-
Ayé Tuntun Náà—Ṣé Wàá Wà Níbẹ̀?Ilé Ìṣọ́—2000 | April 15
-
-
6. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ kẹrin tó mẹ́nu kan “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
6 Ẹ jẹ́ kí a wá gbé ibi kan tó kù tí gbólóhùn náà ti jẹ yọ yẹ̀ wò, ìyẹn ni “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun,” tó wà nínú Aísáyà orí kẹrìndínláàádọ́rin, ẹsẹ ìkejìlélógún sí ìkẹrìnlélógún tó sọ pé: “‘Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun tí èmi yóò ṣe ti dúró níwájú mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ yín àti orúkọ yín yóò dúró. Dájúdájú, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé láti òṣùpá tuntun dé òṣùpá tuntun àti láti sábáàtì dé sábáàtì, gbogbo ẹran ara yóò wọlé wá tẹrí ba níwájú mi,’ ni Jèhófà wí. ‘Wọn yóò sì jáde lọ ní tòótọ́, wọn yóò sì wo òkú àwọn ènìyàn tí ń rélànà mi kọjá; nítorí pé kòkòrò mùkúlú tí ó wà lára wọn kì yóò kú, iná wọn ni a kì yóò sì fẹ́ pa, wọn yóò sì di ohun tí ń kóni nírìíra fún gbogbo ẹran ara.’”
7. Èé ṣe táa fi lè parí èrò sí pé Aísáyà orí kẹrìndínláàádọ́rin, ẹsẹ ìkejìlélógún sí ìkẹrìnlélógún yóò nímùúṣẹ lọ́jọ́ iwájú?
7 Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ kan láàárín àwọn Júù tí wọ́n padà sí orílẹ̀-èdè wọn, àmọ́ yóò tún ní ìmúṣẹ mìíràn. Ìyẹn yóò sì jẹ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí a bá ti kọ lẹ́tà kejì ti Pétérù àti ìwé Ìṣípayá, nítorí pé wọ́n tọ́ka sí ‘ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun’ ti ọjọ́ iwájú. A lè máa fojú sọ́nà fún ìmúṣẹ kíkọyọyọ tó sì pé pérépéré náà nínú ètò tuntun àwọn nǹkan. Gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ipò tí a lè máa fojú sọ́nà láti gbádùn.
-
-
Ayé Tuntun Náà—Ṣé Wàá Wà Níbẹ̀?Ilé Ìṣọ́—2000 | April 15
-
-
10. Èé ṣe tó fi lè dá ọ lójú pé ilẹ̀ ayé tuntun náà kò ní di èyí tí àwọn ẹni ibi bà jẹ́ láìsí àtúnṣe?
10 Aísáyà orí kẹrìndínláàádọ́rin ẹsẹ ìkẹrìnlélógún mú un dá wa lójú pé àlàáfíà àti òdodo inú ilẹ̀ ayé tuntun náà kò ní wà nínú ewu. Àwọn ẹni ibi ò ní bà á jẹ́. Rántí pé Pétérù kejì orí kẹta ẹsẹ ìkeje sọ pé ohun tó wà níwájú wa ni “ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” Àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò di ẹni àwátì. Kò sí ewu kankan tí yóò bá àwọn aláìṣẹ̀, ìyẹn yàtọ̀ pátápátá sí ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ogun tí ènìyàn ń jà, níbi tí àwọn aráàlú tí ogun ń pa ti ń pọ̀ ju àwọn jagunjagun tó ń kú lójú ogun lọ. Atóbilọ́lá Adájọ́ náà fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ọjọ́ òun yóò jẹ́ ọjọ́ ti a óò pa àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run run.
11. Kí ni Aísáyà fi hàn pé yóò jẹ́ ọjọ́ ọ̀la ẹnikẹ́ni tó bá lòdì sí Ọlọ́run àti ìjọsìn rẹ̀?
11 Àwọn olódodo tó bá là á já yóò rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run. Ẹsẹ ìkẹrìnlélógún sọ tẹ́lẹ̀ pé “òkú àwọn ènìyàn tí ń rélànà” Jèhófà “kọjá” ni yóò jẹ́ ẹ̀rí ìdájọ́ rẹ̀. Èdè àpèjúwe tí Aísáyà lò lè dàbí ohun tó múni gbọ̀n rìrì. Síbẹ̀, ó ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ìtàn àtijọ́ kan tí kò ṣeé já ní koro. Ẹ̀yìn ògiri Jerúsálẹ́mù ìgbàanì ni ibi tí wọ́n máa ń da ìdọ̀tí sí wà, ìgbà kọ̀ọ̀kan sì wà tí wọ́n máa ń ju òkú àwọn ọ̀daràn síbẹ̀, ìyẹn àwọn táa dá lẹ́jọ́ pé wọn ò yẹ lẹ́ni táa ń sin lọ́nà yíyẹ.a Kì í sì í pẹ́ tí àwọn kòkòrò mùkúlú àti iná tó wà níbẹ̀ fi ń yanjú àwọn ìdọ̀tí àti àwọn òkú wọ̀nyẹn. Ó ṣe kedere pé àwòrán tí Aísáyà fojú inú rí yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé lọ́tẹ̀ yìí o, ìdájọ́ Jèhófà lórí àwọn tó ń fojú pa ìlànà rẹ̀ rẹ́ yóò jẹ́ àṣekágbá.
-