ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ‘Ẹ Kún fún Ìdùnnú Títí Láé Nínú Ohun Tí Èmi Yóò Dá’
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • Ìlérí Ọjọ́ Ọ̀la Tó Fini Lọ́kàn Balẹ̀

      27. Ọ̀nà wo ni Aísáyà gbà ṣàpèjúwe ìbàlẹ̀ ọkàn tí yóò wà fáwọn Júù tó padà wálé ní ìlú ìbílẹ̀ wọn?

      27 Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí yóò kọ́kọ́ ṣẹ, báwo ni ìgbésí ayé yóò ṣe rí fún àwọn Júù tó padà bọ̀ wálé lábẹ́ ọ̀run tuntun yẹn? Jèhófà sọ pé: “Kì yóò sí ọmọ ẹnu ọmú kan níbẹ̀ tí ọjọ́ rẹ̀ kéré níye, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí àgbàlagbà kan tí ọjọ́ rẹ̀ kò kún; nítorí pé ẹnì kan yóò kú ní ọmọdékùnrin lásán-làsàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún; àti ní ti ẹlẹ́ṣẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún, a ó pe ibi wá sórí rẹ̀.” (Aísáyà 65:20) Áà, àpèjúwe ìbàlẹ̀ ọkàn tí yóò wà fáwọn ìgbèkùn tó padà wálé yìí kọyọyọ! Ọmọ jòjòló tí ọjọ́ rẹ̀ ṣì kéré níye kò ní ṣẹ́kú rárá. Bẹ́ẹ̀ ni ikú kò ní dá ẹ̀mí àgbàlagbà légbodò.d Ọ̀rọ̀ Aísáyà yìí mà fí àwọn Júù tí yóò padà sí Júdà lọ́kàn balẹ̀ gidi o! Kò ní sídìí fún wọn láti máa jáyà pé àwọn ọ̀tá yóò wá gbé àwọn lọ́mọ lọ tàbí pé àwọn ọ̀tá yóò pa àwọn èèyàn àwọn nítorí pé ààbò tó dájú yóò wà fún wọn ní ilẹ̀ wọn.

      28. Ẹ̀kọ́ wo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà kọ́ wa nípa ìwàláàyè nínú ayé tuntun lábẹ́ Ìjọba rẹ̀?

      28 Kí ni ọ̀rọ̀ Jèhófà wá fi ń yé wa nípa ìgbésí ayé nínú ayé tuntun tí ń bọ̀? Òun ni pé, lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, olúkúlùkù ọmọ yóò ní ìbàlẹ̀ ọkàn nípa ọjọ́ ọ̀la. Kò ní sí olùbẹ̀rù Ọlọ́run tí yóò kú ní rèwerèwe. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú ààbò àti ìfọ̀kànbalẹ̀ ni àwọn tó jẹ́ onígbọràn nínú aráyé yóò wà, tí wọn yóò fi lè gbádùn ayé wọn. Ẹnikẹ́ni tó bá wá yàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run ńkọ́? Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yóò pàdánù àǹfààní láti wà láàyè. Ì báà tiẹ̀ jẹ́ “ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún” ni ọlọ̀tẹ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ yẹn, yóò kú dandan ni. Bí ó bá wá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, òun á jẹ́ “ọmọdékùnrin lásánlàsàn” ní ìfiwéra pẹ̀lú ohun tó yẹ kí ó jẹ́, ìyẹn ẹni tí yóò máa wà láàyè títí lọ gbére.

  • ‘Ẹ Kún fún Ìdùnnú Títí Láé Nínú Ohun Tí Èmi Yóò Dá’
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
    • d Bíbélì The Jerusalem Bible túmọ̀ Aísáyà 65:20 báyìí pé: “Kò ní sí pé ọmọ ọwọ́ ṣẹ́kú mọ́, tàbí pé àgbàlagbà kú láìjẹ́ pé ó gbó, pé ó tọ́.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́