ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Òpin Ti Dé Bá Yín Báyìí”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • 8. (a) Báwo ni àṣefihàn Ìsíkíẹ́lì yìí ṣe fi hàn pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa? (b) Ọ̀nà wo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa “fọ́nrán díẹ̀” gbà ṣẹ?

      8 Síbẹ̀, àṣefihàn tí Ìsíkíẹ́lì fi sàsọtẹ́lẹ̀ yìí tún fi hàn pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Jèhófà sọ fún wòlíì Ìsíkíẹ́lì pé kó ṣe ohun kan sí irun tó fá yẹn, ó ní: “Kí o tún mú fọ́nrán díẹ̀ nínú irun náà, kí o sì wé e mọ́ aṣọ rẹ.” (Ìsík. 5:3) Àṣẹ tí Jèhófà pa yìí fi hàn pé díẹ̀ lára àwọn Júù tó bá fọ́n ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè yẹn máa la rògbòdìyàn náà já. Àwọn kan lára “fọ́nrán díẹ̀” yẹn máa wà lára àwọn tó máa pa dà sí Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn àádọ́rin (70) ọdún tí wọ́n máa lò nígbèkùn Bábílónì. (Ìsík. 6:​8, 9; 11:17) Ṣé àsọtẹ́lẹ̀ yìí tiẹ̀ ṣẹ? Bẹ́ẹ̀ ni. Ọdún mélòó kan lẹ́yìn tí wọ́n kúrò nígbèkùn Bábílónì, wòlíì Hágáì sọ pé àwọn kan lára àwọn Júù tó fọ́n ká yẹn ti pa dà sí Jerúsálẹ́mù lóòótọ́. Àwọn ni “àwọn àgbààgbà tó mọ bí ilé náà ṣe rí tẹ́lẹ̀,” ìyẹn tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́. (Ẹ́sírà 3:12; Hág. 2:​1-3) Jèhófà rí i dájú pé wọn ò gbá ìjọsìn mímọ́ wọlẹ̀, bó ṣe ṣèlérí gẹ́lẹ́. A máa jíròrò àlàyé síwájú sí i nípa bí ìjọsìn mímọ́ ṣe pa dà bọ̀ sípò ní Orí 9 nínú ìwé yìí.​—Ìsík. 11:​17-20.

  • “Fá Orí Rẹ àti Irùngbọ̀n Rẹ”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
      • Ìsíkíẹ́lì wé fọ́nrán díẹ̀ lára irun rẹ̀ tó gé mọ́ aṣọ rẹ̀.

        “Wé E Mọ́ Aṣọ”

        Àwọn kan máa pa dà sí Jerúsálẹ́mù láti ìgbèkùn, ìjọsìn mímọ́ ò sì ní pa run

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́