-
“Èmi Yóò Sọ Wọ́n Di Orílẹ̀-Èdè Kan”Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
-
-
3. (a) Kí ni igi “ti Júdà” ṣàpẹẹrẹ? (b) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Éfúrémù ló ṣàpẹẹrẹ ẹ̀yà mẹ́wàá ìjọba Ísírẹ́lì?
3 Jèhófà ní kí Ìsíkíẹ́lì mú igi méjì, kó kọ “ti Júdà” sí ara ọ̀kan, kó sì kọ “ti Jósẹ́fù, igi Éfúrémù” sí ara ìkejì. (Ka Ìsíkíẹ́lì 37:15, 16.) Kí làwọn igi méjì náà ṣàpẹẹrẹ? Èyí tó kọ “ti Júdà” sí ṣàpẹẹrẹ ìjọba ẹ̀yà méjì, ìyẹn Júdà àti Bẹ́ńjámínì. Àwọn ọba tó jẹ́ ẹ̀yà Júdà ló ń ṣàkóso ẹ̀yà méjì náà; ibẹ̀ sì làwọn àlùfáà tó jẹ́ ẹ̀yà Léfì wà torí pé inú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù ni wọ́n ti ń sìn. (2 Kíró. 11:13, 14; 34:30) Nípa bẹ́ẹ̀, Júdà làwọn ọba tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Dáfídì ti ń ṣàkóso, ibẹ̀ náà sì làwọn àlùfáà tó jẹ́ ọmọ Léfì wà. Igi tí wọ́n kọ “igi Éfúrémù” sí ṣàpẹẹrẹ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Éfúrémù ni igi kejì ṣàpẹẹrẹ? Jèróbóámù ni ọba tó kọ́kọ́ jẹ ní ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì, ẹ̀yà Éfúrémù ló sì ti wá. Nígbà tó yá, orúkọ Éfúrémù ni wọ́n fi ń pe gbogbo ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì. (Diu. 33:17; 1 Ọba 11:26) Ẹ kíyè sí i pé ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì kò ní àwọn ọba tó wá láti ìdílé Dáfídì, kò sì ní àwọn àlùfáà tó jẹ́ ẹ̀yà Léfì.
-
-
Síso Igi Méjì Pọ̀Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
-
-
ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 12A
Síso Igi Méjì Pọ̀
Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé kó kọ “ti Júdà” sára ọ̀kan, kó sì kọ “ti Jósẹ́fù, igi Éfúrémù” sára ìkejì.
“ti Júdà”
NÍGBÀ ÀTIJỌ́
Ìjọba ẹ̀yà méjì ti Júdà
LÓDE ÒNÍ
Àwọn ẹni àmì òróró
“ti Jósẹ́fù, igi Éfúrémù”
NÍGBÀ ÀTIJỌ́
Ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ti Ísírẹ́lì
LÓDE ÒNÍ
Àwọn àgùntàn mìíràn
-