ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ọ̀rọ̀ Mẹ́rin tí Ó yí Ayé Padà
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
    • 6 Ṣùgbọ́n, ìwà àfojúdi tí Bẹliṣásárì fẹ́ hù tún burú ju èyí lọ. “Ọba àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn, àwọn wáhàrì rẹ̀ àti àwọn aya rẹ̀ onípò kejì . . . mu wáìnì, wọ́n sì yin àwọn ọlọ́run wúrà àti ti fàdákà, bàbà, irin, igi àti òkúta.” (Dáníẹ́lì 5:3, 4) À ṣé ńṣe ni Bẹliṣásárì fẹ́ gbé àwọn ọlọ́run rẹ̀ ga ju Jèhófà lọ! Ó dà bí pé ìwà yìí jẹ́ ìṣe àwọn ará Bábílónì. Ṣe ni wọ́n ń pẹ̀gàn àwọn Júù òǹdè wọn, tí wọ́n ń fi ìjọsìn wọn ṣẹ̀sín, wọn kò sì jẹ́ kí wọ́n ní ìrètí pé wọ́n ṣì lè padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn ọ̀wọ́n. (Sáàmù 137:1-3; Aísáyà 14:16, 17) Bóyá ṣe ni ọba tí ó yó bìnàkò yìí rò pé títẹ́ àwọn ìgbèkùn wọ̀nyí àti títàbùkù sí Ọlọ́run wọn yóò mú orí àwọn obìnrin àti àwọn olóyè òun wú, tí ìyẹn yóò sì mú kí òun dà bí alágbára kan.a Àmọ́, ká tilẹ̀ ní Bẹliṣásárì rí ìwúrí gbà láti inú gígùn tí agbára gùn yìí, kò wà fún ìgbà pípẹ́ rárá.

  • Ọ̀rọ̀ Mẹ́rin tí Ó yí Ayé Padà
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
    • a Nínú àkọsílẹ̀ fífín ìgbàanì kan, Kírúsì Ọba sọ nípa Bẹliṣásárì pé: “Olókùnrùn kan ni wọ́n fi jẹ alákòóso orílẹ̀-èdè rẹ̀.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́