ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • A Ṣí Àkókò Dídé Mèsáyà Payá
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
    • 25 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ṣì ń bá a lọ láti pọ́n aráyé lójú, fífi tí a fi ikú ké Jésù kúrò àti jíjí tí a jí i dìde sí ìyè ti ọ̀run, mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ. Ó ‘mú ìrélànàkọjá kásẹ̀ nílẹ̀, ó pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́ kúrò, ó ṣe ètùtù nítorí ìṣìnà, ó sì mú òdodo wá.’ Ọlọ́run mú májẹ̀mú Òfin, tí ó kó àwọn Júù síta tí ó sì dá wọn lẹ́bi gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀, kúrò. (Róòmù 5:12, 19, 20; Gálátíà 3:13, 19; Éfésù 2:15; Kólósè 2:13, 14) A lè wá pa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn oníwà àìtọ́ tí ó ronú pìwà dà rẹ́, a sì lè mú ìjìyà tí ó lè tipa bẹ́ẹ̀ jẹyọ kúrò wàyí. Ó wá ṣeé ṣe pé kí àwọn tí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ lè bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ ẹbọ ìpẹ̀tù ti Mèsáyà. Wọ́n lè fojú sọ́nà fún àtigba ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni, ìyẹn ni, “ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Róòmù 3:21-26; 6:22, 23; 1 Jòhánù 2:1, 2.

  • A Ṣí Àkókò Dídé Mèsáyà Payá
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
    • 27. “Ibi Mímọ́ Nínú Àwọn Ibi Mímọ́” wo ni a fòróró yàn, báwo sì ni?

      27 Àsọtẹ́lẹ̀ náà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé a ó fòróró yan “Ibi Mímọ́ Nínú Àwọn Ibi Mímọ́.” Èyí kò tọ́ka sí fífi òróró yan Ibi Mímọ́ Jù Lọ, tàbí yàrá inú lọ́hùn-ún ní tẹ́ńpìlì ti Jerúsálẹ́mù. Gbólóhùn náà, “Ibi Mímọ́ Nínú Àwọn Ibi Mímọ́” tọ́ka sí ibi ibùjọsìn Ọlọ́run ní ọ̀run. Ibẹ̀ ni Jésù ti gbé ìtóye ẹbọ tí ó fi ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn rú, fún Baba rẹ̀. Ẹbọ yẹn ni ó fi òróró yàn, tàbí pé ó ṣe ìyàsọ́tọ̀ ohun ti ọ̀run tí ó jẹ́ ògidì nípa tẹ̀mí, èyí tí a fi Ibi Mímọ́ Jù Lọ inú àgọ́ ìjọsìn àti ti tẹ́ńpìlì lẹ́yìn ìgbà náà ṣàpẹẹrẹ.—Hébérù 9:11, 12.

      ÀSỌTẸ́LẸ̀ TÍ ỌLỌ́RUN JẸ́RÌÍ SÍ

      28. Kí ni ‘fífi èdìdì tẹ ìran àti wòlíì’ túmọ̀ sí?

      28 Àsọtẹ́lẹ̀ tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ nípa Mèsáyà tún mẹ́nu kan ‘fífi èdìdì tẹ ìran àti wòlíì’ pẹ̀lú. Èyí túmọ̀ sí pé gbogbo ohun tí a sọ tẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà—gbogbo ohun tí ẹbọ rẹ̀, àjíǹde rẹ̀, àti ìfarahàn rẹ̀ ní ọ̀run ṣàṣeparí, àti àwọn ohun mìíràn tí ó ṣẹlẹ̀ láàárín ọ̀sẹ̀ àádọ́rin náà—ni a óò fi òǹtẹ̀ lù pé Ọlọ́run fọwọ́ sí i, pé yóò jẹ́ òótọ́, àti pé ó ṣeé gbíyè lé. A óò fi èdìdì di ìran náà, ní fífi í mọ sórí Mèsáyà nìkan. Ara rẹ̀ àti ara iṣẹ́ tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ rẹ̀ ṣe ni yóò ti ní ìmúṣẹ. Inú ohun tí ó bá jẹ mọ́ Mèsáyà tí a sọ tẹ́lẹ̀ náà nìkan ni a ti lè rí ìtumọ̀ tí ó tọ́ nípa ìran náà. Ohunkóhun mìíràn kò lè ṣí èdìdì ìtumọ̀ rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́