ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ‘Ẹ Ó Di Alààyè’
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • 12 Nígbà tó yá, Charles T. Russell àtàwọn míì tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara polongo òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó wá dà bí ìgbà tí “iṣan àti ẹran” bo àwọn egungun náà. Wọ́n lo ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower àtàwọn ìtẹ̀jáde míì láti mú káwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, kí wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró Ọlọ́run. Lápá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1900, Ọlọ́run tún fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó fòróró yàn lágbára kí wọ́n lè fi kún ìtara wọn. Lára ohun tó lò ni Photo-Drama of Creation [ìyẹn, Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá] àti ìwé The Finished Mystery. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni àkókò tó fáwọn èèyàn Ọlọ́run láti “dìde dúró.” (Ìsík. 37:10) Ìgbà wo nìyẹn ṣẹlẹ̀, báwo ló sì ṣe ṣẹlẹ̀? Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nílùú Bábílónì àtijọ́ máa jẹ́ ká rí ìdáhùn ìbéèrè yìí.

      ‘Wọ́n Di Alààyè, Wọ́n sì Dìde Dúró’

      13. (a) Báwo lọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì 37:​10, 14 ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmúṣẹ látọdún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni? (b) Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn kan láti ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá pa dà sí Ísírẹ́lì?

      13 Bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù tó wà ní Bábílónì bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìmúṣẹ ìran Ìsíkíẹ́lì. Lọ́nà wo? Jèhófà mú kí wọ́n pa dà wà láàyè, ó sì mú kí wọ́n “dìde dúró” ní ti pé ó dá wọn nídè kúrò nígbèkùn, ó sì mú kí wọ́n pa dà sílùú ìbílẹ̀ wọn. Ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì, ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ọgọ́ta (42,360) àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje (7,000) àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì ló fi Bábílónì sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ tún Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ kọ́, kí wọ́n sì lè máa gbé nílẹ̀ Ísírẹ́lì. (Ẹ́sírà 1:​1-4; 2:​64, 65; Ìsík. 37:14) Ní nǹkan bí àádọ́rin (70) ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn, Ẹ́sírà àtàwọn bí ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta (1,750) tí wọ́n wà ní Bábílónì pa dà sí Jerúsálẹ́mù. (Ẹ́sírà 8:​1-20) Lápapọ̀, àwọn Júù tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélógójì (44,000) ló pa dà sílùú ìbílẹ̀ wọn, ká sòótọ́, “ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an” ni wọ́n. (Ìsík. 37:10) Bákan náà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn kan láti ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọmọ àwọn tí Ásíríà kó lẹ́rú ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ wà lára àwọn Júù tó pa dà sí Ísírẹ́lì, kí wọ́n lè jọ tún tẹ́ńpìlì kọ́.​—1 Kíró. 9:3; Ẹ́sírà 6:17; Jer. 33:7; Ìsík. 36:10.

      Ọ̀pọ̀ àwọn ẹni àmì òróró láti ọgọ́rùn-ún ọdún kejì sí ọdún 1919.

      ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 10B: Àwọn “Egungun Gbígbẹ” Àtàwọn ‘Ẹlẹ́rìí Méjì’​—Báwo Ni Wọ́n Ṣe Jọra?

      14. (a) Báwo lọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì 37:24 ṣe jẹ́ ká mọ ìgbà tí àsọtẹ́lẹ̀ náà máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1919? (Wo àpótí náà, “‘Àwọn Egungun Gbígbẹ’ Àtàwọn ‘Ẹlẹ́rìí Méjì’​—Báwo Ni Wọ́n Ṣe Jọra?”)

      14 Báwo ni apá yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ṣe ṣẹ lóde òní? Jèhófà fi han Ìsíkíẹ́lì nínú ìran míì pé àsọtẹ́lẹ̀ náà máa ṣẹ lọ́nà tó gbòòrò lẹ́yìn tí Jésù Kristi tó jẹ́ Dáfídì Tó Tóbi Jù bá di Ọba.b(Ìsík. 37:24) Ọ̀rọ̀ sì rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́ torí pé lọ́dún 1919, Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní ẹ̀mí rẹ̀. Èyí mú kí wọ́n “di alààyè,” Jèhófà sì gbà wọ́n kúrò nínú ìgbèkùn Bábílónì Ńlá. (Àìsá. 66:8) Lẹ́yìn náà, Jèhófà mú kí wọ́n pa dà máa gbé lórí “ilẹ̀” wọn, tàbí lédè míì, nínú párádísè tẹ̀mí. Àmọ́, báwo làwọn èèyàn Jèhófà lásìkò tiwa yìí ṣe di “ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an”?

      Arákùnrin àgbàlagbà kan ń ṣàṣàrò lórí ohun tó kà nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì.

      ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 10D: Ó Ń Mú Ká Pa Dà Dìde Dúró

      15, 16. (a) Báwo làwa èèyàn Jèhófà òde òní ṣe di “ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an”? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Ísíkíẹ́lì ṣe lè mú ká máa fara da àwọn ìṣòro wa? (Wo àpótí náà, “Ó Ń Mú Ká Pa Dà Dìde Dúró.”)

      15 Kò pẹ́ lẹ́yìn ọdún 1919 tí Kristi yan ẹrú olóòótọ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ kan tí wòlíì Sekaráyà sọ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ sáwọn èèyàn Jèhófà lára. Àárín àwọn tó pa dà dé láti ìgbèkùn ni wòlíì yìí wà nígbà tó sọ tẹ́lẹ̀ pé: ‘Ọ̀pọ̀ èèyàn àti orílẹ̀-èdè alágbára yóò wá kí wọ́n lè wá Jèhófà.’ Wòlíì náà fi àwọn tó ń wá Jèhófà wé “ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè.” Àwọn ọkùnrin yìí máa di “Júù kan,” ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí mú, wọ́n á sì máa sọ pé: “A fẹ́ bá yín lọ, torí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”​—Sek. 8:​20-23.

      16 Lọ́jọ́ tiwa, àwọn tó jẹ́ ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí (ìyẹn àwọn tó ṣì wà láyé lára àwọn ẹni àmì òróró) àtàwọn “ọkùnrin mẹ́wàá” (tó ṣàpẹẹrẹ àwọn àgùntàn mìíràn) ti para pọ̀ di “ọmọ ogun tó pọ̀ gan-an.” Kódà, a ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ. (Ìsík. 37:10) Torí pé ọmọ ogun Kristi ni wá, à ń tẹ̀ lé Jésù Ọba wa pẹ́kípẹ́kí, ó sì dá wa lójú pé a máa gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún lọ́jọ́ iwájú.​—Sm. 37:29; Ìsík. 37:24; Fílí. 2:25; 1 Tẹs. 4:​16, 17.

  • Ìjọsìn Mímọ́—Pa Dà Bọ̀ Sípò Díẹ̀díẹ̀
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
      • Arákùnrin Nathan H. Knorr, Joseph F. Rutherford àti Hayden C. Covington.

        “Wọ́n wá di alààyè, wọ́n sì dìde dúró”

        Lẹ́yìn táwọn èèyàn Jèhófà “di alààyè” lọ́dún 1919, wọ́n túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù wọn

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́