ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • “Èmi Yóò Mú Kí Ọkàn Wọn Ṣọ̀kan”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • 11 Ní gbogbo àkókò tí kò sí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́, táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sì ń lo agbára lórí àwọn èèyàn, àwọn kan wà tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tòótọ́, ìyẹn àwọn “àlìkámà” tí Jésù sọ nínú àkàwé rẹ̀. Bíi ti àwọn Júù tó wà nígbèkùn, tí Ìsíkíẹ́lì 6:9 sọ nípa wọn, wọ́n rántí Ọlọ́run tòótọ́. Àwọn kan tiẹ̀ fìgboyà ta ko àwọn ẹ̀kọ́ èké tó kúnnú ṣọ́ọ̀ṣì. Àwọn èèyàn fi wọ́n ṣẹ̀sín, wọ́n sì ṣe inúnibíni sí wọn. Àmọ́, ṣé Jèhófà máa fi àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ pátápátá nínú ìgbèkùn tẹ̀mí ni? Ká má rí i! Bíi ti ọ̀rọ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, Jèhófà fi ìbínú hàn dé ìwọ̀n tó yẹ, kò sì jẹ́ kó pẹ́ jù kí ìbínú náà tó rọlẹ̀. (Jer. 46:28) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ò fi àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ láìní ìrètí. Ẹ jẹ́ ká wá pa dà sọ́dọ̀ àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì àtijọ́, ká sì wo bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí wọ́n nírètí pé wọ́n á bọ́ nígbèkùn lọ́jọ́ kan.

      Àwọn olórí ẹ̀sìn fẹ́ sun Kristẹni tòótọ́ kan nínú iná láyè ìgbà tí òkùnkùn tẹ̀mí mú kí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì jẹ gàba.

      Ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn Kristẹni tòótọ́ fi dojú kọ inúnibíni látọ̀dọ̀ Bábílónì Ńlá (Wo ìpínrọ̀ 10 àti 11)

  • “Èmi Yóò Mú Kí Ọkàn Wọn Ṣọ̀kan”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
    • 13 Àwọn Júù olóòótọ́ wà lára àwọn aláìṣòótọ́ èèyàn tí wọ́n kó lọ sígbèkùn. Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run gbẹnu Ìsíkíẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé lára àwọn èèyàn òun máa ronú pìwà dà nígbèkùn tí wọ́n wà. Àwọn Júù tó ronú pìwà dà yìí máa sọ àwọn ohun ìtìjú tí wọ́n ṣe tó fi hàn pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà, wọ́n á bẹ̀ ẹ́ pé kó dárí ji àwọn, kó sì fojúure wo àwọn. (Ìsík. 6:8-10; 12:16) Ìsíkíẹ́lì wà lára àwọn Júù olóòótọ́ yẹn, bẹ́ẹ̀ náà sì ni wòlíì Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Kódà, Dáníẹ́lì pẹ́ láyé débi tó fi rí ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin ìgbèkùn náà. Àdúrà àtọkànwá tó gbà wà nínú Dáníẹ́lì orí 9, ìyẹn àdúrà tó fi bẹ Ọlọ́run pé kó dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jì wọ́n. Ó dájú pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára Dáníẹ́lì náà ló rí lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó wà nígbèkùn, tí wọ́n ń fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wọ́n, kó sì bù kún wọn. Ẹ wo bí ìlérí tí Ọlọ́run mí sí Ìsíkíẹ́lì láti sọ nípa ìtúsílẹ̀ àti ìmúbọ̀sípò ṣe máa dùn mọ́ wọn tó!

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́