Orílẹ̀-èdè náà Tí Ń Pa Ìwàtítọ́ Mọ́
“Ẹ ṣí ilẹ̀kùn bodè sílẹ̀, kí orílẹ̀-èdè òdodo tí ń sọ òtítọ́ baà lè wọ ilé.”—ISAIAH 26:2.
1. Èéṣe tí gbólóhùn Isaiah nípa “orílẹ̀-èdè òdodo” fi lè yanilẹ́nu?
LÓNÌÍ, onírúurú orílẹ̀-èdè ni ó wà. Àwọn kan jẹ́ ti oníjọba dẹmọ, àwọn kan jẹ́ ti oníjọba bóofẹ́-bóokọ̀. Àwọn kan jẹ́ ọlọ́rọ̀, àwọn kan jẹ́ òtòṣì. Ohun kan tí ó wọ́pọ̀ nípa gbogbo wọn ni pé: Gbogbo wọn jẹ́ apákan ayé tí Satani jẹ́ ọlọrun rẹ̀. (2 Korinti 4:4) Pẹ̀lú ojú ìwòye yìí, àwọn ọ̀rọ̀ Isaiah lè dàbí ohun tí ó ya àwọn kan lẹ́nu nígbà tí ó sọ pé: “Ẹ ṣí ilẹ̀kùn bodè sílẹ̀, kí orílẹ̀-èdè òdodo tí ń sọ òtítọ́ baà lè wọ ilé.” (Isaiah 26:2) Orílẹ̀-èdè òdodo kẹ̀? Bẹ́ẹ̀ni, orílẹ̀-èdè òdodo kan wà níwọ̀n bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ti sọ pé yóò wà ní ọjọ́ tiwa. Báwo ni a ṣe lè dá orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ yìí mọ̀?
2. Kí ni “orílẹ̀-èdè òdodo” náà? Báwo sì ni a ṣe mọ̀?
2 Nínú ọ̀nà tí New World Translation gbà túmọ̀ Isaiah 26:2, orílẹ̀-èdè náà ni a sọ pé ó “ń pa ìwà ìṣòtítọ́ mọ́.” Bibeli King James Version (àlàyé ìlà àárín-ìwé) túmọ̀ ẹsẹ̀ yìí sí, “orílẹ̀-èdè òdodo tí ń sọ òtítọ́.” Méjèèjì jẹ́ àpèjúwe tí ó ṣe wẹ́kú. Níti gàsíkíá, ó rọrùn láti dá orílẹ̀-èdè òdodo náà mọ̀ nítorí pé òun ni orílẹ̀-èdè kanṣoṣo náà lórí ilẹ̀-ayé tí ó wà lábẹ́ Kristi gẹ́gẹ́ bí Ọba, nítorí ìdí èyí kì í ṣe apákan ayé Satani. (Johannu 17:16) Nítorí bẹ́ẹ̀, àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ ni a mọ̀ fún ‘títọ́jú ìwà wọn ní dídára láàárín awọn orílẹ̀-èdè.’ Wọ́n ń gbé ìgbésí-ayé tí ń fògo fún Ọlọrun. (1 Peteru 2:12, NW) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, níbikíbi tí wọ́n bá wà nínú ayé, wọ́n jẹ́ apákan “ìjọ Ọlọrun alààyè, ọwọ̀n ati ìtìlẹyìn òtítọ́.” (1 Timoteu 3:15, NW) Ní ṣíṣètìlẹ́yìn fún òtítọ́, wọ́n kọ àwọn ẹ̀kọ́ èrò-orí ti àwọn abọ̀rìṣà tí Kristẹndọm fi ń kọ́ni, wọ́n sì ń ṣe ìgbélárugẹ “wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ naa”—Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí í ṣe Bibeli. (1 Peteru 2:2, NW) Síwájú síi, wọ́n ń fi tìtara-tìtara wàásù ìhìnrere Ìjọba náà “ninu gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Kolosse 1:23, NW) Iyèméjì èyíkéyìí ha lè wà pé àwọn àṣẹ́kù “Israeli Ọlọrun,” ìjọ àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró, ni wọ́n parapọ̀ di orílẹ̀-èdè yìí bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀ kọ́!—Galatia 6:16, NW.
