-
Tẹ̀gbọ́n-Tàbúrò Tó Ń Ṣe Aṣẹ́wóÌjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
-
-
Tẹ̀gbọ́n-Tàbúrò Tó Ń Ṣe Aṣẹ́wó
Nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì orí 23, Ọlọ́run dá àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́bi lọ́nà tó múná nítorí ìwà àìṣòótọ́ wọn. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló mú kí orí yìí bá Ìsíkíẹ́lì orí 16 mu. Àpèjúwe aṣẹ́wó ló wà ní orí 23 bíi ti orí 16. Nínú àpèjúwe náà, Jerúsálẹ́mù ni àbúrò, Samáríà sì ni ẹ̀gbọ́n. Orí méjèèjì fi hàn pé èyí àbúrò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ nídìí iṣẹ́ aṣẹ́wó, àmọ́ ìwà ìbàjẹ́ rẹ̀ tún wá ju ti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ. Ní orí 23, Jèhófà fi orúkọ pe àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò náà: Ó pe ẹ̀gbọ́n ní Òhólà, ìyẹn Samáríà tó jẹ́ olú ìlú ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì; Ó sì pe àbúrò ní Òhólíbà, ìyẹn Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú Júdà.a—Ìsík. 23:1-4.
-
-
Tẹ̀gbọ́n-Tàbúrò Tó Ń Ṣe Aṣẹ́wóÌjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
-
-
a Àwọn orúkọ yìí ní ìtumọ̀ pàtàkì. Òhólà túmọ̀ sí “Àgọ́ [Ìjọsìn] Rẹ̀.” Ó ṣeé ṣe kí èyí máa tọ́ka sí bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń gbé ibi ìjọsìn tiwọn kalẹ̀ dípò kí wọ́n lo tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Lọ́wọ́ kejì, Òhólíbà túmọ̀ sí “Àgọ́ [Ìjọsìn] Mi Wà Nínú Rẹ̀.” Jerúsálẹ́mù ni ibi ìjọsìn Jèhófà wà.
-