-
‘Gbogbo Ohun Tó Wà Níbi tí Omi Náà Ṣàn Dé Yóò Máa Wà Láàyè’Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
-
-
11 Lọ́dún 1919, iye àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ò ju ẹgbẹ̀rún mélòó kan lọ, àmọ́ ṣe ni inú wọn ń dùn bí wọ́n ṣe ń rí oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n nílò gbà. Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i. Lónìí, àwọn èèyàn Ọlọ́run ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ. Ṣé a lè sọ pé omi òtítọ́ tó mọ́ lóló ń yára ṣàn? Bẹ́ẹ̀ ni! Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ òtítọ́ inú Bíbélì ni ètò Ọlọ́run ti ṣàlàyé fún wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Bíbélì, ìwé ńlá, ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ àti àṣàrò kúkúrú ni wọ́n tẹ̀ jáde fáwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́gọ́rùn-ún ọdún tó kọjá. Bíi ti odò tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran, ẹ̀kọ́ òtítọ́ ti yára ṣàn dé ọ̀dọ̀ àwọn tí òùngbẹ tẹ̀mí ń gbẹ kárí ayé, kí wọ́n lè rí ohun tí wọ́n nílò láti sún mọ́ Ọlọ́run. Ọjọ́ pẹ́ tá a ti ń tẹ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì jáde. Ní báyìí, ìkànnì jw.org ti mú kó ṣeé ṣe láti wa àwọn ìwé jáde ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) sórí fóònù tàbí ẹ̀rọ míì! Ipa wo ni omi òtítọ́ yìí ń ní lórí àwọn èèyàn tó lọ́kàn tó tọ́?
-
-
‘Gbogbo Ohun Tó Wà Níbi tí Omi Náà Ṣàn Dé Yóò Máa Wà Láàyè’Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
-
-
17 Odò ìbùkún. Odò ìṣàpẹẹrẹ tá à ń sọ̀rọ̀ ẹ̀ yìí máa ṣàn gan-an nínú Párádísè, ìbùkún tí odò náà sì máa mú wá ò ní jẹ́ ìbùkún tẹ̀mí nìkan, ó tún máa mú ìbùkún tara wá. Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Jésù, Ìjọba Ọlọ́run máa mú kí àwọn olóòótọ́ èèyàn jàǹfààní látinú ẹbọ ìràpadà Jésù lọ́nà tó ga. Díẹ̀díẹ̀ la máa di ẹni pípé! Àìsàn ò ní sí mọ́, kò ní sí àwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì mọ́, kódà kò ní sí ilé ìwòsàn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni a ò ní nílò ètò ìlera táwọn èèyàn ṣe mọ́! Omi ìyè yẹn máa ṣàn dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tó la Amágẹ́dọ́nì já, ìyẹn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tó jáde wá látinú “ìpọ́njú ńlá.” (Ìfi. 7:9, 14) Nígbà tí odò ìbùkún yẹn bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàn, ó máa jọni lójú gan-an, àmọ́ kò ní tó nǹkan kan tá a bá fi wé bó ṣe máa ṣàn tó nígbà tó bá yá. Bó ṣe ṣẹlẹ̀ nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, odò yẹn máa ṣàn káàkiri kó lè dé ọ̀dọ̀ àwọn tó nílò rẹ̀.
Nínú Párádísè, odò ìbùkún máa mú kí àwọn àgbàlagbà di ọ̀dọ́, kí ara wọn sì le (Wo ìpínrọ̀ 17)
-