ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • A Gbà Á Sílẹ̀ Lẹ́nu Àwọn Kìnnìún!
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
    • 16. (a) Èé ṣe tí Dáríúsì fi bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Dáníẹ́lì? (b) Ìrètí wo ni Dáríúsì ní nípa Dáníẹ́lì?

      16 Dáríúsì rò ó pé kò sí ohun tí òun tún lè ṣe mọ́ lórí ọ̀ràn náà. Òfin ọ̀hún kò ṣeé wọ́gi lé, bẹ́ẹ̀ ni “ẹ̀ṣẹ̀” Dáníẹ́lì kò sì láforíjì. Kìkì ohun tí Dáríúsì lè sọ fún Dáníẹ́lì ni pé “Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn láìyẹsẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò gbà ọ́ sílẹ̀.” Ó dà bí pé Dáríúsì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Dáníẹ́lì. Jèhófà ni ó fún Dáníẹ́lì ní agbára tí ó fi lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìṣubú Bábílónì. Ọlọ́run sì tún fún Dáníẹ́lì ní “ẹ̀mí àrà ọ̀tọ̀ kan” tí ó mú kí ó tayọ àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga yòókù. Bóyá Dáríúsì mọ̀ nípa pé Ọlọ́run yìí kan náà ni ó yọ àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta nínú ìléru oníná ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Bóyá ìrètí ọba ni pé kí Jèhófà gba Dáníẹ́lì wàyí, níwọ̀n bí òun Dáríúsì kò ti lè yí òfin tí òun ti buwọ́ lù padà. Nítorí náà, a sọ Dáníẹ́lì sínú ihò kìnnìún.c Lẹ́yìn náà, wọ́n “gbé òkúta kan wá, wọ́n sì yí i dí ẹnu ihò náà, ọba sì fi èdìdì òrùka àmì-àṣẹ rẹ̀ àti ti òrùka àmì-àṣẹ àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn sé e, kí a má bàa yí nǹkan kan padà nínú ọ̀ràn Dáníẹ́lì.”—Dáníẹ́lì 6:16, 17.

  • A Gbà Á Sílẹ̀ Lẹ́nu Àwọn Kìnnìún!
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
    • c Ó ṣeé ṣe kí ihò kìnnìún náà jẹ́ àjà ilẹ̀ kan tí a dá lu lókè. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ó tún ní àwọn ìlẹ̀kùn tàbí àgánrándì irin tí a lè gbé sókè kí ẹranko kan lè wọ ibẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́