A Bí Orílẹ̀-Èdè Náà
3. Ṣàpèjúwe bí a ṣe bí “orílẹ̀-èdè òdodo” náà.
3 Nígbà wo ni a bí “orílẹ̀-èdè òdodo” náà? Bí yóò ṣe bẹ̀rẹ̀ ní a sọtẹ́lẹ̀ nínú ìwé Isaiah. Nínú Isaiah 66:7, 8, a kà pé: “Kí [Sioni] tó rọbí, ó bímọ; kí ìrora rẹ̀ kí ó tó dé, ó bí ọmọkùnrin kan. . . . Bí Sioni ti ń rọbí gẹ́ẹ́, bẹ́ẹ̀ni ó bí àwọn ọmọ[kùnrin] rẹ̀.” Ohun àrà-ọ̀tọ̀ gbáà ni ó jẹ́, pé Sioni, ètò-àjọ Ọlọrun ti òkè-ọ̀run, níláti bí “ọmọkùnrin kan” ṣáájú kí ó tó rọbí. Ní 1914 Ìjọba Messia náà ni a bí nínú àwọn ọ̀run. (Ìṣípayá 12:5) Lẹ́yìn ìyẹn, ogun àgbáyé kìn-ín-ní bo àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ púpọ̀ síi bámúbámú, àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró fojúwiná wàhálà wọ́n sì jìyà inúnibíni lílekoko. Níkẹyìn, ní ọdún 1919, a bí orílẹ̀-èdè tẹ̀mí, “ọmọkùnrin” náà lórí ilẹ̀-ayé. Nípa bẹ́ẹ̀ Sioni ‘bí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀’—àwọn mẹ́ḿbà ẹni-àmì-òróró ti “orílẹ̀-èdè òdodo” titun náà—a sì ṣètò àwọn wọ̀nyí fún iṣẹ́ ìjẹ́rìí kan tí ó túbọ̀ ń gbòòrò síi.—Matteu 24:3, 7, 8, 14; 1 Peteru 2:9.
4. Èéṣe tí orílẹ̀-èdè òdodo ti Ọlọrun fi níláti jà fitafita láti pa ìwàtítọ́ mọ́?
4 Láti ìgbà tí a ti bí i, orílẹ̀-èdè yìí ti dojúkọ àwọn àdánwò lílekoko nípa ìwàtítọ́ rẹ̀. Èéṣe? Nígbà tí a bí Ìjọba ti ọ̀run náà, a lé Satani àti àwọn ẹ̀mí-èṣù rẹ̀ jù sí orí ilẹ̀-ayé láti ọ̀run. Ohùn rara kan pòkìkí pé: “Nísinsìnyí ni ìgbàlà dé ati agbára ati ìjọba Ọlọrun wa ati ọlá-àṣẹ Kristi rẹ̀, nitori pé olùfisùn awọn arákùnrin wa ni a ti fi sọ̀kò sísàlẹ̀, ẹni tí ń fẹ̀sùnkàn wọ́n tọ̀sán tòru níwájú Ọlọrun wa! Wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀ nitori ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa ati nitori ọ̀rọ̀ ìjẹ́rìí wọn, wọn kò sì nífẹ̀ẹ́ ọkàn wọn àní lójú ikú pàápàá.” Satani dáhùnpadà sí ìyípadà àyíká ipò yìí pẹ̀lú ìbínú ńlá “ó sì lọ lati bá awọn tí ó ṣẹ́kù lára irú-ọmọ [obìnrin náà] ja ogun, awọn ẹni tí ń pa awọn àṣẹ Ọlọrun mọ́ tí wọ́n sì ní iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jesu.” Bí wọ́n ti dojúkọ ìrọ́lù kíkorò Satani, àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró dúró gbọn-in-gbọn-in. Títí di òní olónìí, àwọn mẹ́ḿbà orílẹ̀-èdè òdodo Ọlọrun tí wọ́n jẹ́ onítara ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ ìràpadà Jesu wọ́n sì ń bá a nìṣó láti mú kí Jehofa rí ìdáhùn fifún olùṣáátá ńlá náà nípa pípa ìwàtítọ́ mọ́ “àní lójú ikú pàápàá.”—Ìṣípayá 12:1, 5, 9-12, 17, NW; Owe 27:11.
