ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Párádísè Ti Padà Bọ̀ Sípò!
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
    • Ilẹ̀ Ahoro Ń Yọ Ayọ̀

      3. Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àyípadà wo ló máa bá ilẹ̀ yẹn?

      3 Ọ̀rọ̀ tó bẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ onímìísí tí Aísáyà sọ nípa Párádísè táa mú padà bọ̀ sípò, lọ báyìí pé: “Aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì. Láìkùnà, yóò yọ ìtànná, ní ti tòótọ́ yóò fi tayọ̀tayọ̀ kún fún ìdùnnú àti fífi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde. Ògo Lẹ́bánónì pàápàá ni a ó fi fún un, ọlá ńlá Kámẹ́lì àti ti Ṣárónì. Àwọn kan yóò wà tí yóò rí ògo Jèhófà, ọlá ńlá Ọlọ́run wa.”—Aísáyà 35:1, 2.

      4. Ìgbà wo ni ìlú ìbílẹ̀ àwọn Júù dà bí aginjù, báwo ló sì ṣe dà bẹ́ẹ̀?

      4 Nǹkan bí ọdún 732 ṣááju Sànmánì Tiwa ni Aísáyà kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Ní nǹkan bí ọdún márùnlélọ́gọ́fà lẹ́yìn náà, àwọn ará Bábílónì wá pa Jerúsálẹ́mù run, àwọn ará Júdà sì dèrò ìgbèkùn. Ìlú ìbílẹ̀ wọn wá di ahoro tó dá páropáro. (2 Àwọn Ọba 25:8-11, 21-26) Bí ìkìlọ̀ tí Jèhófà fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì pé bí wọ́n bá di aláìṣòótọ́ wọn yóò dèrò ìgbèkùn ṣe ṣẹ nìyẹn o. (Diutarónómì 28:15, 36, 37; 1 Àwọn Ọba 9:6-8) Nígbà tí àwọn ará Hébérù dèrò ìgbèkùn ní ilẹ̀ òkèèrè, àwọn oko àti ọgbà eléso wọn tí wọ́n ń bomi rin dáadáa kò rí àbójútó fún àádọ́rin ọdún, ó wá dà bí aginjù.—Aísáyà 64:10; Jeremáyà 4:23-27; 9:10-12.

      5. (a) Báwo ni ilẹ̀ náà ṣe padà bọ̀ sípò tó wá dà bíi Párádísè? (b) Ọ̀nà wo làwọn èèyàn gbà “rí ògo Jèhófà”?

      5 Àmọ́ o, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ti sọ ọ́ ṣáájú pé ilẹ̀ yẹn ò ní wà láhoro títí ayé. Yóò ṣì padà di Párádísè ní ti gidi. Yóò gba “ògo Lẹ́bánónì” àti “ọlá ńlá Kámẹ́lì àti ti Ṣárónì.”a Lọ́nà wo? Bí àwọn Júù ṣe padà dé láti ìgbèkùn, àyè ṣí sílẹ̀ fún wọn láti tún bẹ̀rẹ̀ sí dá oko wọn, kí wọ́n sì máa bomi rin ín, ilẹ̀ wọn sì wá padà di ibi eléso wọ̀ǹtìwọnti bíi ti tẹ́lẹ̀ rí. Ọpẹ́lọpẹ́ Jèhófà nìyẹn sì fi wáyé. Fífẹ́ tó fẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú ìtìlẹyìn àti ìbùkún rẹ̀, làwọn Júù fi lè wà nínú irú ipò tó dà bíi Párádísè bẹ́ẹ̀. Ó wá ṣeé ṣe fáwọn èèyàn yẹn láti rí “ògo Jèhófà, ọlá ńlá Ọlọ́run” wọn nígbà tí wọ́n gbà pé Jèhófà lọ́wọ́ sí àyípadà tó bá ilẹ̀ àwọn.

      6. Ọ̀nà pàtàkì wo ni ọ̀rọ̀ Aísáyà gbà ṣẹ?

      6 Àmọ́ ṣá, ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣẹ lọ́nà kan tó túbọ̀ ṣe pàtàkì ju ìwọ̀nyí lọ nínú ilẹ̀ Ísírẹ́lì tó padà bọ̀ sípò. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ibi gbígbẹ tó dà bí aṣálẹ̀ ni Ísírẹ́lì jẹ́ nípa tẹ̀mí. Lásìkò tí wọ́n fi wà nígbèkùn ní Bábílónì, ó ṣòro gidigidi láti ṣe ìsìn mímọ́ gaara. Kò sí tẹ́ńpìlì, kò sí pẹpẹ, kò sì sí ìṣètò ẹgbẹ́ àlùfáà. Ẹbọ ojoojúmọ́ dáwọ́ dúró. Wàyí o, Aísáyà wá ń sọ tẹ́lẹ̀ pé nǹkan máa yí padà. Lábẹ́ ìdarí àwọn èèyàn bíi Serubábélì, Ẹ́sírà àti Nehemáyà, àwọn aṣojú látinú ẹ̀yà méjèèjìlá Ísírẹ́lì padà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n tún tẹ́ńpìlì kọ́, wọ́n sì ń sin Jèhófà ní fàlàlà. (Ẹ́sírà 2:1, 2) Párádísè nípa tẹ̀mí ló dé yìí o!

  • Párádísè Ti Padà Bọ̀ Sípò!
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
    • a Ìwé Mímọ́ ṣàpèjúwe Lẹ́bánónì àtijọ́ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ eléso tó ní àwọn igbó tútù yọ̀yọ̀, tó sì ní àwọn igi kédárì ńláńlá, tó ṣeé fi wé Ọgbà Édẹ́nì. (Sáàmù 29:5; 72:16; Ìsíkíẹ́lì 28:11-13) Àwọn èèyàn mọ Ṣárónì gẹ́gẹ́ bí ibi tó ní àwọn odò àti igi óákù; òkìkí Kámẹ́lì sì kàn fún níní tó ní àwọn ọgbà àjàrà, ọgbà eléso, àti àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè tí àwọn òdòdó bò lọ súà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́