-
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn ÒǹkàwéIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016 | June
-
-
Jèhófà mú kí Ìsíkíẹ́lì rí ìwà búburú táwọn èèyàn ń hù ní Jerúsálẹ́mù ṣáájú ìparun ìlú náà lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó sì tún mú kó rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ kí wọ́n tó pa ìlú náà run. Ìsíkíẹ́lì rí àwọn ọkùnrin mẹ́fà tí wọ́n ní àwọn ohun ìjà tó lè fọ́ nǹkan túútúú. Ó tún rí ọkùnrin kan tó wà pẹ̀lú wọn tó “wọ aṣọ ọ̀gbọ̀” tó sì ní “ìwo yíǹkì akọ̀wé.” (Ìsík. 8:6-12; 9:2, 3) Ọlọ́run sọ fún ọkùnrin náà pé: “La àárín ìlú ńlá náà já, . . . kí o sì sàmì sí iwájú orí àwọn ènìyàn tí ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora nítorí gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí tí a ń ṣe ní àárín rẹ̀.” Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run ní kí àwọn ọkùnrin tó mú ohun ìjà lọ́wọ́ wọ ìlú náà lọ kí wọ́n sì pa gbogbo àwọn tí kò ní àmì náà. (Ìsík. 9:4-7) Kí la rí kọ́ nínú ìran tí Ísíkíẹ́lì rí yìí, ta sì ni ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé?
Ọdún 612 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Ìsíkíẹ́lì rí ìran yìí, ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà sì ni ó kọ́kọ́ nímùúṣẹ nígbà táwọn ọmọ ogun Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run. Lóòótọ́ abọ̀rìṣà làwọn ará Bábílónì, àmọ́ àwọn ni Jèhófà lò láti Jerúsálẹ́mù run. (Jer. 25:9, 15-18) Ìdí sì ni pé àwọn èèyàn yẹn ti di apẹ̀yìndà, Jèhófà sì ń fìyà tó tọ́ jẹ wọ́n. Àmọ́ o, kì í wá ṣe kí wọ́n kàn máa pa èèyàn nípakúpa, láìwojú. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ bí ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ń jìyà kí olódodo wá ní ìpín níbẹ̀. Jèhófà fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn Júù tó kórìíra ìwà búburú tó kúnnú ìlú náà, ó sì rí i pé òun dáàbò bò wọ́n.
Kì í ṣe Ìsíkíẹ́lì ló ń sàmì síwájú àwọn èèyàn náà, bẹ́ẹ̀ ni kò sí lára àwọn tó pa ìlú náà run. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn áńgẹ́lì ló mú ìdájọ́ náà ṣẹ. Torí náà, àsọtẹ́lẹ̀ yìí jẹ́ ká rí ohun tí ojú lásán ò lè rí, ìyẹn àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run. Jèhófà ti gbéṣẹ́ lé àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ lọ́wọ́ pé wọ́n á pa àwọn ẹni burúkú run. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn náà láá rí sí i pé kò sóhun tó máa ṣe àwọn olódodo.a
-
-
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn ÒǹkàwéIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016 | June
-
-
Nínú àwọn àlàyé tá a ti ṣe sẹ́yìn nípa ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé, a sọ pé àwọn tó ṣì wà láàyè lára àwọn ẹni àmì òróró ni ọkùnrin náà ṣàpẹẹrẹ lóde òní. A gbà nígbà yẹn pé àwọn tó tẹ́wọ́ gba òtítọ́ tá à ń wàásù rẹ̀ làwọn tá a sàmì sí láti là á já. Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó ti wá ṣe kedere pé a ní láti tún ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, ká sì ṣàtúnṣe sí àwọn àlàyé náà. Bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú Mátíù 25:31-33, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ló máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́. Ìgbà ìpọ́njú ńlá ló máa ṣèdájọ́ tó kẹ́yìn yìí, táá sì ya àwọn èèyàn sọ́tọ̀. Àwọn tá a fi wé àgùntàn ló máa la ìpọ́njú yẹn já nígbà tó jẹ́ pé ńṣe ló máa pa àwọn tá a fi wé ewúrẹ́ run.
-
-
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn ÒǹkàwéIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016 | June
-
-
Láwọn lọ́jọ́ Ísíkíẹ́lì, kò sí ẹnì tó gba àmì tó ṣeé fojú rí síwájú orí rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì lọ̀rọ̀ rí lónìí. Kí làwọn èèyàn gbọ́dọ̀ ṣe láti rí àmì ìṣàpẹẹrẹ náà gbà kí wọ́n bàa lè la ìpọ́njú náà já? Wọ́n ní láti tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá à ń kọ́ àwọn èèyàn, kí wọ́n máa hùwà tó yẹ Kristẹni, kí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, kí wọ́n sì máa fòótọ́ inú ti àwọn arákùnrin Kristi lẹ́yìn. (Mát. 25:35-40) Àwọn tó bá ṣe àwọn ohun tá a sọ yìí ló máa gba àmì ìṣàpẹẹrẹ náà nígbà ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀, ìyẹn láá sì jẹ́ kí wọ́n là á já.
Lónìí, ọkùnrin tó ní ìwo yíǹkì akọ̀wé yẹn dúró fún Jésù Kristi. Jésù lẹni tá ò fojú rí tó ń sàmì sí àwọn tó máa là á já. Ìgbà tó bá ti ya àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nígbà ìpọ́njú ńlá ló máa sàmì sí wọn. Ìyẹn ló máa jẹ́ kí wọ́n láǹfààní láti máa gbé láyé títí láé.—Mát. 25:34, 46.b
-
-
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn ÒǹkàwéIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016 | June
-
-
a Lóòótọ́ kò sí àmì kan téèyàn lè fojú rí níwájú orí Bárúkù (tó jẹ́ akọ̀wé Jeremáyà), Ebedi-mélékì ará Etiópíà àtàwọn ọmọ Rékábù, síbẹ̀ a dá ẹ̀mí wọn sí. (Jer. 35:1-19; 39:15-18; 45:1-5) Ìyẹn fi hàn pé àmì ìṣàpẹẹrẹ ni wọ́n gbà, ìyẹn ló jẹ́ ká dá ẹ̀mí wọn sí.
-
-
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn ÒǹkàwéIlé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016 | June
-
-
b Àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ olóòótọ́ kò nílò àmì yẹn láti là á já. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa gba èdìdì ìkẹyìn wọn gẹ́rẹ́ kí wọ́n tó kú. Tí wọ́n bá ṣì wà láàyè, wọ́n máa gba èdìdì ìkẹyìn wọn kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀.—Ìṣí. 7:1, 3.
-