ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Òpin Ti Dé Bá Yín Báyìí”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • Ìsíkíẹ́lì ń fá irun orí rẹ̀.

      ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 6A: “Fá Orí Rẹ àti Irùngbọ̀n Rẹ”

      7. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé kó pín irun tó fá yẹn sí ọ̀nà mẹ́ta, kó sì ṣe ohun tó yàtọ̀ síra sí ìpín kọ̀ọ̀kan?

      7 Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé kó pín irun tó fá yẹn sí ọ̀nà mẹ́ta, kó sì ṣe ohun tó yàtọ̀ síra sí ìpín kọ̀ọ̀kan? (Ka Ìsíkíẹ́lì 5:​7-12.) Ìsíkíẹ́lì dáná sun ìdá kan nínú irun yẹn “nínú ìlú náà” láti fi yé àwọn tó ń wòran pé àwọn kan lára àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù máa kú sínú ìlú náà. Ó fi idà gé ìdá mẹ́ta míì “káàkiri ìlú náà” láti fi hàn pé wọ́n máa pa àwọn míì lára àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù káàkiri ẹ̀yìn odi ìlú náà. Ó sì fọ́n ìdá mẹ́ta yòókù sínú afẹ́fẹ́ láti fi hàn pé àwọn kan lára àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù máa fọ́n ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, àmọ́ “idà” máa “lé wọn bá.” Torí náà, ibi yòówù kí àwọn tó yè bọ́ náà sá lọ láti máa gbé, ọkàn wọn ò ní balẹ̀.

  • “Fá Orí Rẹ àti Irùngbọ̀n Rẹ”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
      • Ìsíkíẹ́lì fi iná sun ìdá kan nínú irun tó gé.

        ‘Sun Ún’

        Àwọn kan máa kú sínú ìlú náà

      • Ìsíkíẹ́lì fi idà gé ìdá kan nínú irun rẹ̀ tó gé.

        ‘Fi Idà Gé E’

        Wọ́n máa pa àwọn kan káàkiri ẹ̀yin odi ìlú náà

      • Ìsíkíẹ́lì fọ́n ìdá kan nínú irun rẹ̀ tó gé sínú afẹ́fẹ́.

        ‘Fọ́n Ọn Ká’

        Àwọn kan máa yè bọ́, àmọ́ ọkàn wọn ò ní balẹ̀

  • “Òpin Ti Dé Bá Yín Báyìí”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • 10 Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fi hàn pé àwọn tó ń ti ìsìn èké lẹ́yìn máa yè bọ́ nígbà tí ètò ìsìn èké bá pa run. Ìbẹ̀rù máa mú kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ onírúurú èèyàn tó ń wá ibi tí wọ́n máa fara pa mọ́ sí. (Sek. 13:​4-6; Ìfi. 6:​15-17) Ọ̀rọ̀ wọn mú ká ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù àtijọ́ tí wọ́n yè bọ́ nígbà ìparun ìlú náà tí wọ́n sì fọ́n ká “sínú afẹ́fẹ́.” Bá a ṣe sọ ní ìpínrọ̀ 7, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n yè bọ́ nígbà yẹn, Jèhófà ‘mú idà, ó sì lé wọn bá.’ (Ìsík. 5:2) Bákan náà, ibi yòówù kí àwọn tó bá yè bọ́ nígbà ìparun ìsìn èké sá lọ láti fara pa mọ́, wọn ò ní bọ́ lọ́wọ́ idà Jèhófà. Ó máa pa àwọn àti gbogbo àwọn ẹni bí ewúrẹ́ run ní Amágẹ́dọ́nì.​—Ìsík. 7:4; Mát. 25:​33, 41, 46; Ìfi. 19:​15, 18.

      Tó bá kan wíwàásù ìhìn rere, a ò “ní lè sọ̀rọ̀” mọ́

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́