5. Ìṣarasíhùwà dídára wo tí àwọn Ẹlẹ́rìí òde-òní fihàn ni ó ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pa ìwàtítọ́ mọ́?
5 Ní 1919, nígbà tí àwọn ẹlẹ́rìí òde-òní fún Ìjọba Ọlọrun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, gẹ́gẹ́ bí a ti ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nígbà náà, kéré níye ṣùgbọ́n wọ́n jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́. Wọ́n di àwọn mẹ́ḿbà ìpìlẹ̀ fún ‘ìlú agbára, tí a yan ìgbàlà fún odi àti ààbò rẹ̀.’ Wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé wọn nínú “Oluwa Jehofa [tí í ṣe] àpáta ayérayé.” (Isaiah 26:1, 3, 4) Bíi ti Mose ìgbàanì, wọ́n pòkìkí pé: “Èmi óò kókìkí orúkọ OLUWA kiri: ẹ fi ọlá fún Ọlọrun wa. Àpáta náà, pípé ni iṣẹ́ rẹ̀; nítorí pé ìdájọ́ ni gbogbo ọ̀nà rẹ̀: Ọlọrun òtítọ́ àti aláìṣègbè, òdodo àti òtítọ́ ni òun.”—Deuteronomi 32:3, 4.
6. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jehofa ti gbà bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí?
6 Láti ìgbà náà wá, àwọn bodè ìṣètò Ìjọba Ọlọrun ti wà ní ṣíṣí sílẹ̀ níwọ̀n bí a ti kọ́kọ́ kó àṣẹ́kù 144,000 àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró jọpọ̀ tí ogunlọ́gọ̀ ńlá ti “awọn àgùtàn mìíràn” sì ń darapọ̀ mọ́ wọn nísinsìnyí nínú pípolongo àwọn ète Ìjọba Jehofa. (Johannu 10:16, NW) Nípa bẹ́ẹ̀, a lè fi tayọ̀tayọ̀ kéde pé: “Ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè bísíi, Oluwa, ìwọ ti mú orílẹ̀-èdè bísíi; ìwọ ti di ẹni-àyìnlógo: ìwọ ti sún gbogbo ààlà síwájú.” (Isaiah 26:15) Bí a ti ń bojúwo pápá ayé lónìí, a ń rí i bí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ti jẹ́ òtítọ́ tó! Nípasẹ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́, a ti jẹ́rìí nípa Ìjọba Kristi tí ń bọ̀wá “títí dé apá ibi jíjìnnà jùlọ ní ilẹ̀-ayé.” (Iṣe 1:8) A lè mọ ibi tí ìmúgbòòrò náà ti dé láti inú Ìròyìn Ọdún Iṣẹ́-Ìsìn 1994 ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Kárí-Ayé, tí ó hàn ní ojú-ìwé 12 sí 15.
Góńgó Titun Nínú Iye Àwọn Akéde
7, 8. (a) Ẹ̀rí wo ni ó wà níbẹ̀ pé àwọn ènìyàn Ọlọrun ti ‘sọ okùn ibùgbé wọn di gígùn’? (b) Ní wíwo Ìròyìn Ọdún Iṣẹ́-Ìsìn 1994, àwọn agbègbè wo ni o rí tí wọ́n ‘ń sọ ààlà wọn di gbígbòòrò’ lọ́nà àrà-ọ̀tọ̀?
