ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ‘Ẹ Kún fún Ìdùnnú Títí Láé Nínú Ohun Tí Èmi Yóò Dá’
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • Wọ́n Gbẹ́kẹ̀ Lé “Ọlọ́run Oríire”

      13, 14. Àwọn ìṣe wo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run ń ṣe tó fi hàn pé wọ́n ti kẹ̀yìn sí i, kí ni ìyẹn yóò sì fà bá wọn?

      13 Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà wá padà sórí ọ̀rọ̀ àwọn tó kọ Jèhófà sílẹ̀ tí wọ́n sì di abọ̀rìṣà paraku. Ó ní: “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin jẹ́ àwọn tí ń fi Jèhófà sílẹ̀, àwọn tí ń gbàgbé òkè ńlá mímọ́ mi, àwọn tí ń tẹ́ tábìlì fún ọlọ́run Oríire, àti àwọn tí ń bu àdàlù wáìnì kún dẹ́nu fún ọlọ́run Ìpín.” (Aísáyà 65:11) Ìṣe àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà ni àwọn Júù apẹ̀yìndà yìí tọrùn bọ̀ bí wọ́n ṣe tẹ́ tábìlì oúnjẹ àti ohun mímu síwájú “ọlọ́run Oríire” àti “ọlọ́run Ìpín” yìí.b Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó bá fi ìwàǹwára lọ ń gbẹ́kẹ̀ lé àwọn òrìṣà wọ̀nyí?

  • ‘Ẹ Kún fún Ìdùnnú Títí Láé Nínú Ohun Tí Èmi Yóò Dá’
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • 15. Ọ̀nà wo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní gbà ń kọbi ara sí ìkìlọ̀ tó wà nínú Aísáyà 65:11, 12?

      15 Lóde òní, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń kọbi ara sí ìkìlọ̀ tó wà ní Aísáyà 65:11, 12. Wọn kò gba “Oríire” gbọ́, nítorí kì í ṣe ohun alágbára àràmàǹdà kan tó lè ṣeni lóore. Wọn kò jẹ́ fi ohun ìní wọn ṣòfò ní gbígbìyànjú láti tu “ọlọ́run Oríire” lójú, ìyẹn ni wọ́n fi ń yàgò fún gbogbo ohun tó bá jẹ mọ́ tẹ́tẹ́ títa. Ó dá wọn lójú hán-únhán-ún pé ṣe làwọn tó ń bọ òrìṣà yìí yóò pàdánù ohun gbogbo lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, nítorí pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà sọ fún pé: “Èmi yóò yàn yín sọ́tọ̀ fún idà.”

  • ‘Ẹ Kún fún Ìdùnnú Títí Láé Nínú Ohun Tí Èmi Yóò Dá’
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • b Nígbà tí Jerome, tó jẹ́ atúmọ̀ Bíbélì (ẹni tí wọ́n bí ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa), ń ṣàlàyé nípa ẹsẹ yìí, ó sọ nípa ohun kan táwọn abọ̀rìṣà máa ń ṣe látijọ́ ní ìparí oṣù tó kẹ́yìn nínú ọdún wọn. Ó kọ̀wé pé: “Wọ́n máa ń tẹ́ tábìlì tó kún fún onírúurú oúnjẹ àti ife ọtí tí wọ́n fi wáìnì dídùn lú, nítorí kí wọ́n lè ṣoríire nídìí ìbísí ti ọdún tó parí, tàbí kí ìbísí lè wà lọ́dún tuntun.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́