-
“Ọlọ́gbọ́n Ni”—Síbẹ̀ Ó Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
3 Jèhófà jẹ́ mímọ́, torí náà kò ní ìwà burúkú èyíkéyìí bí ìgbéraga tó máa ń sọni di ẹlẹ́gbin. (Máàkù 7:20-22) Kíyè sí ohun tí wòlíì Jeremáyà sọ fún Jèhófà, ó ní: “Ó dájú pé o máa rántí, wàá sì bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ kí o lè ràn mí lọ́wọ́.”a (Ìdárò 3:20) Àbẹ́ ò rí nǹkan! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run ṣe tán láti “bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀,” tàbí rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ sí ipò rírẹlẹ̀ tí Jeremáyà wà, kó lè ràn án lọ́wọ́. (Sáàmù 113:7) Jèhófà mà nírẹ̀lẹ̀ o! Àmọ́ báwo ló ṣe ń fi hàn pé òun jẹ́ onírẹ̀lẹ̀? Báwo ni ọgbọ́n ṣe ń hàn nínú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ Jèhófà? Báwo ló sì ṣe ń ṣe wá láǹfààní?
-
-
“Ọlọ́gbọ́n Ni”—Síbẹ̀ Ó Jẹ́ Onírẹ̀lẹ̀Sún Mọ́ Jèhófà
-
-
a Nígbà àtijọ́, àwọn adàwékọ tó ń jẹ́ Sóférímù yí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí pa dà, wọ́n sọ pé Jeremáyà ló bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, dípò Jèhófà. Wọ́n gbà pé kò bọ́gbọ́n mu láti sọ pé Ọlọ́run “bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀,” tàbí rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀ kó lè ran èèyàn lọ́wọ́. Torí náà, ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ni kò gbé kókó pàtàkì inú ẹsẹ yìí yọ.
-