-
Ọba Naa Jọba!“Kí Ijọba Rẹ Dé”
-
-
“IGBA MEJE” NAA—BAWO NI Ó TI GÙN TÓ?
23. Eeṣe tí Akoko awọn Keferi fi nilati nasẹ̀ dé ọjọ wa?
23 Dajudaju, nigba naa, “igba meje” naa gẹgẹ bi a ti lò ó fun Akoko awọn Keferi nilati gùn gan-an pupọpupọ jù ọdun meje lasan lọ. Ranti pe, Jesu sọrọ nipa ‘imuṣẹ’ tabi opin Akoko awọn Keferi wọnyi ní isopọ pẹlu ‘ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan.’ (Luku 21:7, 24; Matteu 24:3) Nitori naa wọn nilati nasẹ̀ dé ọjọ wa. Bawo ni wọn tilẹ ti gùn tó gan-an?
24. Bawo ni a ṣe lè tumọ gígùn “igba meje” naa?
24 Bi a bá yíjúsí Ìfihàn ori 12, awa yoo kiyesi pe ẹsẹ 6 ati 14 fi sáà 1,260 ọjọ hàn pe ó jẹ́ ‘akoko kan ati awọn akoko ati idaji akoko,’ tabi 1 + 2 + 1/2 tí ó jẹ́ aropọ 3 1/2 akoko. Nitori naa, “akoko kan” yoo jẹ́ 360 ọdun, tabi oṣu oṣupa 12 tí ọkọọkan rẹ̀ jẹ́ 30 ọjọ ní ipindọgba. “Igba meje” yoo jẹ́ 2,520 ọjọ; iṣiro Bibeli lọna asọtẹlẹ ti “ọjọ kan fun ọdun kan, ọjọ kan fun ọdun kan,” sì fihan pe awọn wọnyi nitootọ yoo jásí 2,520 ọdun inu kalẹnda. (Numeri 14:34; Esekieli 4:6) Nitori naa, eyi ni gígùn “igba meje” naa—Akoko awọn Keferi.
-
-
Ọba Naa Jọba!“Kí Ijọba Rẹ Dé”
-
-
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 135]
ṢÍṢÍRÒ “IGBA MEJE” NAA
“igba” 7 = 7 × 360 = 2,520 ọdun
(“igba” tabi ọdun inu Bibeli jẹ́ ipindọgba laaarin ọdun ti a fi yíyọ oṣupa kà 354 ọjọ ati eyi ti a fi iyipo oorun kà ti 365 1/4 ọjọ)
607 B.C.E. si 1 B.C.E. = 606 ọdun
1 B.C.E. si 1 C.E. = 1 ọdun
1 C.E. si 1914 C.E. = 1,913 ọdun
607 B.C.E. si 1914 C.E. = 2,520 ọdun
-