-
Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Mèsáyà—Igi Kédárì ŃláÌjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
-
-
5. Lábẹ́ òjìji Ìjọba Jésù, àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ onígbọràn máa gbé lábẹ́ ààbò
-
-
“Èmi Yóò Yan Olùṣọ́ Àgùntàn Kan”Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
-
-
10 Bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ. Jèhófà mú Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, látinú ìdílé Ọba Dáfídì (ìyẹn “igi kédárì tó ga fíofío”), ó sì gbìn ín sí Òkè Síónì ti ọ̀run (ìyẹn “òkè tó ga fíofío”). (Sm. 2:6; Jer. 23:5; Ìfi. 14:1) Jèhófà tipa báyìí mú Ọmọ rẹ̀, táwọn ọ̀tá kà sí ‘ẹni tó rẹlẹ̀ jù nínú àwọn èèyàn,’ ó sì gbé e ga ní ti pé ó fi sórí “ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀.” (Dán. 4:17; Lúùkù 1:32, 33) Bíi ti igi kédárì ńlá yẹn, Jésù Kristi, Mèsáyà Ọba, máa ṣàkóso gbogbo ayé, ó sì máa mú ìbùkún wá fún gbogbo àwọn tó wà lábẹ́ ìjọba rẹ̀. Òun gan-an ni Alákòóso tá a lè fọkàn tán. Lábẹ́ òjìji Ìjọba Jésù, àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ onígbọràn ‘máa gbé lábẹ́ ààbò. Ìbẹ̀rù àjálù ò sì ní yọ wọ́n lẹ́nu’ mọ.—Òwe 1:33.
-