ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jèhófà Tú Ìbínú Rẹ̀ Sórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
    • 16, 17. Kí ni Édómù yóò dà, yóò sì ti pẹ́ tó tí yóò fi wà bẹ́ẹ̀?

      16 Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tẹ̀ síwájú, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ẹranko ló máa wá rọ́pò àwọn èèyàn tí ń gbé ilẹ̀ Édómù, tí í ṣe àmì ahoro tí ń bọ̀, ó ní: “Láti ìran dé ìran ni yóò gbẹ hán-ún hán-ún; títí láé àti láéláé, kò sí ẹni tí yóò gbà á kọjá. Ẹyẹ òfú àti òòrẹ̀ yóò sì gbà á, àwọn òwìwí elétí gígùn àti ẹyẹ ìwò pàápàá yóò sì máa gbé inú rẹ̀; òun yóò sì na okùn ìdiwọ̀n òfìfo àti àwọn òkúta òfò sórí rẹ̀. Àwọn ọ̀tọ̀kùlú rẹ—kò sí ìkankan níbẹ̀ tí wọn yóò pè wá sí ipò ọba, àní gbogbo ọmọ aládé rẹ̀ yóò sì di aláìjámọ́ nǹkan kan. Ẹ̀gún yóò hù sórí àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀, èsìsì àti èpò ẹlẹ́gùn-ún yóò hù sí àwọn ibi olódi rẹ̀; yóò sì di ibi gbígbé fún àwọn akátá, àgbàlá fún àwọn ògòǹgò. Àwọn olùgbé ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò sì bá àwọn ẹranko tí ń hu pàdé, ẹ̀mí èṣù onírìísí ewúrẹ́ pàápàá yóò sì pe alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, ó dájú pé ibẹ̀ ni ẹyẹ aáṣẹ̀rẹ́ yóò fara balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ sí, tí yóò sì ti rí ibi ìsinmi fún ara rẹ̀. Ibẹ̀ ni ejò ọlọ́fà kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí, tí ó sì yé ẹyin sí.”—Aísáyà 34:10b-15.a

      17 Àní sẹ́, Édómù yóò dahoro. Yóò dá páropáro, tó fi jẹ́ pé àwọn ẹranko ẹhànnà, àti ẹyẹ, àti ejò nìkan ló máa kù síbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ kẹwàá ti wí, ilẹ̀ gbígbẹ ni yóò jẹ́ “títí láé àti láéláé.” Kò ní padà bọ̀ sípò.—Ọbadáyà 18.

  • Jèhófà Tú Ìbínú Rẹ̀ Sórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
    • a Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ní ìmúṣẹ nígbà tó fi máa di ìgbà ayé Málákì. (Málákì 1:3) Málákì ròyìn pé àwọn ọmọ Édómù retí àtitún ilẹ̀ wọn tó ti dahoro kọ́. (Málákì 1:4) Àmọ́ o, ìfẹ́ Jèhófà kọ́ nìyẹn, nígbà tó sì ṣe, àwọn ará ibòmíràn, ìyẹn àwọn Nábátíà, wá ń gbé ibi tó jẹ́ ilẹ̀ Édómù tẹ́lẹ̀ rí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́