7 Gbé díẹ̀ yẹ̀wò lára àwọn kókó inú ìròyìn yìí. Góńgó iye àwọn akéde Ìjọba nínú pápá ti dórí 4,914,094! Ẹ wo bí ó ti móríyá tó láti kíyèsí ìkójọwọlé ‘ogunlọ́gọ̀ ńlá . . . lati inú gbogbo awọn orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ati ènìyàn ati ahọ́n, tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ ati níwájú Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa, tí wọ́n sì wọ aṣọ ìgúnwà funfun’! Bẹ́ẹ̀ni, àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ti fihàn pé àwọn jẹ́ olùpa ìwàtítọ́ mọ́. “Wọ́n sì ti fọ aṣọ ìgúnwà wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa,” níwọ̀n bí a ti kà wọ́n sí olódodo nítorí lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jesu.—Ìṣípayá 7:9, 14, NW.
8 Ní pàtàkì jùlọ láti ọdún 1919 wá, ìpè náà ti dún sí etígbọ̀ọ́ ètò-àjọ Jehofa pé: “Sọ ibi àgọ́ rẹ di gbígbòòrò, sì jẹ́ kí wọ́n na aṣọ títa ibùgbé rẹ jáde: máṣe dásí, sọ okùn rẹ di gígùn, kí o sì mú èèkàn rẹ le.” (Isaiah 54:2) Ní ìdáhùnpadà, iṣẹ́ ìwàásù náà ń bá a lọ láìdáwọ́ dúró, kódà ní ìlú-ńlá Yukon oníyìnyín, tí ó wà ní ààlà ilẹ̀ Alaska, níbi tí àwùjọ àwọn aṣáájú-ọ̀nà oníforítì ti ń farada ìtutùnini tí ó lè dé -45° sí -50° lórí ìwọ̀n Celsius fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ tẹ̀léra. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí ogunlọ́gọ̀ ń rọ́ wọnú orílẹ̀-èdè Jehofa tí ń pa ìwàtítọ́ mọ́ yìí lọ́nà yíyára kánkán ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Ẹnubodè túbọ̀ ṣí sílẹ̀ gbayawu láti gba àwọn wọ̀nyí wọlé láti àwọn ilẹ̀ Asia lẹ́yìn òde Kristẹndọm, láti àwọn ilẹ̀ tí Kọministi jẹgàba lé lórí tẹ́lẹ̀, láti ọ̀pọ̀ nínú àwọn ilẹ̀ Africa, àti láti àwọn pápá àkóso Katoliki, bí Itali, Spania, Portugal, àti South America. Àwọn ènìyàn tí a lé kúrò nílùú ti ṣí pápá mìíràn sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ní England, àwọn Ẹlẹ́rìí ń bójútó àìní àwùjọ ẹ̀yà 13 tí ń sọ èdè àjèjì.
“Ẹ Máa Ṣe Èyí”
9. (a) Kí ni iye àwọn tí ó pésẹ̀ síbi Ìṣe-Ìrántí ọdún 1994 fihàn? (b) Àwọn wo ni díẹ̀ lára àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ní iye àwọn olùpésẹ̀ síbi Ìṣe-Ìrántí tí iye wọn pọ̀ lọ́nà àrà-ọ̀tọ̀?
9 Kókó ìtẹnumọ́ mìíràn nínú ìròyìn ọdọọdún náà ni iye àwọn tí ó wá síbi Ìṣe-Ìrántí. Kété ṣáájú ikú rẹ̀, Jesu dá Ìṣe-Ìrántí tí ń ránnilétí ikú rẹ̀ sílẹ̀ ó sì sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (1 Korinti 11:24, NW) Ó múnilóríyá ní 1994 láti rí 12,288,917—iye tí ó pọ̀ púpọ̀ ju ìlọ́po méjì àwọn akéde ògbóṣáṣá—tí wọ́n péjọpọ̀ láti ṣègbọràn sí àṣẹ yẹn, yálà gẹ́gẹ́ bí olùṣàjọpín tàbí gẹ́gẹ́ bí òǹwòran. Ní àwọn ilẹ̀ kan ìpíndọ́gba iye àwọn tí ó wá síbi Ìṣe-Ìrántí sí àwọn akéde tilẹ̀ ga jù. Inú 4,049 àwọn akéde ní Estonia, Latvia, àti Lithuania dùn láti rí 12,876 tí wọ́n pésẹ̀ síbi Ìṣe-Ìrántí, wọ́n ju iye àwọn akéde lọ ní ìlọ́po mẹ́ta. Ní Benin, àwọn 16,786 tí wọ́n wá síbi Ìṣe-Ìrántí dúró fún iye àwọn akéde ní nǹkan bí ìgbà márùn-ún. Nínú ìjọ kan tí àwọn akéde 45 wà 831 ni iye àwọn tí ó pésẹ̀!
