ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 7/15 ojú ìwé 32
  • O Lè Ní “Ọkàn Kìnnìún”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Lè Ní “Ọkàn Kìnnìún”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 7/15 ojú ìwé 32

O Lè Ní “Ọkàn Kìnnìún”

NÍGBÀ míràn, Bíbélì máa ń lo kìnnìún gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìgboyà àti àyà níní. A ṣàpèjúwe àwọn akíkanjú tàbí onígboyà ọkùnrin pé wọ́n ní “ọkàn kìnnìún,” a sì sọ pé àwọn olódodó “láyà bíi kìnnìún.” (Sámúẹ́lì Kejì 17:10; Òwe 28:1) Ní pàtàkì, nígbà tí a bá tọ́ ọ níjà, kìnnìún máa ń fi hàn pé òún lẹ́tọ̀ọ́ sí ìfùsì òun gẹ́gẹ́ bí ‘alágbára jù lọ nínú ẹranko.’—Òwe 30:30.

Àìbẹ̀ru kìnnìún ni Jèhófà Ọlọ́run fi ìpinnu rẹ̀ láti dáàbò bo àwọn ènìyàn rẹ̀ wé. Aísáyà 31:4, 5 sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bíi kìnnìún àti ẹgbọrọ kìnnìún ti ń kùn sí ohun ọdẹ rẹ̀, nígbà tí a ń pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́ àgùntàn jáde wá sí i, tí òun kò bẹ̀rù ohùn wọn, tí kò sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ariwo wọn: bẹ́ẹ̀ ni Olúwa àwọn ọmọ ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wá láti jà lórí òkè ńlá Síónì, . . . ní dídáàbò bò ọ́ pẹ̀lú yóò sì gbà ọ́ sílẹ̀; ní ríré kọjá òun óò sì dá a sí.” Jèhófà tipa báyìí mú ìtọ́jú alágbára rẹ̀ dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lójú, pàápàá lóju wàhálà.

Bíbélì fi elénìní aráyé gíga jù lọ, Sátánì Èṣù, wé kìnnìún arébipa, tí ń ké ramúramù. Láti yẹra fún dídi ohun ọdẹ rẹ̀, a sọ fún wa nínú Ìwé Mímọ́ pé: “Ẹ pa àwọn agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára.” (Pétérù Kìíní 5:8) Ọ̀nà kan láti ṣe èyí jẹ́ nípa yíyẹra fún ìtòògbé aṣekúpani nípa tẹ̀mí. Nípa èyí, Jésù sọ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín kí ọkàn-àyà yín má baà di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé.” (Lúùkù 21:34-36) Bẹ́ẹ̀ ni, wíwà lójúfò nípa tẹ̀mí ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí lè fún wa ní “ọkàn kìnnìún,” ọ̀kan tí ó ‘dúró ṣánṣán, tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa.’—Tímótì Kejì 3:1; Orin Dáfídì 112:7, 8.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́