-
Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀tá Ìkẹyìn, Ikú Di Ohun AsánIlé Ìṣọ́—2014 | September 15
-
-
10. (a) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa sọ ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù di asán? (b) Kí làwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí fi hàn nípa Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀?
10 Jèhófà lágbára láti gba Pọ́ọ̀lù sílẹ̀. Ní kété lẹ́yìn tí Aísáyà sọ̀rọ̀ “ìràgàbò,” ó sọ ní ẹsẹ tó tẹ̀ lé e pé: “Òun yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.” (Aísá. 25:8) Bíi bàbá onífẹ̀ẹ́ kan tó yanjú ìṣoro àwọn ọmọ rẹ̀ tó sì nu omijé ojú wọn kúrò, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe fẹ́ sọ ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù di asán! Jésù ni Jèhófà sì máa lò. Ìwé 1 Kọ́ríńtì 15:22 sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi.” Bákan náà, lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù béèrè pé “Ta ni yóò gbà mí?” ó sọ síwájú sí i pé: “Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa!” (Róòmù 7:25) Ó ṣe kedere pé bí Ádámù àti Éfà tiẹ̀ ya ọlọ̀tẹ̀, síbẹ̀ ìfẹ́ tó mú kí Jèhófà dá ìran èèyàn kò dín kù. Bákan náà, Jésù tó wà pẹ̀lú Jèhófà nígbà tó dá tọkọtaya àkọ́kọ́ ò jẹ́ kí ìfẹ́ tó ní sí àtọmọdọ́mọ wọn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ dín kù. (Òwe 8:30, 31) Àmọ́, báwo ni aráyé ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú?
-
-
Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀tá Ìkẹyìn, Ikú Di Ohun AsánIlé Ìṣọ́—2014 | September 15
-
-
15, 16. (a) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà, ‘ọ̀tá ìkẹyìn, ìyẹn ikú,’ tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀? Ìgbà wo sì ni yóò di asán? (b) Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 15:28, kí ni Jésù máa ṣe láìpẹ́?
15 Ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún ìṣàkóso Ìjọba Kristi, àwọn ẹ̀dá èèyàn tó jẹ́ onígbọràn yóò ti bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí àìgbọràn Ádámù sọ di ọ̀tá aráyé. Bíbélì sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi. Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ní ẹgbẹ́ tirẹ̀: Kristi àkọ́so, lẹ́yìn náà àwọn tí ó jẹ́ ti Kristi [ìyẹn àwọn tó máa bá a ṣàkóso] nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ni òpin, nígbà tí ó bá fi ìjọba lé Ọlọ́run àti Baba rẹ̀ lọ́wọ́, nígbà tí ó bá ti sọ gbogbo ìjọba àti gbogbo ọlá àṣẹ àti agbára di asán. Nítorí òun gbọ́dọ̀ ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba títí Ọlọ́run yóò fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a ó sọ di asán.” (1 Kọ́r. 15:22-26) Nígbẹ̀yìn gbẹ́yìn, ikú tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù kò ní sí mọ́. “Ìràgàbò” tó bo gbogbo aráyé mọ́lẹ̀ kò ní sí mọ́ títí láé.—Aísá. 25:7, 8.
-