10. (a) Ẹrù-iṣẹ́ wo ni iye àwọn ènìyàn púpọ̀ tí wọ́n wá síbi Ìṣe-Ìrántí gbé kà wá lórí? (b) Ṣàpèjúwe ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹnì kan tí ó wá síbi Ìṣe-Ìrántí bá rí ìrànlọ́wọ́ síwájú síi gbà.
10 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láyọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn olùfìfẹ́hàn darapọ̀ mọ́ wọn ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí ó pèsè ìfojúsọ́nà rere náà. Nísinsìnyí wọ́n fẹ́ láti ran àwọn wọ̀nyí lọ́wọ́ láti túbọ̀ tẹ̀síwájú síi nínú òye àti ìfẹ́ wọn fún òtítọ́. Àwọn kan lè dáhùnpadà bíi ti Alla ní Russia. Alla ń kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan ṣùgbọ́n kò tẹ̀síwájú dàbí alárà, nítorí náà wọ́n dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dúró. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Alla tẹ́wọ́gba ìkésíni láti pésẹ̀ síbi Ìṣe-Ìrántí. Ìpàdé yẹn, èyí tí ó ní ìjẹ́pàtàkì gidi, ní ipa jíjinlẹ̀ lórí rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó padà sílé, ó kó gbogbo ère ìsìn rẹ̀ sọnù ó sì gbàdúrà sí Jehofa fún ìrànlọ́wọ́. Ní ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà náà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Alla láti rí bí ó ti gbádùn Ìṣe-Ìrántí náà sí. Ìjíròrò ṣíṣàǹfààní tibẹ̀ jẹyọ. Ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Alla padà. Kò sì pẹ́ tí ó fi bẹ̀rẹ̀ síí ṣàjọpín nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí. Ìrírí yìí fi ìníyelórí ìkésíni tí a ṣe láti padà ṣiṣẹ́ lórí ọkàn-ìfẹ́ àwọn wọnnì tí wọ́n bá wá síbi Ìṣe-Ìrántí hàn. Ó ṣeé ṣe kí púpọ̀ dáhùnpadà gẹ́gẹ́ bí Alla ti ṣe.
“Kí A Má Máa Ṣá Ìpéjọpọ̀ Ara Wa Tì”
11-13. (a) Kí ni ó jẹ́ apákan ìwà ìṣòtítọ́ orílẹ̀-èdè òdodo náà? (b) Èéṣe tí àwọn Kristian tòótọ́ fi níláti máa lọ sí àwọn ìpàdé?
11 Ìṣe-Ìrántí ni ìpàdé tí ó ṣe pàtàkì jùlọ lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ṣùgbọ́n kì í ṣe òun nìkanṣoṣo ni ìpàdé tí ó wà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń péjọpọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní ìṣègbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nìkínní kejì lati ru ara wa lọ́kàn sókè sí ìfẹ́ ati sí awọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa ṣá ìpéjọpọ̀ ara wa tì, bí awọn kan ti ní àṣà naa, ṣugbọn kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nìkínní kejì, pàápàá jùlọ bí ẹ̀yin ti rí ọjọ́ naa tí ń súnmọ́lé.” (Heberu 10:24, 25, NW) Wọ́n ń darapọ̀ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè òdodo Jehofa tí a ń fi ìwà ìṣòtítọ́ rẹ̀ dámọ̀. Ìwà ìṣòtítọ́ wémọ́ lílọ sí àwọn ìpàdé nígbà gbogbo.
