-
“Ọkàn Rẹ Yóò . . . Tẹ̀ Ba Mọ́lẹ̀ Lórí Mi”Ilé Ìṣọ́—2012 | June 1
-
-
ÌWÀ ìrẹ̀lẹ̀ máa ń fani mọ́ra gan-an. A sábà máa ń fà mọ́ àwọn tó bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé láyé òde òní, àwọn tó ní ojúlówó ìrẹ̀lẹ̀ kò wọ́pọ̀, pàápàá láàárín àwọn tí wọ́n ní agbára tàbí àṣẹ lórí àwọn ẹlòmíì. Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ alágbára jù lọ láyé àtọ̀run wá ńkọ́? Ṣé òun náà níwà ìrẹ̀lẹ̀? Jẹ́ ká wo ohun tí wòlíì Jeremáyà sọ nínú ìwé Ìdárò 3:20, 21.—Kà á.
-
-
“Ọkàn Rẹ Yóò . . . Tẹ̀ Ba Mọ́lẹ̀ Lórí Mi”Ilé Ìṣọ́—2012 | June 1
-
-
Ó dá Jeremáyà lójú pé Jèhófà máa “tẹ̀ ba mọ́lẹ̀” lórí àwọn èèyàn tó bá ronú pìwà dà. Ìtúmọ̀ Bíbélì míì sọ pé: “Jọ̀wọ́ rántí, kó o sì bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ wá sọ́dọ̀ mi.” Gbólóhùn yìí jẹ́ ká lè máa fojú inú wo Jèhófà pé ó jẹ́ Ọlọ́run aláàánú. Jèhófà tó jẹ́ “Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé” yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, láti gbé àwọn tó ń sìn ín kúrò ní ipò ìrẹ̀sílẹ̀ tí wọ́n wà, á sì mú kí wọ́n pa dà rí ojú rere òun. (Sáàmù 83:18) Ìrètí tí Jeremáyà ní yìí tù ú nínú gan-an lákòókò tí ọkàn rẹ̀ gbọgbẹ́ yẹn. Wòlíì olóòótọ́ yìí ti pinnu láti fi sùúrù dúró de àkókó tí Jèhófà yóò dá àwọn èèyàn Ọlọ́run tó ronú pìwà dà nídè.—Ẹsẹ 21.
-