo ni ó wà nibẹ pe yoo ní awọn àlejò ninu?

      19 Sibẹ, ni sisọ asọtẹlẹ irapada ati ipada awọn eniyan Ọlọrun naa, Aisaya sọ asọtẹlẹ ayanilẹnu lojiji yii: “Awọn keferi [“orilẹ-ede,” NW] yoo wá sí imọlẹ rẹ, ati awọn ọba si títàn yiyọ rẹ.” (Aisaya 59:20; 60:3) Eyi tumọsi ju pe awọn àlejò kọọkan ni a tẹwọgba, ni ìlà pẹlu adura Solomọni. Aisaya ń tọka si iyipada ti ó ṣajeji kan ninu ipo. “Awọn orilẹ-ede” yoo ṣiṣẹsin pẹlu awọn ọmọkunrin Isirẹli: “Awọn ọmọ àlejò yoo sì mọ odi rẹ: awọn ọba wọn yoo ṣe iranṣẹ fun ọ: nitori ni ikannu mi ni mo lù ọ́, ṣugbọn ni inu rere mi ni mo sì ṣaanu fun ọ.”—Aisaya 60:10.

  • Ara-ilu Tabi Àlejò, Ọlọrun Tẹwọgba Ọ́!
    Ilé-Ìṣọ́nà—1992 | April 15
    • 22. Bawo ni “awọn àlejò” ṣe wá lati ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn Isirẹli tẹmi?

      22 Ki ni nipa ti ‘awọn àlejò ti yoo mọ awọn odi rẹ’? Eyi pẹlu ti ṣẹlẹ ni akoko wa. Bi ìkésíni awọn 144,000 ti ń wá si opin, ogunlọgọ ńlá lati inu gbogbo awọn orilẹ-ede bẹrẹ sii rọ́ gìrìgìrì wá lati jọsin pẹlu Isirẹli tẹmi. Awọn ẹni titun wọnyi ní ireti ti a gbekari Bibeli ti ìyè ainipẹkun lori paradise ilẹ̀-ayé. Bi o tilẹ jẹ pe ọgangan àyè iṣẹ-isin oluṣotitọ wọn yoo yatọ, ó dùn mọ wọn ninu lati ran aṣẹku ẹni ami ororo lọwọ ninu wiwaasu ihinrere Ijọba naa.—Matiu 24:14.

      23. Dé iwọn àyè wo ni “awọn àlejò” ti ran awọn ẹni ami ororo lọwọ?

      23 Lonii, iye ti o ju 4,000,000 ti wọn jẹ́ “awọn àlejò,” papọ pẹlu awọn wọnni ti ‘ilu ibilẹ wọn wà ni ọ̀run,’ ń fi ẹ̀rí ifọkansin wọn si Jehofa han. Ọpọlọpọ ninu wọn, lọkunrin ati lobinrin, lọmọde ati lágbà, ń ṣiṣẹsin ninu iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun gẹgẹ bi aṣaaju-ọna. Ni eyi ti o pọ julọ ninu iye awọn ìjọ ti o ju 66,000 lọ, iru awọn àlejò bẹẹ ń gbé ẹru-iṣẹ gẹgẹ bi alagba ati iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ. Awọn aṣẹku yọ̀ ninu eyi, ni rírí imuṣẹ awọn ọrọ Aisaya pe: “Awọn àlejò yoo sì duro, wọn ó sì bọ́ ọ̀wọ́ ẹran yin, awọn ọmọ àlejò yoo sì ṣe atúlẹ̀ yin, ati olùrẹ́ ọwọ́ àjàrà yin.”—Aisaya 61:5.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́