12 A lóye èyí lọ́nà tí ó ṣe kedere ní Philippines, níbi tí ìpíndọ́gba iye àwọn tí ń wá sí ìpàdé ọjọ́ Sunday yíká orílẹ̀-èdè náà ti jẹ́ ìpín 125 nínú ọgọ́rùn-ún iye àwọn akéde. Àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí àti olùfìfẹ́hàn ní Argentina tún lóye rẹ̀ pẹ̀lú. Wọ́n ń gbé ní nǹkan bíi 20 kìlómítà sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, alábòójútó àyíká ròyìn pé bí a bá yọwọ́ ti àìsàn kúrò, kò sí èyíkéyìí tí ń pa ìpàdé jẹ nínú wọn. Wọ́n ń rìnrìn-àjò wákàtí mẹ́rin lórí kẹ̀kẹ́ àfẹṣinfà tàbí lórí ẹṣin, bí ó bá sì di ìgbà otútù wọ́n máa ń rìnrìn-àjò padà sílé ní òru dúdú.
13 Bí òpin ètò-ìgbékalẹ̀ yìí ti túbọ̀ ń súnmọ́lé, ìgbésí-ayé túbọ̀ ń lekoko síi, àwọn ìṣòro ń ga síi, lílọ sí àwọn ìpàdé déédéé sì lè di ìpèníjà gidigidi. Ṣùgbọ́n lábẹ́ irú àwọn àyíká ipò bẹ́ẹ̀, a ní àìní púpọ̀ síi ju ti ìgbàkígbà rí lọ fún oúnjẹ tẹ̀mí àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ọlọ́yàyà ti a lè rí nínú irú àwọn ìpéjọpọ̀ bẹ́ẹ̀ nìkanṣoṣo.
“Wà Lẹ́nu Rẹ̀ Ní Kánjúkánjú”
14. Èéṣe tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ní òye ìmọ̀lára ìjẹ́kánjú-kánjú nípa iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn, ìyọrísí wo ni ó sì fi èyí hàn?
14 Ní ọdún tí ó kọjá, Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki ní Itali tọ́ka sí iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gẹ́gẹ́ bí “ìfijàgídíjàgan sọni di aláwọ̀ṣe.” Ṣùgbọ́n, òtítọ́ ni pé kò sí ohunkóhun tí ó jọ jàgídíjàgan nínú ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn jẹ́ fífi ìfẹ́ jíjinlẹ̀ hàn fún àwọn aládùúgbò wọn. Ó tún jẹ́ ẹ̀rí ìṣègbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ Paulu pé: “Wàásù ọ̀rọ̀ naa, wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú ní àsìkò tí ó rọgbọ, ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú.” (2 Timoteu 4:2, NW) Òye ìmọ̀lára ìjẹ́kánjú-kánjú ń sún àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láti jẹ́ onítara nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú lílò tí wọ́n lo àròpọ̀ 1,096,065,354 wákàtí ní 1994 fún wíwàásù fún àwọn aládùúgbò wọn, ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò, àti dídarí 4,701,357 ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ó ṣeé ṣe fún púpọ̀ láti nípìn-ín nínú iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà, èyí tí ó fihàn pé ẹ̀mí aṣáájú-ọ̀nà ń jófòfò. Ìpíndọ́gba 636,202 aṣáájú-ọ̀nà kárí-ayé jẹ́rìí sí èyí.
15, 16. (a) Báwo ni tèwe-tàgbà ṣe fi ẹ̀mí aṣáájú-ọ̀nà hàn? (b) Ní wíwo orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan nínú Ìròyìn Ọdún Iṣẹ́-Ìsìn 1994, níbo ni o ti rí iye àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí ó tayọ jùlọ?
