ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Ìbùkún Ìhìn Rere
    Ilé Ìṣọ́—2002 | January 1
    • Àwọn Ìbùkún Ìhìn Rere

      “Jèhófà ti fòróró yàn mí láti sọ ìhìn rere fún àwọn ọlọ́kàn tútù. Ó ti rán mi láti di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn, . . . láti tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.”—AÍSÁYÀ 61:1, 2.

      1, 2. (a) Kí ni Jésù fi hàn pé òun jẹ́, lọ́nà wo sì ni? (b) Àwọn ìbùkún wo ni ìhìn rere tí Jésù ń kéde rẹ̀ mú wá?

      JÉSÙ wà nínú sínágọ́gù ní Násárétì lọ́jọ́ sábáàtì kan, nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àkọsílẹ̀ náà wí, “a fi àkájọ ìwé wòlíì Aísáyà lé e lọ́wọ́, ó sì ṣí àkájọ ìwé náà, ó sì rí ibi tí a ti kọ ọ́ pé: ‘Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fòróró yàn mí láti polongo ìhìn rere.’” Jésù tún ka àsọtẹ́lẹ̀ náà síwájú sí i. Lẹ́yìn náà ó jókòó, ó sì wí pé: “Lónìí, ìwé mímọ́ tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ tán yìí ní ìmúṣẹ.”—Lúùkù 4:16-21.

      2 Báyìí ni Jésù ṣe fi hàn pé òun ni ajíhìnrere tí a sọ tẹ́lẹ̀ náà, ìyẹn ẹni tó ń sọ ìhìn rere, tó sì ń tu àwọn èèyàn nínú. (Mátíù 4:23) Ẹ ò rí i pé ìhìn rere ni Jésù ń sọ lóòótọ́! Ó sọ fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé: “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹni tí ó bá ń tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn lọ́nàkọnà, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.” (Jòhánù 8:12) Ó tún sọ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:31, 32) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jésù lẹni tí ń sọ “àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 6:68, 69) Dájúdájú, ìbùkún tó ṣeyebíye gbáà ni ìmọ́lẹ̀, ìyè àti òmìnira jẹ́!

      3. Ìhìn rere wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wàásù rẹ̀?

      3 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń bá iṣẹ́ ìwàásù Jésù lọ lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Wọ́n wàásù “ìhìn rere ìjọba” náà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè. (Mátíù 24:14; Ìṣe 15:7; Róòmù 1:16) Àwọn tó tẹ́wọ́ gbà á wá mọ Jèhófà Ọlọ́run. Wọ́n bọ́ lọ́wọ́ oko ẹrú ìsìn, wọ́n sì di ara orílẹ̀-èdè tẹ̀mí tuntun náà, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” tí àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ ní ìrètí ṣíṣàkóso títí láé ní ọ̀run pẹ̀lú Olúwa wọn, Jésù Kristi. (Gálátíà 5:1; 6:16; Éfésù 3:5-7; Kólósè 1:4, 5; Ìṣípayá 22:5) Àwọn ìbùkún tó ṣeyebíye nìwọ̀nyẹn lóòótọ́!

      Iṣẹ́ Ìjíhìnrere Lóde Òní

      4. Ọ̀nà wo ni a gbà ń mú àṣẹ náà láti wàásù ìhìn rere ṣẹ lóde òní?

      4 Lóde òní, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” tí ń pọ̀ sí i ń tì lẹ́yìn, ń bá a lọ láti mú iṣẹ́ tá a gbé lé Jésù fúnra rẹ̀ lọ́wọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ. (Ìṣípayá 7:9; Jòhánù 10:16) Àbájáde rẹ̀ ni pé, ìhìn rere náà ti di èyí tá a ti wàásù rẹ̀ débi gbígbòòrò ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Igba ó lé márùndínlógójì [235] ilẹ̀ àti àwọn ìpínlẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti jáde lọ “láti sọ ìhìn rere fún àwọn ọlọ́kàn tútù . . . , láti di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn, láti pòkìkí ìdásílẹ̀ lómìnira fún àwọn tí a mú ní òǹdè àti ìlajúsílẹ̀ rekete àní fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n; láti pòkìkí ọdún ìtẹ́wọ́gbà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà àti ọjọ́ ẹ̀san níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa; láti tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.” (Aísáyà 61:1, 2) Nítorí náà, iṣẹ́ ìjíhìnrere táwa Kristẹni ń ṣe ń bá a lọ láti mú àwọn ìbùkún wá fún ọ̀pọ̀ ènìyàn àti láti fún “àwọn tí ó wà nínú ìpọ́njú èyíkéyìí” ní ojúlówó ìtùnú.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

  • Àwọn Ìbùkún Ìhìn Rere
    Ilé Ìṣọ́—2002 | January 1
    • Ìhìn Rere Tó Ń Mú Àwọn Ìbùkún Ayérayé Wá

      6. Ìhìn rere wo ni a ń wàásù rẹ̀ lóde òní?

      6 Ìhìn rere táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù ni ìhìn rere tó dára jù lọ. Wọ́n ń ṣí Bíbélì wọn, wọ́n sì ń fi han àwọn tó ní etí ìgbọ́ àti àyà ìgbàṣe pé Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ kí ọ̀nà lè là fún aráyé láti tọ Ọlọ́run lọ, láti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, àti láti ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 3:16; 2 Kọ́ríńtì 5:18, 19) Wọ́n ń kéde pé a ti fìdí Ìjọba Ọlọ́run múlẹ̀ ni ọ̀run, lábẹ́ Jésù Kristi, Ọba tí a fòróró yàn, àti pé láìpẹ́ yóò mú ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé, yóò sì rí sí i pé a mú Párádísè padà bọ̀ sípò. (Ìṣípayá 11:15; 21:3, 4) Ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, wọ́n ń sọ fún àwọn aládùúgbò wọn pé ìsinsìnyí ni “ọdún ìtẹ́wọ́gbà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà” nígbà tí àǹfààní ṣì wà fún aráyé láti gbọ́ ìhìn rere náà. Wọ́n tún ń kìlọ̀ pé láìpẹ́ “ọjọ́ ẹ̀san níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa” yóò dé, nígbà tí Jèhófà yóò pa àwọn olubi tí kò ronú pìwà dà run.—Sáàmù 37:9-11.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́