-
Jèhófà Ṣe Orúkọ Ẹlẹ́wà fún Ara Rẹ̀Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
12, 13. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà kò gbà rí olùrànlọ́wọ́? (b) Báwo ni apá Jèhófà ṣe mú ìgbàlà wá fún un, báwo sì ni ìbínú rẹ̀ ṣe tì í lẹ́yìn?
12 Jèhófà ń bọ́rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Mo sì ń wò ṣáá, ṣùgbọ́n kò sí olùrànlọ́wọ́ kankan; ẹnu sì bẹ̀rẹ̀ sí yà mí, ṣùgbọ́n kò sí ẹnì kankan tí ó pèsè ìtìlẹyìn. Nítorí náà, apá mi mú ìgbàlà wá fún mi, ìhónú mi sì ni ohun tí ó tì mí lẹ́yìn. Mo sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ àwọn ènìyàn mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí mú kí wọ́n mu ìhónú mi ní àmupara, mo sì mú kí ẹ̀jẹ̀ wọn tí ń tú ṣùrùṣùrù dà wá sí ilẹ̀.”—Aísáyà 63:5, 6.
13 Kò sí ọmọ aráyé tó lè sọ pé òun lòun ran Jèhófà lọ́wọ́ lọ́jọ́ ẹ̀san ńlá rẹ̀. Àti pé Jèhófà ò tiẹ̀ nílò ìtìlẹyìn ọmọ èèyàn kó tó mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.c Apá rẹ̀ alágbára tó bùáyà ti tó láti ṣe iṣẹ́ yẹn. (Sáàmù 44:3; 98:1; Jeremáyà 27:5) Ẹ̀wẹ̀, ìhónú rẹ̀ tún tì í lẹ́yìn pẹ̀lú. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ó rí bẹ́ẹ̀ ní ti pé Ọlọ́run kì í bínú sódì, ìbínú òdodo ni ìbínú rẹ̀ máa ń jẹ́. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ìlànà òdodo ni Jèhófà máa fi ń ṣe gbogbo ohun tó bá ń ṣe, ńṣe ni ìhónú rẹ̀ tì í lẹ́yìn, tó sì sún un láti mú kí “ẹ̀jẹ̀” àwọn ọ̀tá rẹ̀ “tí ń tú ṣùrùṣùrù” di èyí tó “dà wá sí ilẹ̀” láti dójú tì wọ́n àti láti ṣẹ́gun wọn.—Sáàmù 75:8; Aísáyà 25:10; 26:5.
-
-
Jèhófà Ṣe Orúkọ Ẹlẹ́wà fún Ara Rẹ̀Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
c Ó ya Jèhófà lẹ́nu pé ẹnikẹ́ni kò ṣètìlẹyìn. Ó lè jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu lóòótọ́ pé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì lẹ́yìn ikú Jésù, àwọn alágbára nínú ọmọ aráyé ṣì ń tako ìfẹ́ Ọlọ́run síbẹ̀síbẹ̀.—Sáàmù 2:2-12; Aísáyà 59:16.
-