15 Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ wà lára àwọn aṣáájú-ọ̀nà yẹn. Nísinsìnyí àwọn kan ní United States ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé nígbà tí wọ́n ń lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga, tí àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn sì jẹ́ agbègbè ìpínlẹ̀ wọn pàtàkì. Àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí ti rí i pé ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà ni ọ̀nà tí ó dára jùlọ fún dídáàbòbo araawọn kúrò lọ́wọ́ oògùn, ìwà pálapàla, àti ìwà ipá tí ó kún inú ọ̀pọ̀ ilé-ẹ̀kọ́ dẹ́nu ní ilẹ̀ náà. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ mìíràn ní iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà gẹ́gẹ́ bí góńgó wọn nígbà tí wọ́n bá jáde ilé-ẹ̀kọ́. Irina, ní Ukraine, ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ títí jálẹ̀ gbogbo àkókó tí ó fi wà ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga kí ó baà lè múra araarẹ̀ sílẹ̀ fún ṣíṣe aṣáájú-ọ̀nà lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́yege. Nígbà tí ó jáde ilé-ẹ̀kọ́, ìdílé rẹ̀ yàn láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa bíbójútó àìní rẹ̀ níti ọ̀ràn ìnáwó kí ó baà lè ṣojú fún wọn nínú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Níti ìṣúnná-owó, àwọn nǹkan kò rọrùn ní Ukraine. Ṣùgbọ́n Irina sọ pé: “Mo mọ̀ pé mo ń ṣe iṣẹ́ kan tí kìí ṣe èmi nìkanṣoṣo ni ó túmọ̀ sí ìyè fún ṣùgbọ́n fún àwọn wọnnì tí mo ń wàásù fún pẹ̀lú.” Ó jẹ́ ohun tí ó dùnmọ́ni nítòótọ́ láti rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ lónìí tí wọ́n ń ronú bíi ti Irina. Ọ̀nà dídára jù wo ni ó wà fún wọn láti ‘rántí ẹlẹ́dàá wọn ní ọjọ́ èwe wọn ju ìyẹn lọ’?—Oniwasu 12:1.
16 Ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà jẹ́ àgbàlagbà. Ọ̀kan ròyìn pé nígbà ogun àgbáyé kejì, bàbá òun àti arákùnrin òun ni a pa níbi tí wọ́n ti ń jagun, tí a sì yìnbọn pa ìyá àti arábìnrin òun ní àgọ́ àwọn akúṣẹ̀ẹ́. Lẹ́yìn náà ikú mú ọmọkùnrin rẹ̀ lọ. Nísinsìnyí, bí ọjọ́-ogbó ti ń dé sí i tí ó sì ń jìyà àìlera, Jehofa ti fún un ní ìdílé tí ó túbọ̀ pọ̀ nínú ìjọ Kristian ju èyí tí ó ti pàdánù lọ. Ó sì ń rí ayọ̀ rẹ̀ nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé.
17, 18. Báwo ni ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, yálà a jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣe lè fi ẹ̀mí aṣáájú-ọ̀nà hàn?
17 Àmọ́ ṣáá o, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ó lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ó dùn mọ́ Jehofa nínú láti gba gbogbo ìdámẹ́wàá wa, èyí tí ó dára jùlọ tí a lè fifúnni, ohun yòówù kí èyí jẹ́ nínú ọ̀ràn tiwa fúnra wa. (Malaki 3:10, àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé) Nítòótọ́, gbogbo wa lè mú ẹ̀mí àwọn aṣáájú-ọ̀nà onítara wọ̀nyí dàgbà kí a sì ṣe ohunkóhun tí àyíká ipò wa bá yọ̀ọ̀da láti mú ìwàásù ìhìnrere náà tẹ̀síwájú.
