-
Ọlọ́run Tó “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
“Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín . . . máa di funfun bíi yìnyín”
10. Tí Jèhófà bá ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kí nìdí tí kò fi yẹ ká rò pé àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yẹn á ṣì wà lára wa jálẹ̀ ìgbésí ayé wa?
10 Ṣó o ti gbìyànjú láti mú àbààwọ́n kúrò lára aṣọ funfun rí? Pẹ̀lú gbogbo bó o ṣe fọ̀ ọ́ tó, àbààwọ́n náà ò kúrò. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Jèhófà sọ tó jẹ́ ká mọ bí ìdáríjì rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó. Ó ní: “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tiẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, wọ́n máa di funfun bíi yìnyín; bí wọ́n tiẹ̀ pọ́n bí aṣọ tó pupa yòò, wọ́n máa dà bí irun àgùntàn.” (Àìsáyà 1:18) Bó ṣe wù ká gbìyànjú tó, a ò lè mú àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kúrò fúnra wa. Àmọ́ Jèhófà lè sọ ẹ̀ṣẹ̀ tó pupa bí aṣọ rírẹ̀dòdò tàbí èyí tó pọ́n yòò di funfun gbòò bí ìrì dídì tàbí bí irun àgùntàn tí a kò tíì pa láró. Tí Jèhófà bá ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, kò yẹ ká máa rò pé àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yẹn á ṣì wà lára wa jálẹ̀ ìgbésí ayé wa.
-
-
Ọlọ́run Tó “Ṣe Tán Láti Dárí Jini”Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
4. Kí ni Jèhófà máa ń rántí nípa àwa èèyàn, báwo lèyí ṣe kan bó ṣe ń ṣe sí wa?
-