18 Fún àpẹẹrẹ, ní Australia, April 16 ni a yàsọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àkànṣe fún ìjẹ́rìí òpópónà. Àwọn akéde àti àwọn aṣáájú-ọ̀nà pẹ̀lú kọ́wọ́tì í dáradára, gẹ́gẹ́ bí góńgó titun ti 58,780 nínú iye àwọn akéde ní oṣù yẹn ti jẹ́rìí síi. Síwájú síi, a pín ìwé ìròyìn tí ó fi 90,000 ju iye tí a pín ní oṣù kan náà ní ọdún tí ó kọjá. Ní ọjọ́ àkànṣe náà, arábìnrin kan fi ìwé-ìròyìn sóde lọ́dọ̀ ọkùnrin kan, nígbà tí ó sì ń kọ orúkọ àti àdírẹ́sì rẹ̀ sílẹ̀ kí ó baà lè padà ṣiṣẹ́ lórí ọkàn-ìfẹ́ náà, ó wá rí i pé ẹbí ni àwọn jẹ́! Ó ṣẹlẹ̀ pé ó jẹ́ ọmọkùnrin ẹ̀gbọ́n ìyá akéde náà ó sì tó 30 ọdún tí àwọn méjèèjì ti ríra gbẹ̀yìn. Dájúdájú ìyẹn ṣí àyè sílẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò tí ó máyọ̀wá!
Pa Ìwàtítọ́ Mọ́ Títí Dé Òpin
19. Èéṣe tí ó fi jẹ́ kánjúkánjú pé kí orílẹ̀-èdè òdodo Jehofa pa ìwàtítọ́ mọ́ dé òpin gbẹrẹgbẹrẹ?
19 Ó jẹ́ kánjúkánjú pé kí gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú orílẹ̀-èdè òdodo Ọlọrun pa ìwàtítọ́ mọ́ bí ayé Satani ti ń lọ sí òpin rẹ̀. Láìpẹ́, orílẹ̀-èdè mímọ́ Jehofa yóò gbọ́ ìkésíni náà pé: “Wá, ènìyàn mi, wọ inú iyẹ̀wù rẹ lọ, sì sé ilẹ̀kùn rẹ mọ́ ara rẹ: fi ara rẹ pamọ́ bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan, títí ìbínú náà fi rékọjá.” Lọ́nà tí kò ṣeé yẹ̀sílẹ̀ ayé tí ó ti jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ yìí yóò jìyà ìdájọ́ àtọ̀runwá. “Nítorí náà, kíyèsí i, Oluwa ti ipò rẹ̀ jáde láti bẹ àìṣedéédéé ẹni tí ń gbé orí ilẹ̀ wò lórí ilẹ̀; ilẹ̀ pẹ̀lú yóò fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ hàn, kì yóò sì bo òkú rẹ̀ mọ́.” (Isaiah 26:20, 21) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan dúró gbọn-in-gbọn-in gẹ́gẹ́ bí Kristian olùpa ìwàtítọ́ mọ́ tí ń kẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè òdodo ti Jehofa. Nígbà náà àwa yóò yọ̀ láti jèrè ìye àìnípẹ̀kun nínú ilẹ̀-àkóso Ìjọba Kristi ní orí ilẹ̀-ayé tàbí ní òkè ọ̀run.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Nígbà wo ni a bí “orílẹ̀-èdè òdodo” náà?
◻ Èéṣe tí ó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn Ọlọrun nílò ìfaradà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí?
◻ Kí ni iye àwọn akéde àti wákàtí gíga tí a lò nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ náà ṣàpẹẹrẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú Ìròyìn Ọdún Iṣẹ́-Ìsìn 1994?
◻ Èéṣe tí pípésẹ̀ sí àwọn ìpàdé fi ṣe pàtàkì gan-an bí ayé yìí ti túbọ̀ ń súnmọ́ òpin rẹ̀?
◻ Èéṣe tí gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n darapọ̀ mọ́ orílẹ̀-èdè òdodo Ọlọrun fi gbọ́dọ̀ pa ìwàtítọ́ mọ́?
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 12-15]
ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 1994 TI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA KÁRÍ AYÉ
(Wo àdìpọ̀)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn olùpa ìwàtítọ́ mọ́ nínú orílẹ̀-èdè òdodo Jehofa yóò jèrè ìyè àìnípẹ̀kun nínú ìjẹ́pípé